Psalms 41 - Listen Online
Read Psalms 41
1 IBUKÚN ni fun ẹniti nrò ti awọn alaini, Oluwa yio gbà a ni ìgbà ipọnju.
1 Blessed is he that considereth the poor: the LORD will deliver him in time of trouble.
2 Oluwa yio pa a mọ́, yio si mu u wà lãye; a o si bukún fun u lori ilẹ: iwọ kì yio si fi i le ifẹ awọn ọta rẹ̀ lọwọ.
2 The LORD will preserve him, and keep him alive; and he shall be blessed upon the earth: and thou wilt not deliver him unto the will of his enemies.
3 Oluwa yio gbà a ni iyanju lori ẹní àrun: iwọ o tẹ ẹní rẹ̀ gbogbo ni ibulẹ arun rẹ̀.
3 The LORD will strengthen him upon the bed of languishing: thou wilt make all his bed in his sickness.
4 Emi wipe, Oluwa ṣãnu fun mi: mu ọkàn mi lara da; nitori ti mo ti ṣẹ̀ si ọ.
4 I said, LORD, be merciful unto me: heal my soul; for I have sinned against thee.
5 Awọn ọta mi nsọ ibi si mi pe, nigbawo ni on o kú, ti orukọ rẹ̀ yio si run?
5 Mine enemies speak evil of me, When shall he die, and his name perish?
6 Bi o ba si wá wò mi, on a ma sọ̀rọ ẹ̀tan: aiya rẹ̀ kó ẹ̀ṣẹ jọ si ara rẹ̀; nigbati o ba jade lọ, a ma wi i.
6 And if he come to see me, he speaketh vanity: his heart gathereth iniquity to itself; when he goeth abroad, he telleth it.
7 Gbogbo awọn ti o korira mi jumọ nsọ̀rọ kẹlẹ́ si mi: emi ni nwọn ngbìmọ ibi si.
7 All that hate me whisper together against me: against me do they devise my hurt.
8 Pe, ohun buburu li o dì mọ ọ ṣinṣin: ati ibiti o dubulẹ si, kì yio dide mọ.
8 An evil disease, say they, cleaveth fast unto him: and now that he lieth he shall rise up no more.
9 Nitõtọ ọrẹ-iyọrẹ ara mi, ẹniti mo gbẹkẹle, ẹniti njẹ ninu onjẹ mi, o gbe gigisẹ rẹ̀ si mi.
9 Yea, mine own familiar friend, in whom I trusted, which did eat of my bread, hath lifted up his heel against me.
10 Ṣugbọn iwọ, Oluwa, ṣãnu fun mi, ki o si gbé mi dide, ki emi ki o le san a fun wọn.
10 But thou, O LORD, be merciful unto me, and raise me up, that I may requite them.
11 Nipa eyi ni mo mọ̀ pe iwọ ṣe oju-rere si mi, nitoriti awọn ọta mi kò yọ̀ mi.
11 By this I know that thou favourest me, because mine enemy doth not triumph over me.
12 Bi o ṣe ti emi ni, iwọ dì mi mu ninu ìwatitọ mi, iwọ si gbé mi kalẹ niwaju rẹ titi lai.
12 And as for me, thou upholdest me in mine integrity, and settest me before thy face for ever.
13 Olubukún ni Oluwa, Ọlọrun Israeli, lailai titi lai. Amin, Amin.
13 Blessed be the LORD God of Israel from everlasting, and to everlasting. Amen, and Amen.