Skip to content

Yoruba Bible

Orin Dafidi 8

Ògo OLUWA ati ipò eniyan

1 OLUWA, Oluwa wa, orukọ rẹ ti ni iyìn to ni gbogbo aiye! iwọ ti o gbé ogo rẹ kà ori awọn ọrun.

2 Lati ẹnu awọn ọmọ-ọwọ ati ọmọ-ọmu ni iwọ ti ṣe ilana agbara, nitori awọn ọta rẹ, nitori ki iwọ ki o le mu ọta olugbẹsan nì dakẹjẹ.

3 Nigbati mo rò ọrun rẹ, iṣẹ ika rẹ, oṣupa ati irawọ, ti iwọ ti ṣe ilana silẹ.

4 Kili enia, ti iwọ fi nṣe iranti rẹ̀? ati ọmọ enia, ti iwọ fi mbẹ̀ ẹ wò.

5 Iwọ sa da a li onirẹlẹ diẹ jù awon angeli lọ, iwọ si ti fi ogo ati ọlá de e li ade.

6 Iwọ mu u jọba iṣẹ ọwọ rẹ; iwọ si ti fi ohun gbogbo sabẹ ẹsẹ rẹ̀;

7 Awọn agutan ati awọn malu pẹlu, ati awọn ẹranko igbẹ;

8 Awọn ẹiyẹ oju ọrun, ati awọn ẹja okun, ti o nkọja lọ nipa ọ̀na okun.

9 Oluwa, Oluwa wa, orukọ rẹ ti ni iyìn to ni gbogbo aiye!

Open Bible reader