Psalms 84 - Listen Online
Read Psalms 84
1 AGỌ rẹ wọnni ti li ẹwà to, Oluwa awọn ọmọ-ogun!
1 How amiable are thy tabernacles, O LORD of hosts!
2 Ọkàn mi nfà nitõtọ, o tilẹ pe ongbẹ fun agbala Oluwa: aiya mi ati ara mi nkigbe si Ọlọrun alãye.
2 My soul longeth, yea, even fainteth for the courts of the LORD: my heart and my flesh crieth out for the living God.
3 Nitõtọ, ologoṣẹ ri ile, ati alapandẹdẹ tẹ́ itẹ fun ara rẹ̀, nibiti yio gbe ma pa awọn ọmọ rẹ̀ mọ́ si, ani ni pẹpẹ rẹ wọnni, Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọba mi ati Ọlọrun mi.
3 Yea, the sparrow hath found an house, and the swallow a nest for herself, where she may lay her young, even thine altars, O LORD of hosts, my King, and my God.
4 Ibukún ni fun awọn ti ngbe inu ile rẹ: nwọn o ma yìn ọ sibẹ.
4 Blessed are they that dwell in thy house: they will be still praising thee. Selah.
5 Ibukún ni fun enia na, ipá ẹniti o wà ninu rẹ: li ọkàn ẹniti ọ̀na rẹ wà.
5 Blessed is the man whose strength is in thee; in whose heart are the ways of them.
6 Awọn ti nla afonifoji omije lọ, nwọn sọ ọ di kanga; akọrọ-òjo si fi ibukún bò o.
6 Who passing through the valley of Baca make it a well; the rain also filleth the pools.
7 Nwọn nlọ lati ipá de ipá, ni Sioni ni awọn yọ niwaju Ọlọrun.
7 They go from strength to strength, every one of them in Zion appeareth before God.
8 Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, gbọ́ adura mi; fi eti si i, Ọlọrun Jakobu.
8 O LORD God of hosts, hear my prayer: give ear, O God of Jacob. Selah.
9 Kiyesi i, Ọlọrun asà wa, ki o si ṣiju wò oju Ẹni-ororo rẹ.
9 Behold, O God our shield, and look upon the face of thine anointed.
10 Nitori pe ọjọ kan ninu agbala rẹ sanju ẹgbẹrun ọjọ lọ. Mo fẹ ki nkuku ma ṣe adena ni ile Ọlọrun mi, jù lati ma gbe agọ ìwa-buburu.
10 For a day in thy courts is better than a thousand. I had rather be a doorkeeper in the house of my God, than to dwell in the tents of wickedness.
11 Nitori Oluwa Ọlọrun li õrun ati asà: Oluwa yio fun ni li ore-ọfẹ ati ogo: kò si ohun rere ti yio fà sẹhin lọwọ awọn ti nrìn dede.
11 For the LORD God is a sun and shield: the LORD will give grace and glory: no good thing will he withhold from them that walk uprightly.
12 Oluwa awọn ọmọ-ogun, ibukún ni fun oluwarẹ̀ na ti o gbẹkẹle ọ.
12 O LORD of hosts, blessed is the man that trusteth in thee.