Psalms 80 - Listen Online
Read Psalms 80
1 FI eti si ni, Oluṣọ-agutan Israeli, iwọ ti o ndà Josefu bi ọwọ́-agutan; iwọ ti o joko lãrin awọn kerubu tàn imọlẹ jade.
1 Give ear, O Shepherd of Israel, thou that leadest Joseph like a flock; thou that dwellest between the cherubims, shine forth.
2 Niwaju Efraimu ati Benjamini ati Manasse rú ipa rẹ soke ki o si wá fun igbala wa.
2 Before Ephraim and Benjamin and Manasseh stir up thy strength, and come and save us.
3 Tún wa yipada, Ọlọrun, ki o si mu oju rẹ tàn imọlẹ; a o si gbà wa là.
3 Turn us again, O God, and cause thy face to shine; and we shall be saved.
4 Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, iwọ o ti binu pẹ to si adura awọn enia rẹ?
4 O LORD God of hosts, how long wilt thou be angry against the prayer of thy people?
5 Iwọ fi onjẹ omije bọ́ wọn; iwọ si fun wọn li omije mu li ọ̀pọlọpọ.
5 Thou feedest them with the bread of tears; and givest them tears to drink in great measure.
6 Iwọ sọ wa di ijà fun awọn aladugbo wa: awọn ọta wa si nrẹrin ninu ara wọn.
6 Thou makest us a strife unto our neighbours: and our enemies laugh among themselves.
7 Tún wa yipada, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, ki o si mu oju rẹ tàn imọlẹ; a o si gbà wa là.
7 Turn us again, O God of hosts, and cause thy face to shine; and we shall be saved.
8 Iwọ ti mu ajara kan jade ti Egipti wá: iwọ ti tì awọn keferi jade, iwọ si gbin i.
8 Thou hast brought a vine out of Egypt: thou hast cast out the heathen, and planted it.
9 Iwọ ṣe àye silẹ fun u, iwọ si mu u ta gbòngbo jinlẹ̀, o si kún ilẹ na.
9 Thou preparedst room before it, and didst cause it to take deep root, and it filled the land.
10 A fi ojiji rẹ̀ bò awọn òke mọlẹ, ati ẹka rẹ̀ dabi igi kedari Ọlọrun.
10 The hills were covered with the shadow of it, and the boughs thereof were like the goodly cedars.
11 O yọ ẹka rẹ̀ sinu okun, ati ọwọ rẹ̀ si odò nla nì.
11 She sent out her boughs unto the sea, and her branches unto the river.
12 Ẽṣe ti iwọ ha fi ya ọgbà rẹ̀ bẹ̃, ti gbogbo awọn ẹniti nkọja lọ li ọ̀na nká a?
12 Why hast thou then broken down her hedges, so that all they which pass by the way do pluck her?
13 Imado lati inu igbo wá mba a jẹ, ati ẹranko igbẹ njẹ ẹ run.
13 The boar out of the wood doth waste it, and the wild beast of the field doth devour it.
14 Yipada, awa mbẹ ọ, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun: wolẹ lati ọrun wá, ki o si wò o, ki o si bẹ àjara yi wò:
14 Return, we beseech thee, O God of hosts: look down from heaven, and behold, and visit this vine;
15 Ati agbala-àjara ti ọwọ ọtún rẹ ti gbin, ati ọmọ ti iwọ ti mule fun ara rẹ.
15 And the vineyard which thy right hand hath planted, and the branch that thou madest strong for thyself.
16 O jona, a ke e lulẹ: nwọn ṣegbe nipa ibawi oju rẹ.
16 It is burned with fire, it is cut down: they perish at the rebuke of thy countenance.
17 Jẹ ki ọwọ rẹ ki o wà lara ọkunrin ọwọ ọtún rẹ nì, lara ọmọ-enia ti iwọ ti mule fun ara rẹ.
17 Let thy hand be upon the man of thy right hand, upon the son of man whom thou madest strong for thyself.
18 Bẹ̃li awa kì yio pada sẹhin kuro lọdọ rẹ: mu wa yè, awa o si ma pè orukọ rẹ.
18 So will not we go back from thee: quicken us, and we will call upon thy name.
19 Tún wa yipada, Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, mu oju rẹ tàn imọlẹ; a o si gbà wa là.
19 Turn us again, O LORD God of hosts, cause thy face to shine; and we shall be saved.