Skip to content

Yoruba Bible

Orin Dafidi 110

OLUWA ati Àyànfẹ́ Ọba Rẹ̀

1 OLUWA wi fun Oluwa mi pe, Iwọ joko li ọwọ ọ̀tún mi, titi emi o fi sọ awọn ọta rẹ di apoti-itisẹ rẹ.

2 Oluwa yio nà ọpá agbara rẹ lati Sioni wá: iwọ jọba larin awọn ọta rẹ.

3 Awọn enia rẹ yio jẹ ọrẹ atinuwá li ọjọ ijade-ogun rẹ, ninu ẹwà ìwà-mimọ́: lati inu owurọ wá, iwọ ni ìri ewe rẹ.

4 Oluwa ti bura, kì yio si yi ọkàn pada pe, Iwọ li alufa titi lai nipa ẹsẹ ti Melkisedeki.

5 Oluwa li ọwọ ọtún rẹ ni yio lù awọn ọba jalẹ li ọjọ ibinu rẹ̀.

6 Yio ṣe idajọ lãrin awọn keferi, yio fi okú kún ibi wọnni; yio fọ́ ori lori ilẹ pupọ̀.

7 Yio ma mu ninu odò na li ọ̀na: nitorina ni yio ṣe gbé ori soke.

Open Bible reader