Skip to content

Psalms 100 - Listen Online

Loading Bible...
Read Psalms 100

1 Ẹ ho iho ayọ̀ si Oluwa, ẹnyin ilẹ gbogbo.

1 Make a joyful noise unto the LORD, all ye lands.

2 Ẹ fi ayọ̀ sìn Oluwa: ẹ wá ti ẹnyin ti orin si iwaju rẹ̀.

2 Serve the LORD with gladness: come before his presence with singing.

3 Ki ẹnyin ki o mọ̀ pe Oluwa, on li Ọlọrun: on li o dá wa, tirẹ̀ li awa; awa li enia rẹ̀, ati agutan papa rẹ̀.

3 Know ye that the LORD he is God: it is he that hath made us, and not we ourselves; we are his people, and the sheep of his pasture.

4 Ẹ lọ si ẹnu ọ̀na rẹ̀ ti ẹnyin ti ọpẹ, ati si agbala rẹ̀ ti ẹnyin ti iyìn: ẹ ma dupẹ fun u, ki ẹ si ma fi ibukún fun orukọ rẹ̀.

4 Enter into his gates with thanksgiving, and into his courts with praise: be thankful unto him, and bless his name.

5 Nitori ti Oluwa pọ̀ li ore; ãnu rẹ̀ kò nipẹkun; ati otitọ rẹ̀ lati iran-diran.

5 For the LORD is good; his mercy is everlasting; and his truth endureth to all generations.