Romans 4 - Listen Online
Read Romans 4
1 NJẸ kili awa o ha wipe Abrahamu, baba wa nipa ti ara, ri?
1 What shall we say then that Abraham our father, as pertaining to the flesh, hath found?
2 Nitori bi a ba da Abrahamu lare nipa iṣẹ, o ni ohun iṣogo; ṣugbọn kì iṣe niwaju Ọlọrun.
2 For if Abraham were justified by works, he hath whereof to glory; but not before God.
3 Iwe-mimọ́ ha ti wi? Abrahamu gbà Ọlọrun gbọ́, a si kà a si ododo fun u.
3 For what saith the scripture? Abraham believed God, and it was counted unto him for righteousness.
4 Njẹ fun ẹniti o ṣiṣẹ a kò kà ère na si ore-ọfẹ bikoṣe si gbese.
4 Now to him that worketh is the reward not reckoned of grace, but of debt.
5 Ṣugbọn fun ẹniti kò ṣiṣẹ, ti o si ngbà ẹniti o nda enia buburu lare gbọ́, a kà igbagbọ́ rẹ̀ si ododo.
5 But to him that worketh not, but believeth on him that justifieth the ungodly, his faith is counted for righteousness.
6 Gẹgẹ bi Dafidi pẹlu ti pe oluwarẹ̀ na ni ẹni ibukun, ẹniti Ọlọrun kà ododo si laisi ti iṣẹ́,
6 Even as David also describeth the blessedness of the man, unto whom God imputeth righteousness without works,
7 Wipe, Ibukún ni fun awọn ẹniti a dari irekọja wọn jì, ti a si bò ẹ̀ṣẹ wọn mọlẹ.
7 Saying, Blessed are they whose iniquities are forgiven, and whose sins are covered.
8 Ibukún ni fun ọkunrin na ẹniti Oluwa kò kà ẹ̀ṣẹ si li ọrùn.
8 Blessed is the man to whom the Lord will not impute sin.
9 Ibukún yi ha jẹ ti awọn akọla nikan ni, tabi ti awọn alaikọla pẹlu? nitoriti a wipe, a kà igbagbọ́ fun Abrahamu si ododo.
9 Cometh this blessedness then upon the circumcision only, or upon the uncircumcision also? for we say that faith was reckoned to Abraham for righteousness.
10 Bawo li a ha kà a si i? nigbati o wà ni ikọla tabi li aikọla? Kì iṣe ni ikọla, ṣugbọn li aikọla ni.
10 How was it then reckoned? when he was in circumcision, or in uncircumcision? Not in circumcision, but in uncircumcision.
11 O si gbà àmi ikọla, èdidi ododo igbagbọ́ ti o ni nigbati o wà li aikọla: ki o le ṣe baba gbogbo awọn ti o gbagbọ́, bi a kò tilẹ kọ wọn ni ilà; ki a le kà ododo si wọn pẹlu:
11 And he received the sign of circumcision, a seal of the righteousness of the faith which he had yet being uncircumcised: that he might be the father of all them that believe, though they be not circumcised; that righteousness might be imputed unto them also:
12 Ati baba ikọla fun awọn ti kò si ninu kìki awọn akọla nikan, ṣugbọn ti nrin pẹlu nipasẹ igbagbọ́ Abrahamu baba wa, ti o ni li aikọla.
12 And the father of circumcision to them who are not of the circumcision only, but who also walk in the steps of that faith of our father Abraham, which he had being yet uncircumcised.
13 Nitori ileri fun Abrahamu tabi fun irú-ọmọ rẹ̀ pe, on ó ṣe arole aiye, kì iṣe nipa ofin, bikoṣe nipa ododo igbagbọ́.
13 For the promise, that he should be the heir of the world, was not to Abraham, or to his seed, through the law, but through the righteousness of faith.
14 Nitori bi awọn ti nṣe ti ofin ba ṣe arole, igbagbọ́ di asan, ileri si di alailagbara:
14 For if they which are of the law be heirs, faith is made void, and the promise made of none effect:
15 Nitori ofin nṣiṣẹ́ ibinu: ṣugbọn nibiti ofin kò ba si, irufin kò si nibẹ̀.
15 Because the law worketh wrath: for where no law is, there is no transgression.
16 Nitorina li o fi ṣe ti ipa igbagbọ́, ki o le ṣe ti ipa ore-ọfẹ; ki ileri ki o le da gbogbo irú-ọmọ loju; kì iṣe awọn ti ipa ofin nikan, ṣugbọn ati fun awọn ti inu igbagbọ́ Abrahamu pẹlu, ẹniti iṣe baba gbogbo wa,
16 Therefore it is of faith, that it might be by grace; to the end the promise might be sure to all the seed; not to that only which is of the law, but to that also which is of the faith of Abraham; who is the father of us all,
17 (Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Mo ti fi ọ ṣe baba orilẹ-ède pupọ,) niwaju ẹniti on gbagbọ́, Ọlọrun tikararẹ̀, ti o sọ okú di ãye, ti o si pè ohun wọnni ti kò si bi ẹnipe nwọn ti wà;
17 (As it is written, I have made thee a father of many nations,) before him whom he believed, even God, who quickeneth the dead, and calleth those things which be not as though they were.
18 Nigbati ireti kò si, ẹniti o gbagbọ ni ireti ki o le di baba orilẹ-ède pupọ, gẹgẹ bi eyi ti a ti wipe, Bayi ni irú-ọmọ rẹ yio ri.
18 Who against hope believed in hope, that he might become the father of many nations; according to that which was spoken, So shall thy seed be.
19 Ẹniti kò ṣe ailera ni igbagbọ́, kò rò ti ara on tikararẹ̀ ti o ti kú tan (nigbati o to bi ẹni ìwọn ọgọrun ọdún), ati kíku inu Sara:
19 And being not weak in faith, he considered not his own body now dead, when he was about an hundred years old, neither yet the deadness of Sara's womb:
20 Kò fi aigbagbọ ṣiyemeji ileri Ọlọrun; ṣugbọn o le ni igbagbọ́, o nfi ogo fun Ọlọrun;
20 He staggered not at the promise of God through unbelief; but was strong in faith, giving glory to God;
21 Nigbati o sa ti mọ̀ dajudaju pe, ohun ti on ba ti leri, o si le ṣe e.
21 And being fully persuaded that, what he had promised, he was able also to perform.
22 Nitorina li a si ṣe kà a si ododo fun u.
22 And therefore it was imputed to him for righteousness.
23 A kò sá kọ ọ nitori tirẹ̀ nikan pe, a kà a si fun u,
23 Now it was not written for his sake alone, that it was imputed to him;
24 Ṣugbọn nitori tiwa pẹlu, ẹniti a o si kà a si fun, bi awa ba gbà a gbọ́, ẹniti o gbé Jesu Oluwa wa dide kuro ninu okú;
24 But for us also, to whom it shall be imputed, if we believe on him that raised up Jesus our Lord from the dead;
25 Ẹniti a fi tọrẹ ẹ̀ṣẹ wa, ti a si jinde nitori idalare wa.
25 Who was delivered for our offences, and was raised again for our justification.