Exodus 25 - Listen Online
Read Exodus 25
1 OLUWA si sọ fun Mose pe,
1 And the LORD spake unto Moses, saying,
2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, ki nwọn ki o mú ọrẹ fun mi wá: lọwọ olukuluku enia ti o ba fifunni tinutinu ni ki ẹnyin ki o gbà ọrẹ mi.
2 Speak unto the children of Israel, that they bring me an offering: of every man that giveth it willingly with his heart ye shall take my offering.
3 Eyi si li ọrẹ ti ẹnyin o gbà lọwọ wọn; wurà, ati fadakà, ati idẹ;
3 And this is the offering which ye shall take of them; gold, and silver, and brass,
4 Ati aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ, ati irun ewurẹ;
4 And blue, and purple, and scarlet, and fine linen, and goats' hair,
5 Ati awọ àgbo ti a sè ni pupa, ati awọ seali, ati igi ṣittimu.
5 And rams' skins dyed red, and badgers' skins, and shittim wood,
6 Oróro fun fitila, olõrùn fun oróro itasori, ati fun turari didùn;
6 Oil for the light, spices for anointing oil, and for sweet incense,
7 Okuta oniki, ati okuta ti a o tò si ẹ̀wu-efodi, ati si igbàiya.
7 Onyx stones, and stones to be set in the ephod, and in the breastplate.
8 Ki nwọn ki o si ṣe ibi mimọ́ kan fun mi; ki emi ki o le ma gbé ãrin wọn.
8 And let them make me a sanctuary; that I may dwell among them.
9 Gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo fihàn ọ, nipa apẹrẹ agọ́, ati apẹrẹ gbogbo ohunèlo inu rẹ̀, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o si ṣe e.
9 According to all that I shew thee, after the pattern of the tabernacle, and the pattern of all the instruments thereof, even so shall ye make it.
10 Nwọn o si ṣe apoti igi ṣittimu: igbọnwọ meji on àbọ ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan on àbọ ni ibú rẹ̀, ati igbọnwọ kan on àbọ ni giga rẹ̀.
10 And they shall make an ark of shittim wood: two cubits and a half shall be the length thereof, and a cubit and a half the breadth thereof, and a cubit and a half the height thereof.
11 Iwọ o si fi kìki wurà bò o, ninu ati lode ni iwọ o fi bò o, iwọ o si ṣe igbáti wurà sori rẹ̀ yiká.
11 And thou shalt overlay it with pure gold, within and without shalt thou overlay it, and shalt make upon it a crown of gold round about.
12 Iwọ o si ṣe oruka wurà mẹrin si i, iwọ o si fi wọn si igun mẹrin rẹ̀; oruka meji yio si wà li apa kini rẹ̀, oruka meji yio si wà li apa keji rẹ̀.
12 And thou shalt cast four rings of gold for it, and put them in the four corners thereof; and two rings shall be in the one side of it, and two rings in the other side of it.
13 Iwọ o si ṣe ọpá ṣittimu, ki iwọ ki o si fi wurà bò wọn.
13 And thou shalt make staves of shittim wood, and overlay them with gold.
14 Iwọ o si fi ọpá wọnni bọ̀ inu oruka wọnni ni ìha apoti na, ki a le ma fi wọn gbé apoti na.
14 And thou shalt put the staves into the rings by the sides of the ark, that the ark may be borne with them.
15 Ọpá wọnni yio si ma wà ninu oruka apoti na: a ki yio si yọ wọn kuro ninu rẹ̀.
15 The staves shall be in the rings of the ark: they shall not be taken from it.
16 Iwọ o si fi ẹrí ti emi o fi fun ọ sinu apoti nì.
16 And thou shalt put into the ark the testimony which I shall give thee.
17 Iwọ o si fi kìki wurà ṣe itẹ-anu: igbọnwọ meji on àbọ ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan on àbọ ni ibú rẹ̀.
17 And thou shalt make a mercy seat of pure gold: two cubits and a half shall be the length thereof, and a cubit and a half the breadth thereof.
18 Iwọ o si ṣe kerubu wurà meji; ni iṣẹ lilù ni ki iwọ ki o fi ṣe wọn, ni ìku itẹ́-ãnu na mejeji.
18 And thou shalt make two cherubims of gold, of beaten work shalt thou make them, in the two ends of the mercy seat.
19 Si ṣe kerubu kini ni ìku kan, ati kerubu keji ni ìku keji: lati itẹ́-ãnu ni ki ẹnyin ki o ṣe awọn kerubu na ni ìku rẹ̀ mejeji.
19 And make one cherub on the one end, and the other cherub on the other end: even of the mercy seat shall ye make the cherubims on the two ends thereof.
20 Awọn kerubu na yio si nà iyẹ́-apa wọn si oke, ki nwọn ki o fi iyẹ́-apa wọn bò itẹ́-ãnu na, ki nwọn ki o si kọjusi ara wọn; itẹ́-ãnu na ni ki awọn kerubu na ki o kọjusi.
20 And the cherubims shall stretch forth their wings on high, covering the mercy seat with their wings, and their faces shall look one to another; toward the mercy seat shall the faces of the cherubims be.
21 Iwọ o si fi itẹ́-ãnu na sori apoti na; ati ninu apoti na ni iwọ o fi ẹri ti emi o fi fun ọ si.
21 And thou shalt put the mercy seat above upon the ark; and in the ark thou shalt put the testimony that I shall give thee.
22 Nibẹ̀ li emi o ma pade rẹ, emi o si ma bá ọ sọ̀rọ lati oke itẹ́-ãnu wá, lati ãrin awọn kerubu mejeji wá, ti o wà lori apoti ẹrí na, niti ohun gbogbo ti emi o palaṣẹ fun ọ si awọn ọmọ Israeli.
22 And there I will meet with thee, and I will commune with thee from above the mercy seat, from between the two cherubims which are upon the ark of the testimony, of all things which I will give thee in commandment unto the children of Israel.
23 Iwọ o si ṣe tabili igi ṣittimu kan: igbọnwọ meji ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan ni ibú rẹ̀, ati igbọnwọ kan on àbọ ni giga rẹ̀.
23 Thou shalt also make a table of shittim wood: two cubits shall be the length thereof, and a cubit the breadth thereof, and a cubit and a half the height thereof.
24 Iwọ o si fi kìki wurà bò o, iwọ o si ṣe igbáti wurà si i yiká.
24 And thou shalt overlay it with pure gold, and make thereto a crown of gold round about.
25 Iwọ o si ṣe eti kan bi ibú-atẹlẹwọ si i yiká, iwọ o si ṣe igbáti wurà si eti rẹ̀ yiká.
25 And thou shalt make unto it a border of an hand breadth round about, and thou shalt make a golden crown to the border thereof round about.
26 Iwọ o si ṣe oruka wurà mẹrin si i, iwọ o si fi oruka wọnni si igun mẹrẹrin, ti o wà li ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹrẹrin.
26 And thou shalt make for it four rings of gold, and put the rings in the four corners that are on the four feet thereof.
27 Li abẹ igbáti na li oruka wọnni yio wà, fun ibi ọpá lati ma fi rù tabili na.
27 Over against the border shall the rings be for places of the staves to bear the table.
28 Iwọ o si ṣe ọpá igi ṣittimu, iwọ o si fi wurà bò wọn, ki a le ma fi wọn rù tabili na.
28 And thou shalt make the staves of shittim wood, and overlay them with gold, that the table may be borne with them.
29 Iwọ o si ṣe awopọkọ rẹ̀, ati ṣibi rẹ̀, ati ìgo rẹ̀, ati awo rẹ̀, lati ma fi dà: kìki wurà ni ki iwọ ki o fi ṣe wọn.
29 And thou shalt make the dishes thereof, and spoons thereof, and covers thereof, and bowls thereof, to cover withal: of pure gold shalt thou make them.
30 Iwọ o si ma gbé àkara ifihàn kalẹ lori tabili na niwaju mi nigbagbogbo.
30 And thou shalt set upon the table shewbread before me alway.
31 Iwọ o si fi kìki wurà ṣe ọpá-fitila kan: iṣẹlilù li a o fi ṣe ọpá-fitila na, ipilẹ rẹ̀, ọpá rẹ̀; ago rẹ̀, irudi rẹ̀, ati itanna rẹ̀, ọkanna ni nwọn o jẹ́:
31 And thou shalt make a candlestick of pure gold: of beaten work shall the candlestick be made: his shaft, and his branches, his bowls, his knops, and his flowers, shall be of the same.
32 Ẹka mẹfa ni yio yọ ni ìha rẹ̀; ẹka mẹta ọpá-fitila na ni ìha kan, ati ẹka mẹta ọpá-fitila na ni ìha keji:
32 And six branches shall come out of the sides of it; three branches of the candlestick out of the one side, and three branches of the candlestick out of the other side:
33 Ago mẹta ni ki a ṣe bi itanna almondi, pẹlu irudi ati itanna li ẹka kan; ati ago mẹta ti a ṣe bi itanna almondi li ẹka ekeji, pẹlu irudi ati itanna: bẹ̃li ẹka mẹfẹ̃fa ti o yọ lara ọpá-fitila na.
33 Three bowls made like unto almonds, with a knop and a flower in one branch; and three bowls made like almonds in the other branch, with a knop and a flower: so in the six branches that come out of the candlestick.
34 Ati ninu ọpá-fitila na li ago mẹrin yio wà ti a ṣe bi itanna almondi, pẹlu irudi wọn ati itanna wọn.
34 And in the candlestick shall be four bowls made like unto almonds, with their knops and their flowers.
35 Irudi kan yio si wà nisalẹ ẹka rẹ̀ meji ki o ri bakanna, irudi kan yio si wà nisalẹ ẹka rẹ̀ meji ki o ri bakanna, irudi kan yio si wà nisalẹ ẹka rẹ̀ meji ki o ri bakanna, gẹgẹ bi ẹka rẹ̀ mẹfẹfa ti o ti ara ọpá-fitila na yọ jade.
35 And there shall be a knop under two branches of the same, and a knop under two branches of the same, and a knop under two branches of the same, according to the six branches that proceed out of the candlestick.
36 Irudi wọn ati ẹka wọn ki o ri bakanna: ki gbogbo rẹ̀ ki o jẹ́ lilù kìki wurà kan.
36 Their knops and their branches shall be of the same: all it shall be one beaten work of pure gold.
37 Iwọ o si ṣe fitila rẹ̀ na, meje: ki nwọn ki o si fi fitila wọnni sori rẹ̀, ki nwọn ki o le ma ṣe imọlẹ si iwaju rẹ̀.
37 And thou shalt make the seven lamps thereof: and they shall light the lamps thereof, that they may give light over against it.
38 Ati alumagaji rẹ̀, ati awo alumagaji rẹ̀, kìki wurà ni ki o jẹ́.
38 And the tongs thereof, and the snuffdishes thereof, shall be of pure gold.
39 Talenti kan kìki wurà ni ki o fi ṣe e, pẹlu gbogbo ohunèlo wọnyi.
39 Of a talent of pure gold shall he make it, with all these vessels.
40 Si kiyesi i, ki iwọ ki o ṣe wọn gẹgẹ bi apẹrẹ wọn, ti a fihàn ọ lori oke.
40 And look that thou make them after their pattern, which was shewed thee in the mount.