Ezekiel 6 - Listen Online
Read Ezekiel 6
1 Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,
1 And the word of the LORD came unto me, saying,
2 Ọmọ enia, kọju rẹ si awọn oke-nla Israeli, si sọtẹlẹ si wọn.
2 Son of man, set thy face toward the mountains of Israel, and prophesy against them,
3 Si wipe, Ẹnyin oke-nla Israeli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa Ọlọrun; bayi li Oluwa Ọlọrun wi si awọn oke-nla, si awọn oke kekeke, si awọn odò siṣàn, ati si awọn afonifoji; kiyesi i, Emi, ani Emi, o mu idà wá sori nyin, emi o si pa ibi giga nyin run.
3 And say, Ye mountains of Israel, hear the word of the Lord GOD; Thus saith the Lord GOD to the mountains, and to the hills, to the rivers, and to the valleys; Behold, I, even I, will bring a sword upon you, and I will destroy your high places.
4 Pẹpẹ nyin yio si di ahoro, ere nyin yio si fọ; okú nyin li emi o si gbe jù siwaju oriṣa nyin.
4 And your altars shall be desolate, and your images shall be broken: and I will cast down your slain men before your idols.
5 Emi o si tẹ́ okú awọn ọmọ Israeli siwaju oriṣa wọn; emi o si tú egungun nyin ka yi pẹpẹ nyin ka.
5 And I will lay the dead carcases of the children of Israel before their idols; and I will scatter your bones round about your altars.
6 Ilu-nla li a o parun ninu gbogbo ibugbe nyin, ibi giga yio si di ahoro: ki a le run pẹpẹ nyin, ki a si sọ ọ di ahoro, ki a si le fọ́ oriṣa nyin, ki o si tan, ki a si le ké ere nyin lu ilẹ, ki iṣẹ́ nyin si le parẹ.
6 In all your dwellingplaces the cities shall be laid waste, and the high places shall be desolate; that your altars may be laid waste and made desolate, and your idols may be broken and cease, and your images may be cut down, and your works may be abolished.
7 Okú yio si ṣubu li ãrin nyin, ẹnyin o si mọ̀ pe, Emi li Oluwa.
7 And the slain shall fall in the midst of you, and ye shall know that I am the LORD.
8 Ṣugbọn emi o fi iyokú silẹ, ki ẹnyin le ni diẹ ti yio bọ́ lọwọ idà lãrin awọn orilẹ-ède, nigbati a o tú nyin ka gbogbo ilẹ.
8 Yet will I leave a remnant, that ye may have some that shall escape the sword among the nations, when ye shall be scattered through the countries.
9 Awọn ti o bọ́ ninu nyin yio si ranti mi, lãrin awọn orilẹ-ède nibiti nwọn o gbe dì wọn ni igbekun lọ, nitoriti mo ti fọ́ ọkàn agbere wọn ti o ti lọ kuro lọdọ mi, ati pẹlu oju wọn, ti nṣagbere lọ sọdọ oriṣa wọn: nwọn o si sú ara wọn nitori ìwa ibi ti nwọn ti hù ninu gbogbo irira wọn.
9 And they that escape of you shall remember me among the nations whither they shall be carried captives, because I am broken with their whorish heart, which hath departed from me, and with their eyes, which go a whoring after their idols: and they shall lothe themselves for the evils which they have committed in all their abominations.
10 Nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa, emi kò wi lasan pe, emi o ṣe ibi yi si wọn.
10 And they shall know that I am the LORD, and that I have not said in vain that I would do this evil unto them.
11 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; pàtẹwọ rẹ, si fi ẹsẹ rẹ kì ilẹ; si wipe, o ṣe! fun gbogbo irira buburu ilẹ Israeli, nitori nwọn o ṣubu nipa idà, nipa ìyan, ati nipa ajakalẹ àrun.
11 Thus saith the Lord GOD; Smite with thine hand, and stamp with thy foot, and say, Alas for all the evil abominations of the house of Israel! for they shall fall by the sword, by the famine, and by the pestilence.
12 Ẹniti o jina rere yio kú nipa ajakalẹ àrun; ati ẹniti o sunmọ tosí yio ṣubu nipa idà; ati ẹniti o kù ti a si do tì yio kú nipa iyàn: bayi li emi o mu irunu mi ṣẹ lori wọn.
12 He that is far off shall die of the pestilence; and he that is near shall fall by the sword; and he that remaineth and is besieged shall die by the famine: thus will I accomplish my fury upon them.
13 Nigbana li ẹnyin o mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati okú wọn yio wà larin ere wọn yi pẹpẹ wọn ka, lori oke kekeke gbogbo, lori ṣonṣo ori oke giga gbogbo, ati labẹ igi tutu gbogbo, ati labẹ gbogbo igi oaku bibò, ibiti nwọn ti rubọ õrùn didùn si gbogbo ere wọn.
13 Then shall ye know that I am the LORD, when their slain men shall be among their idols round about their altars, upon every high hill, in all the tops of the mountains, and under every green tree, and under every thick oak, the place where they did offer sweet savour to all their idols.
14 Bẹ̃ li emi o nà ọwọ́ mi jade sori wọn, emi o si sọ ilẹ na di ahoro, nitotọ, yio di ahoro jù aginju iha Diblati lọ, ninu gbogbo ibugbe wọn: nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
14 So will I stretch out my hand upon them, and make the land desolate, yea, more desolate than the wilderness toward Diblath, in all their habitations: and they shall know that I am the LORD.