Skip to content

Yoruba Bible

Jobu 26

1 ṢUGBỌN Jobu si dahùn wipe,

2 Bawo ni iwọ nṣe iranlọwọ ẹniti kò ni ipá, bawo ni iwọ nṣe gbà apa ẹniti kò li agbara?

3 Bawo ni iwọ nṣe ìgbimọ ẹniti kò li ọgbọ́n, tabi bawo ni iwọ nsọdi ọ̀ran li ọ̀pọlọpọ bi o ti ri?

4 Tani iwọ mbà sọ̀rọ, ati ẹmi tani o ti ọdọ rẹ wá?

5 Awọn alailagbara ti isa-okú wáriri; labẹ omi pẹlu awọn ti ngbe inu rẹ̀.

6 Ihoho ni ipo-okú niwaju rẹ̀, ibi iparun kò si ni iboju.

7 On ni o nà ìha ariwa ọrun ni ibi ofurufu, o si fi aiye rọ̀ li oju ofo.

8 O di omiyomi pọ̀ ninu awọsanma rẹ̀ ti o nipọn; awọsanma kò si ya nisalẹ wọn.

9 O si fa oju itẹ rẹ̀ sẹhin, o si tẹ awọ sanma rẹ̀ si i lori.

10 O fi ìde yi omi-okun ka, titi de ala imọlẹ ati òkunkun.

11 Ọwọn òpo ọrun wáriri, ẹnu si yà wọn si ibawi rẹ̀.

12 O fi ipa rẹ̀ damu omi-okun, nipa oye rẹ̀ o lu agberaga jalẹjalẹ.

13 Nipa ẹmi rẹ li o ti ṣe ọrun li ọ̀ṣọ, ọwọ rẹ̀ li o ti da ejo-wiwọ́ nì.

14 Kiyesi i, eyi ni opin ọ̀na rẹ̀, ohùn eyiti a gbọ́ ti kere tó! ṣugbọn ãra ipá rẹ̀ tali oye rẹ̀ le iye?

Open Bible reader