Skip to content

Psalms 85 - Listen Online

Loading Bible...
Read Psalms 85

1 OLUWA, iwọ ti nṣe oju rere si ilẹ rẹ: iwọ ti mu igbekun Jakobu pada bọ̀.

1 LORD, thou hast been favourable unto thy land: thou hast brought back the captivity of Jacob.

2 Iwọ ti dari aiṣedede awọn enia rẹ jì, iwọ ti bò gbogbo ẹ̀ṣẹ wọn mọlẹ.

2 Thou hast forgiven the iniquity of thy people, thou hast covered all their sin. Selah.

3 Iwọ ti mu gbogbo ibinu rẹ kuro: iwọ ti yipada kuro ninu gbigbona ibinu rẹ.

3 Thou hast taken away all thy wrath: thou hast turned thyself from the fierceness of thine anger.

4 Yi wa pada, Ọlọrun igbala wa, ki o si mu ibinu rẹ si wa ki o dá.

4 Turn us, O God of our salvation, and cause thine anger toward us to cease.

5 Iwọ o binu si wa titi lai? iwọ o fà ibinu rẹ jade lati irandiran?

5 Wilt thou be angry with us for ever? wilt thou draw out thine anger to all generations?

6 Iwọ kì yio tun mu wa sọji: ki awọn enia rẹ ki o ma yọ̀ ninu rẹ?

6 Wilt thou not revive us again: that thy people may rejoice in thee?

7 Oluwa fi ãnu rẹ hàn fun wa, ki o si fun wa ni igbala rẹ.

7 Shew us thy mercy, O LORD, and grant us thy salvation.

8 Emi o gbọ́ bi Ọlọrun Oluwa yio ti wi: nitoriti yio sọ alafia si awọn enia rẹ̀, ati si awọn enia mimọ́ rẹ̀: ṣugbọn ki nwọn ki o má tun pada si were.

8 I will hear what God the LORD will speak: for he will speak peace unto his people, and to his saints: but let them not turn again to folly.

9 Nitõtọ igbala rẹ̀ sunmọ́ awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀; ki ogo ki o le ma gbé ilẹ wa.

9 Surely his salvation is nigh them that fear him; that glory may dwell in our land.

10 Ãnu ati otitọ padera; ododo ati alafia ti fi ẹnu kò ara wọn li ẹnu.

10 Mercy and truth are met together; righteousness and peace have kissed each other.

11 Otitọ yio rú jade lati ilẹ wá: ododo yio si bojuwò ilẹ lati ọrun wá.

11 Truth shall spring out of the earth; and righteousness shall look down from heaven.

12 Nitõtọ Oluwa yio funni li eyi ti o dara; ilẹ wa yio si ma mu asunkun rẹ̀ wá.

12 Yea, the LORD shall give that which is good; and our land shall yield her increase.

13 Ododo yio ṣãju rẹ̀; yio si fi ipasẹ rẹ̀ ṣe ọ̀na.

13 Righteousness shall go before him; and shall set us in the way of his steps.