Exodus 26 - Listen Online
Read Exodus 26
1 IWỌ o fi aṣọ-tita mẹwa ṣe agọ́ na; aṣọ ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ati ti aṣọ-alaró, ati ti elesè-àluko, ati ti ododó, ti on ti awọn kerubu iṣẹ ọlọnà ni ki iwọ ki o ṣe wọn.
1 Moreover thou shalt make the tabernacle with ten curtains of fine twined linen, and blue, and purple, and scarlet: with cherubims of cunning work shalt thou make them.
2 Ina aṣọ-tita kan ki o jẹ́ igbọnwọ mejidilọgbọ̀n, ibò aṣọ-tita kan igbọnwọ mẹrin: gbogbo aṣọ-tita na ni ki o jẹ́ ìwọn kanna.
2 The length of one curtain shall be eight and twenty cubits, and the breadth of one curtain four cubits: and every one of the curtains shall have one measure.
3 Aṣọ-tita marun ni ki a solù mọ́ ara wọn; ati aṣọ-tita marun keji ni ki a solù mọ́ ara wọn.
3 The five curtains shall be coupled together one to another; and other five curtains shall be coupled one to another.
4 Iwọ o si ṣe ojóbo aṣọ-alaró si eti aṣọ-tita kan lati iṣẹti rẹ̀ wá ni ibi isolù, ati bẹ̃ gẹgẹ ni iwọ o ṣe li eti ikangun aṣọ-tita keji, ni ibi isolù keji.
4 And thou shalt make loops of blue upon the edge of the one curtain from the selvedge in the coupling; and likewise shalt thou make in the uttermost edge of another curtain, in the coupling of the second.
5 Ãdọta ojóbo ni ki iwọ ki o ṣe si aṣọ-tita kan, ãdọta ojóbo ni ki iwọ ki o si ṣe si eti aṣọ-tita ti o wà ni isolù keji; ki ojóbo ki o le kọ́ ara wọn.
5 Fifty loops shalt thou make in the one curtain, and fifty loops shalt thou make in the edge of the curtain that is in the coupling of the second; that the loops may take hold one of another.
6 Iwọ o si ṣe ãdọta ikọ́ wurà, iwọ o si fi ikọ́ na fà awọn aṣọ-tita so: on o si jẹ́ agọ́ kan.
6 And thou shalt make fifty taches of gold, and couple the curtains together with the taches: and it shall be one tabernacle.
7 Iwọ o si ṣe aṣọ-tita irun ewurẹ, lati ṣe ibori sori agọ́ na: aṣọ-tita mọkanla ni iwọ o ṣe e.
7 And thou shalt make curtains of goats' hair to be a covering upon the tabernacle: eleven curtains shalt thou make.
8 Ìna aṣọ-tita kan yio jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ, ati ibò aṣọ-tita kan yio jẹ́ igbọnwọ mẹrin: aṣọ-tita mọkọkanla na yio si jẹ́ ìwọn kanna.
8 The length of one curtain shall be thirty cubits, and the breadth of one curtain four cubits: and the eleven curtains shall be all of one measure.
9 Iwọ o si so aṣọ-tita marun lù mọ́ ara wọn li ọ̀tọ, ati aṣọ-tita mẹfa lù mọ́ ara wọn li ọ̀tọ, iwọ o si ṣẹ aṣọ-tita kẹfa po ni meji niwaju agọ́ na.
9 And thou shalt couple five curtains by themselves, and six curtains by themselves, and shalt double the sixth curtain in the forefront of the tabernacle.
10 Iwọ o si ṣe ãdọta ojóbo li eti aṣọ-tita na, ti o yọ si ode jù ninu isolù, ati ãdọta ojóbo li eti aṣọ-tita ti o so ekeji lù.
10 And thou shalt make fifty loops on the edge of the one curtain that is outmost in the coupling, and fifty loops in the edge of the curtain which coupleth the second.
11 Iwọ o si ṣe ãdọta ikọ́ idẹ, ki o si fi ikọ́ wọnni sinu ojóbo, ki o si fi so agọ́ na pọ̀, yio si jẹ́ ọkan.
11 And thou shalt make fifty taches of brass, and put the taches into the loops, and couple the tent together, that it may be one.
12 Ati iyokù ti o kù ninu aṣọ-tita agọ́ na, àbọ aṣọ-tita ti o kù, yio rọ̀ sori ẹhin agọ na.
12 And the remnant that remaineth of the curtains of the tent, the half curtain that remaineth, shall hang over the backside of the tabernacle.
13 Ati igbọnwọ kan li apa kan, ati igbọnwọ kan li apa keji, eyiti o kù ni ìna aṣọ-tita agọ́ na, yio si rọ̀ si ìha agọ́ na ni ìha ihin ati ni ìha ọhún, lati bò o.
13 And a cubit on the one side, and a cubit on the other side of that which remaineth in the length of the curtains of the tent, it shall hang over the sides of the tabernacle on this side and on that side, to cover it.
14 Iwọ o si ṣe ibori awọ àgbo ti a sè ni pupa fun agọ́ na, ati ibori awọ seali lori rẹ̀.
14 And thou shalt make a covering for the tent of rams' skins dyed red, and a covering above of badgers' skins.
15 Iwọ o si ṣe apáko igi ṣittimu fun agọ́ na li ogurodo.
15 And thou shalt make boards for the tabernacle of shittim wood standing up.
16 Igbọnwọ mẹwa ni gigùn apáko na, ati igbọnwọ kan on àbọ ni ibò apáko kan.
16 Ten cubits shall be the length of a board, and a cubit and a half shall be the breadth of one board.
17 Ìtẹbọ meji ni ki o wà li apáko kan, ti o tò li ẹsẹ-ẹsẹ̀ si ara wọn: bayi ni ki iwọ ki o ṣe si gbogbo apáko agọ́ na.
17 Two tenons shall there be in one board, set in order one against another: thus shalt thou make for all the boards of the tabernacle.
18 Iwọ o si ṣe apáko agọ́ na, ogún apáko ni ìha gusù si ìha gusù.
18 And thou shalt make the boards for the tabernacle, twenty boards on the south side southward.
19 Iwọ o si ṣe ogoji ihò-ìtẹbọ fadakà nisalẹ ogún apáko wọnni; ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko kan fun ìtẹbọ meji na, ati ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko keji fun ìtẹbọ meji na;
19 And thou shalt make forty sockets of silver under the twenty boards; two sockets under one board for his two tenons, and two sockets under another board for his two tenons.
20 Ati ìha keji agọ́ na ni ìha ariwa, ogún apáko ni yio wà nibẹ̀:
20 And for the second side of the tabernacle on the north side there shall be twenty boards:
21 Ati ogoji ihò-ìtẹbọ fadakà wọn; ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko na kan, ati ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko keji.
21 And their forty sockets of silver; two sockets under one board, and two sockets under another board.
22 Ati fun ìha agọ́ na ni ìha ìwọ-õrùn apáko mẹfa ni ki iwọ ki o ṣe.
22 And for the sides of the tabernacle westward thou shalt make six boards.
23 Ati apáko meji ni iwọ o ṣe fun igun agọ́ na ni ìha ẹhin rẹ̀.
23 And two boards shalt thou make for the corners of the tabernacle in the two sides.
24 A o si so wọn pọ̀ nisalẹ, a o si so wọn pọ̀ li oke ori rẹ̀ si oruka kan: bẹ̃ni yio si ṣe ti awọn mejeji; nwọn o si ṣe ti igun mejeji.
24 And they shall be coupled together beneath, and they shall be coupled together above the head of it unto one ring: thus shall it be for them both; they shall be for the two corners.
25 Nwọn o si jẹ́ apáko mẹjọ, ati ihò-ìtẹbọ fadakà wọn, ihò-ìtẹbọ mẹrindilogun; ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko kan, ati ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko keji.
25 And they shall be eight boards, and their sockets of silver, sixteen sockets; two sockets under one board, and two sockets under another board.
26 Iwọ o si ṣe ọpá idabu igi ṣittimu; marun fun apáko ìha kan agọ́ na,
26 And thou shalt make bars of shittim wood; five for the boards of the one side of the tabernacle,
27 Ati ọpá idabu marun fun apáko na ni ìha keji agọ́ na, ati ọpá idabu marun fun apáko na ni ìha agọ́ na, fun ìha mejeji ni ìha ìwọ-õrùn.
27 And five bars for the boards of the other side of the tabernacle, and five bars for the boards of the side of the tabernacle, for the two sides westward.
28 Ati ọpá ãrin li agbedemeji apáko wọnni yio ti ìku dé ìku.
28 And the middle bar in the midst of the boards shall reach from end to end.
29 Iwọ o si fi wurà bò apáko wọnni, iwọ o si fi wurà ṣe oruka wọn li àye fun ọpá idabu wọnni: iwọ o si fi wurà bò ọpá idabu wọnni.
29 And thou shalt overlay the boards with gold, and make their rings of gold for places for the bars: and thou shalt overlay the bars with gold.
30 Iwọ o si gbé agọ́ na ró, gẹgẹ bi apẹrẹ rẹ̀, ti a fihàn ọ lori oke.
30 And thou shalt rear up the tabernacle according to the fashion thereof which was shewed thee in the mount.
31 Iwọ o si ṣe aṣọ-ikele alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ ti iṣẹ ọlọnà: ti on ti awọn kerubu nì ki a ṣe e:
31 And thou shalt make a vail of blue, and purple, and scarlet, and fine twined linen of cunning work: with cherubims shall it be made:
32 Iwọ o si fi rọ̀ sara opó igi ṣittimu mẹrin, ti a fi wurà bò, wurà ni ikọ́ wọn lori ihò-ìtẹbọ fadakà mẹrẹrin na.
32 And thou shalt hang it upon four pillars of shittim wood overlaid with gold: their hooks shall be of gold, upon the four sockets of silver.
33 Iwọ o si ta aṣọ-ikele na si abẹ ikọ́ wọnni, ki iwọ ki o le mú apoti ẹrí nì wá si inu aṣọ-ikele nì: aṣọ-ikele nì ni yio si pinya lãrin ibi mimọ́ ati ibi mimọ́ julọ fun nyin.
33 And thou shalt hang up the vail under the taches, that thou mayest bring in thither within the vail the ark of the testimony: and the vail shall divide unto you between the holy place and the most holy.
34 Iwọ o si fi itẹ́-ãnu sori apoti ẹrí nì, ni ibi mimọ́ julọ.
34 And thou shalt put the mercy seat upon the ark of the testimony in the most holy place.
35 Iwọ o si gbé tabili na kà ẹhin ode aṣọ-ikele nì, ati ọpá-fitila nì kọjusi tabili na ni ìha agọ́ na ni ìha gusù: iwọ o si gbé tabili na kà ìha ariwa.
35 And thou shalt set the table without the vail, and the candlestick over against the table on the side of the tabernacle toward the south: and thou shalt put the table on the north side.
36 Iwọ o si ṣe aṣọ-tita kan fun ẹnu-ọ̀na agọ́ na, ti aṣọ-alaró, ti elesè-aluko, ti ododó, ati ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ti a fi iṣẹ abẹ́rẹ ṣe.
36 And thou shalt make an hanging for the door of the tent, of blue, and purple, and scarlet, and fine twined linen, wrought with needlework.
37 Iwọ o si ṣe opó igi ṣittimu marun fun aṣọ-tita na, ki o si fi wurà bò wọn; ati ikọ́ wọn wurà: iwọ o si dà ihò-ìtẹbọ idẹ marun fun wọn.
37 And thou shalt make for the hanging five pillars of shittim wood, and overlay them with gold, and their hooks shall be of gold: and thou shalt cast five sockets of brass for them.