Skip to content

Psalms 43 - Listen Online

Loading Bible...
Read Psalms 43

1 ṢE idajọ mi, Ọlọrun, ki o si gbà ọ̀ran mi rò si alailãnu orilẹ-ède: gbà mi lọwọ ẹlẹtan ati ọkunrin alaiṣõtọ nì.

1 Judge me, O God, and plead my cause against an ungodly nation: O deliver me from the deceitful and unjust man.

2 Nitori iwọ li Ọlọrun agbara mi: ẽṣe ti iwọ fi ṣa mi tì? ẽṣe ti emi fi nrìn ni igbawẹ nitori inilara ọta nì.

2 For thou art the God of my strength: why dost thou cast me off? why go I mourning because of the oppression of the enemy?

3 Rán imọlẹ rẹ ati otitọ rẹ jade, ki nwọn ki o ma ṣe amọna mi: ki nwọn ki o mu mi gùn òke mimọ́ rẹ, ati sinu agọ rẹ wọnni.

3 O send out thy light and thy truth: let them lead me; let them bring me unto thy holy hill, and to thy tabernacles.

4 Nigbana li emi o lọ si ibi pẹpẹ Ọlọrun, sọdọ Ọlọrun ayọ̀ nla mi: nitõtọ, lara duru li emi o ma yìn ọ, Ọlọrun, Ọlọrun mi.

4 Then will I go unto the altar of God, unto God my exceeding joy: yea, upon the harp will I praise thee, O God my God.

5 Ẽṣe ti ori rẹ fi tẹ̀ba, iwọ ọkàn mi? ẽṣe ti ara rẹ kò fi lelẹ ninu mi? iwọ ṣe ireti niti Ọlọrun: nitoriti emi o sa ma yìn i sibẹ, ẹniti iṣe iranlọwọ oju mi, ati Ọlọrun mi.

5 Why art thou cast down, O my soul? and why art thou disquieted within me? hope in God: for I shall yet praise him, who is the health of my countenance, and my God.