Skip to content

Yoruba Bible

Orin Dafidi 54

Adura Ààbò

Orin Dafidi, nigbati awọn ara Sifi wá, ti nwọn si sọ fun Saulu pe, Dafidi fi ara rẹ̀ pamọ lọdọ wa.

1 ỌLỌRUN gbà mi nipa orukọ rẹ, si ṣe idajọ mi nipa agbara rẹ.

2 Gbọ́ adura mi, Ọlọrun; fi eti si ọ̀rọ ẹnu mi.

3 Nitoriti awọn alejò dide si mi, awọn aninilara si nwá ọkàn mi: nwọn kò kà Ọlọrun si li oju wọn.

4 Kiyesi i, Ọlọrun li oluranlọwọ mi: Oluwa wà pẹlu awọn ti o gbé ọkàn mi duro.

5 Yio si fi ibi san a fun awọn ọta mi: ke wọn kuro ninu otitọ rẹ.

6 Emi o rubọ atinuwa si ọ: Oluwa, emi o yìn orukọ rẹ; nitoriti o dara.

7 Nitori o ti yọ mi kuro ninu iṣẹ́ gbogbo: oju mi si ri ifẹ rẹ̀ lara awọn ọta mi.

Open Bible reader