Skip to content

Exodus 24 - Listen Online

Loading Bible...
Read Exodus 24

1 O SI wi fun Mose pe, Goke tọ̀ OLUWA wá, iwọ, ati Aaroni, Nadabu, ati Abihu, ati ãdọrin ninu awọn àgba Israeli; ki ẹnyin ki o si ma sìn li òkere rére.

1 And he said unto Moses, Come up unto the LORD, thou, and Aaron, Nadab, and Abihu, and seventy of the elders of Israel; and worship ye afar off.

2 Mose nikanṣoṣo ni yio si sunmọ OLUWA; ṣugbọn awọn wọnyi kò gbọdọ sunmọ tosi; bẹ̃li awọn enia kò gbọdọ bá a gòke lọ.

2 And Moses alone shall come near the LORD: but they shall not come nigh; neither shall the people go up with him.

3 Mose si wá o si sọ gbogbo ọ̀rọ OLUWA, ati gbogbo idajọ fun awọn enia: gbogbo enia si fi ohùn kan dahùn wipe, Gbogbo ọ̀rọ ti OLUWA wi li awa o ṣe.

3 And Moses came and told the people all the words of the LORD, and all the judgments: and all the people answered with one voice, and said, All the words which the LORD hath said will we do.

4 Mose si kọwe gbogbo ọ̀rọ OLUWA, o si dide ni kùtukutu owurọ̀, o si tẹ́ pẹpẹ kan nisalẹ òke na, o mọ ọwọ̀n mejila, gẹgẹ bi ẹ̀ya Israeli mejila.

4 And Moses wrote all the words of the LORD, and rose up early in the morning, and builded an altar under the hill, and twelve pillars, according to the twelve tribes of Israel.

5 O si rán awọn ọdọmọkunrin ninu awọn ọmọ Israeli, nwọn si ru ẹbọ sisun, nwọn si fi akọmalu ru ẹbọ alafia si OLUWA.

5 And he sent young men of the children of Israel, which offered burnt offerings, and sacrificed peace offerings of oxen unto the LORD.

6 Mose si mú àbọ ẹ̀jẹ na o si fi i sinu awokòto; ati àbọ ẹ̀jẹ na o fi wọ́n ara pẹpẹ na.

6 And Moses took half of the blood, and put it in basons; and half of the blood he sprinkled on the altar.

7 O si mú iwé majẹmu nì, o si kà a li eti awọn enia: nwọn si wipe, Gbogbo eyiti OLUWA wi li awa o ṣe, awa o si gbọràn.

7 And he took the book of the covenant, and read in the audience of the people: and they said, All that the LORD hath said will we do, and be obedient.

8 Mose si mú ẹ̀jẹ na, o si wọ́n ọ sara awọn enia, o si wipe, Kiyesi ẹ̀jẹ majẹmu, ti OLUWA bá nyin dá nipasẹ ọ̀rọ gbogbo wọnyi.

8 And Moses took the blood, and sprinkled it on the people, and said, Behold the blood of the covenant, which the LORD hath made with you concerning all these words.

9 Nigbana ni Mose, ati Aaroni, Nadabu, ati Abihu, ati ãdọrin ninu awọn àgba Israeli gòke lọ:

9 Then went up Moses, and Aaron, Nadab, and Abihu, and seventy of the elders of Israel:

10 Nwọn si ri Ọlọrun Israeli; bi iṣẹ okuta Safire wà li abẹ ẹsẹ̀ rẹ̀, o si dabi irisi ọrun ni imọ́toto rẹ̀.

10 And they saw the God of Israel: and there was under his feet as it were a paved work of a sapphire stone, and as it were the body of heaven in his clearness.

11 Kò si nà ọwọ́ rẹ̀ lé awọn ọlọlá ọmọ Israeli: nwọn si ri Ọlọrun, nwọn si jẹ, nwọn si mu.

11 And upon the nobles of the children of Israel he laid not his hand: also they saw God, and did eat and drink.

12 OLUWA si wi fun Mose pe, Gòke tọ̀ mi wá sori òke, ki o si duro nibẹ̀; emi o si fi walã okuta fun ọ, ati aṣẹ kan, ati ofin ti mo ti kọ, ki iwọ ki o le ma kọ́ wọn.

12 And the LORD said unto Moses, Come up to me into the mount, and be there: and I will give thee tables of stone, and a law, and commandments which I have written; that thou mayest teach them.

13 Mose si dide, ati Joṣua iranṣẹ rẹ̀: Mose si gòke lọ si oke Ọlọrun.

13 And Moses rose up, and his minister Joshua: and Moses went up into the mount of God.

14 O si wi fun awọn àgba na pe, Ẹ duro dè wa nihinyi, titi awa o fi tun pada tọ̀ nyin wá: si kiyesi i, Aaroni ati Huri mbẹ pẹlu nyin: bi ẹnikan ba li ọ̀ran kan, ki o tọ̀ wọn wá.

14 And he said unto the elders, Tarry ye here for us, until we come again unto you: and, behold, Aaron and Hur are with you: if any man have any matters to do, let him come unto them.

15 Mose si gòke lọ sori òke na, awọsanma si bò òke na mọlẹ.

15 And Moses went up into the mount, and a cloud covered the mount.

16 Ogo OLUWA si sọkalẹ sori òke Sinai, awọsanma na si bò o mọlẹ ni ijọ́ mẹfa: ni ijọ́ keje o ké si Mose lati ãrin awọsanma wá.

16 And the glory of the LORD abode upon mount Sinai, and the cloud covered it six days: and the seventh day he called unto Moses out of the midst of the cloud.

17 Iwò ogo OLUWA dabi iná ajonirun li ori òke na li oju awọn ọmọ Israeli.

17 And the sight of the glory of the LORD was like devouring fire on the top of the mount in the eyes of the children of Israel.

18 Mose si lọ sãrin awọsanma na, o sì gùn ori òke na: Mose si wà lori òke li ogoji ọsán ati ogoji oru.

18 And Moses went into the midst of the cloud, and gat him up into the mount: and Moses was in the mount forty days and forty nights.