Skip to content

Yoruba Bible

Orin Dafidi 121

OLUWA Aláàbò Wa

1 EMI o gbé oju mi si ori oke wọnnì, nibo ni iranlọwọ mi yio ti nwa?

2 Iranlọwọ mi yio ti ọwọ Oluwa wá, ti o da ọrun on aiye.

3 On kì yio jẹ́ ki ẹsẹ rẹ ki o yẹ̀; ẹniti npa ọ mọ́ kì yio tõgbe.

4 Kiyesi i, ẹniti npa Israeli mọ́, kì itõgbe, bẹ̃ni kì isùn.

5 Oluwa li olupamọ́ rẹ: Oluwa li ojiji rẹ li ọwọ ọ̀tún rẹ.

6 Orùn kì yio pa ọ nigba ọsan, tabi oṣupa nigba oru.

7 Oluwa yio pa ọ mọ́ kuro ninu ibi gbogbo: yio pa ọkàn rẹ mọ́.

8 Oluwa yio pa alọ ati àbọ rẹ mọ́ lati igba yi lọ, ati titi lailai.

Open Bible reader