Isaiah 39 - Listen Online
Read Isaiah 39
1 LI akoko na ni Merodaki-baladani, ọmọ Baladani, ọba Babiloni, rán iwe ati ọrẹ si Hesekiah: nitori o ti gbọ́ pe o ti ṣaisàn, o si ti sàn.
1 At that time Merodach-baladan, the son of Baladan, king of Babylon, sent letters and a present to Hezekiah: for he had heard that he had been sick, and was recovered.
2 Inu Hesekiah si dùn si wọn, o si fi ile iṣura hàn wọn, fadaka, ati wura, ati nkan olõrun didùn, ati ikunra iyebiye, ati ile gbogbo ìhamọra rẹ̀, ati ohun gbogbo ti a ri ninu iṣura rẹ̀: kò si si nkankan ti Hesekiah kò fi hàn wọn ninu ile rẹ̀, tabi ni ijọba rẹ̀.
2 And Hezekiah was glad of them, and shewed them the house of his precious things, the silver, and the gold, and the spices, and the precious ointment, and all the house of his armour, and all that was found in his treasures: there was nothing in his house, nor in all his dominion, that Hezekiah shewed them not.
3 Nigbana ni wolĩ Isaiah wá sọdọ Hesekiah ọba, o si wi fun u pe, Kini awọn ọkunrin wọnyi wi? ati lati ibo ni nwọn ti wá sọdọ rẹ? Hesekiah si wi pe, Lati ilẹ jijin ni nwọn ti wá sọdọ mi, ani lati Babiloni.
3 Then came Isaiah the prophet unto king Hezekiah, and said unto him, What said these men? and from whence came they unto thee? And Hezekiah said, They are come from a far country unto me, even from Babylon.
4 O si wipe, Kini nwọn ri ni ile rẹ? Hesekiah si dahùn pe, Ohun gbogbo ti o wà ni ile mi ni nwọn ti ri: kò si nkankan ti emi kò fi hàn wọn ninu iṣura mi.
4 Then said he, What have they seen in thine house? And Hezekiah answered, All that is in mine house have they seen: there is nothing among my treasures that I have not shewed them.
5 Nigbana ni Isaiah wi fun Hesekiah pe, Gbọ́ ọ̀rọ Oluwa awọn ọmọ-ogun:
5 Then said Isaiah to Hezekiah, Hear the word of the LORD of hosts:
6 Kiyesi i, ọjọ na dé, ti a o kó ohun gbogbo ti o wà ni ile rẹ, ati ohun ti awọn baba rẹ ti kojọ titi di oni, lọ si Babiloni: kò si nkankan ti yio kù, li Oluwa wi.
6 Behold, the days come, that all that is in thine house, and that which thy fathers have laid up in store until this day, shall be carried to Babylon: nothing shall be left, saith the LORD.
7 Ati ninu awọn ọmọ rẹ ọkunrin ti yio ti inu rẹ jade, ti iwọ o bi, ni nwọn o kó lọ: nwọn o si jẹ́ iwẹ̀fa ni ãfin ọba Babiloni.
7 And of thy sons that shall issue from thee, which thou shalt beget, shall they take away; and they shall be eunuchs in the palace of the king of Babylon.
8 Nigbana ni Hesekiah wi fun Isaiah pe, Rere ni ọ̀rọ Oluwa ti iwọ ti sọ. O si wi pẹlu pe, Alafia ati otitọ́ yio sa wà li ọjọ mi.
8 Then said Hezekiah to Isaiah, Good is the word of the LORD which thou hast spoken. He said moreover, For there shall be peace and truth in my days.