Psalms 88 - Listen Online
Read Psalms 88
1 OLUWA Ọlọrun igbala mi, emi nkigbe lọsan ati loru niwaju rẹ.
1 O LORD God of my salvation, I have cried day and night before thee:
2 Jẹ ki adura mi ki o wá si iwaju rẹ: dẹ eti rẹ silẹ si igbe mi.
2 Let my prayer come before thee: incline thine ear unto my cry;
3 Nitori ti ọkàn mi kún fun ipọnju, ẹmi mi si sunmọ isa-okú.
3 For my soul is full of troubles: and my life draweth nigh unto the grave.
4 A kà mi pẹlu kún awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò: emi dabi ọkunrin ti kò ni ipá.
4 I am counted with them that go down into the pit: I am as a man that hath no strength:
5 Ẹniti a kọ̀ silẹ lãrin awọn okú, bi awọn ẹni pipa ti o dubulẹ ni isa-okú, ẹniti iwọ kò ranti mọ́: a si ke wọn kuro nipa ọwọ rẹ.
5 Free among the dead, like the slain that lie in the grave, whom thou rememberest no more: and they are cut off from thy hand.
6 Iwọ ti fi mi le ibi isalẹ ti o jìn julọ, ninu okunkun, ninu ọgbun.
6 Thou hast laid me in the lowest pit, in darkness, in the deeps.
7 Ibinu rẹ lẹ̀ mọ mi lara kikan, iwọ si ti fi riru omi rẹ gbogbo ba mi ja.
7 Thy wrath lieth hard upon me, and thou hast afflicted me with all thy waves. Selah.
8 Iwọ ti mu awọn ojulumọ mi jina si mi; iwọ si sọ mi di irira si wọn; a se mi mọ́, emi kò le jade.
8 Thou hast put away mine acquaintance far from me; thou hast made me an abomination unto them: I am shut up, and I cannot come forth.
9 Oju mi nkãnu nitori ipọnju: Oluwa, emi ti npè ọ lojojumọ, emi si ti nawọ mi si ọ.
9 Mine eye mourneth by reason of affliction: LORD, I have called daily upon thee, I have stretched out my hands unto thee.
10 Iwọ o fi iṣẹ iyanu rẹ hàn fun okú bi? awọn okú yio ha dide ki nwọn si ma yìn ọ bi?
10 Wilt thou shew wonders to the dead? shall the dead arise and praise thee? Selah.
11 A o ha fi iṣeun ifẹ rẹ hàn ni isà-òkú bi? tabi otitọ rẹ ninu iparun?
11 Shall thy lovingkindness be declared in the grave? or thy faithfulness in destruction?
12 A ha le mọ̀ iṣẹ iyanu rẹ li okunkun bi? ati ododo rẹ ni ilẹ igbagbe?
12 Shall thy wonders be known in the dark? and thy righteousness in the land of forgetfulness?
13 Ṣugbọn iwọ ni mo kigbe si, Oluwa; ati ni kutukutu owurọ li adura mi yio ṣaju rẹ.
13 But unto thee have I cried, O LORD; and in the morning shall my prayer prevent thee.
14 Oluwa, ẽṣe ti iwọ fi ṣa ọkàn mi tì? ẽṣe ti iwọ fi pa oju rẹ mọ́ kuro lọdọ mi?
14 LORD, why castest thou off my soul? why hidest thou thy face from me?
15 Iṣẹ́ nṣẹ mi, emi mura ati kú lati igba ewe mi wá: nigbati ẹ̀ru rẹ ba mbà mi, emi di gbéregbère.
15 I am afflicted and ready to die from my youth up: while I suffer thy terrors I am distracted.
16 Ifẹju ibinu rẹ kọja lara mi; ìbẹru rẹ ti ke mi kuro.
16 Thy fierce wrath goeth over me; thy terrors have cut me off.
17 Nwọn wá yi mi ka li ọjọ gbogbo bi omi: nwọn yi mi kakiri tan.
17 They came round about me daily like water; they compassed me about together.
18 Olufẹ ati ọrẹ ni iwọ mu jina si mi, ati awọn ojulumọ mi ninu okunkun.
18 Lover and friend hast thou put far from me, and mine acquaintance into darkness.