Skip to content

Psalms 86 - Listen Online

Loading Bible...
Read Psalms 86

1 OLUWA, dẹ eti rẹ silẹ, gbohùn mi: nitori ti emi jẹ́ talaka ati alaini.

1 Bow down thine ear, O LORD, hear me: for I am poor and needy.

2 Pa ọkàn mi mọ́; nitori emi li ẹniti iwọ ṣe ojurere fun: iwọ, Ọlọrun mi, gbà ọmọ ọdọ rẹ ti o gbẹkẹle ọ.

2 Preserve my soul; for I am holy: O thou my God, save thy servant that trusteth in thee.

3 Ṣãnu fun mi, Oluwa: nitori iwọ li emi nkepè lojojumọ.

3 Be merciful unto me, O Lord: for I cry unto thee daily.

4 Mu ọkàn iranṣẹ rẹ yọ̀: Oluwa, nitori iwọ ni mo gbé ọkàn mi soke si.

4 Rejoice the soul of thy servant: for unto thee, O Lord, do I lift up my soul.

5 Nitori iwọ, Oluwa, o ṣeun, o si mura ati dariji; o si pọ̀ li ãnu fun gbogbo awọn ti nkepè ọ.

5 For thou, Lord, art good, and ready to forgive; and plenteous in mercy unto all them that call upon thee.

6 Oluwa, fi eti si adura mi; ki o si fiye si ohùn ẹ̀bẹ mi.

6 Give ear, O LORD, unto my prayer; and attend to the voice of my supplications.

7 Li ọjọ ipọnju mi, emi o kepè ọ: nitori ti iwọ o da mi lohùn.

7 In the day of my trouble I will call upon thee: for thou wilt answer me.

8 Oluwa, ninu awọn oriṣa kò si ọ̀kan ti o dabi rẹ, bẹ̃ni kò si iṣẹ kan ti o dabi iṣẹ rẹ.

8 Among the gods there is none like unto thee, O Lord; neither are there any works like unto thy works.

9 Gbogbo awọn orilẹ-ède ti iwọ da ni yio wá, nwọn o si sìn niwaju rẹ, Oluwa; nwọn o si ma fi ogo fun orukọ rẹ.

9 All nations whom thou hast made shall come and worship before thee, O Lord; and shall glorify thy name.

10 Nitoripe iwọ pọ̀, iwọ si nṣe ohun iyanu: iwọ nikan li Ọlọrun.

10 For thou art great, and doest wondrous things: thou art God alone.

11 Oluwa, kọ́ mi li ọ̀na rẹ; emi o ma rìn ninu otitọ rẹ: mu aiya mi ṣọkan lati bẹ̀ru orukọ rẹ.

11 Teach me thy way, O LORD; I will walk in thy truth: unite my heart to fear thy name.

12 Emi o yìn ọ, Oluwa Ọlọrun mi, tinutinu mi gbogbo: emi o si ma fi ogo fun orukọ rẹ titi lai.

12 I will praise thee, O Lord my God, with all my heart: and I will glorify thy name for evermore.

13 Nitoripe nla li ãnu rẹ si mi: iwọ si ti gbà ọkàn mi lọwọ isa-okú jijin.

13 For great is thy mercy toward me: and thou hast delivered my soul from the lowest hell.

14 Ọlọrun, awọn agberaga dide si mi, ati ijọ awọn alagbara nwá ọkàn mi kiri; nwọn kò si fi ọ pè li oju wọn.

14 O God, the proud are risen against me, and the assemblies of violent men have sought after my soul; and have not set thee before them.

15 Ṣugbọn iwọ, Oluwa, li Ọlọrun ti o kún fun iyọ́nu, ati olore-ọfẹ, olupamọra, o si pọ̀ li ãnu ati otitọ.

15 But thou, O Lord, art a God full of compassion, and gracious, longsuffering, and plenteous in mercy and truth.

16 Yipada si mi ki o si ṣãnu fun mi; fi ipá rẹ fun iranṣẹ rẹ, ki o si gbà ọmọkunrin iranṣẹ-birin rẹ là.

16 O turn unto me, and have mercy upon me; give thy strength unto thy servant, and save the son of thine handmaid.

17 Fi àmi hàn mi fun rere; ki awọn ti o korira mi ki o le ri i, ki oju ki o le tì wọn, nitori iwọ, Oluwa, li o ti ràn mi lọwọ ti o si tù mi ninu.

17 Shew me a token for good; that they which hate me may see it, and be ashamed: because thou, LORD, hast holpen me, and comforted me.