Zechariah 9 - Listen Online
Read Zechariah 9
1 Ọ̀RỌ-ÌMỌ ọ̀rọ Oluwa ni ilẹ Hadraki, Damasku ni yio si jẹ ibi isimi rẹ̀: nitori oju Oluwa mbẹ lara enia, ati lara gbogbo ẹ̀ya Israeli.
1 The burden of the word of the LORD in the land of Hadrach, and Damascus shall be the rest thereof: when the eyes of man, as of all the tribes of Israel, shall be toward the LORD.
2 Ati Hamati pẹlu yio ṣe ãla rẹ̀: Tire ati Sidoni bi o tilẹ ṣe ọlọgbọ́n gidigidi.
2 And Hamath also shall border thereby; Tyrus, and Zidon, though it be very wise.
3 Tire si mọ odi lile fun ara rẹ̀, o si ko fàdakà jọ bi ekuru, ati wurà daradara bi ẹrẹ̀ ita.
3 And Tyrus did build herself a strong hold, and heaped up silver as the dust, and fine gold as the mire of the streets.
4 Kiye si i, Oluwa yio tá a nù, yio si kọlu ipá rẹ̀ ninu okun; a o si fi iná jẹ ẹ run.
4 Behold, the Lord will cast her out, and he will smite her power in the sea; and she shall be devoured with fire.
5 Aṣkeloni yio ri i, yio si bẹ̀ru; Gasa pẹlu yio ri i, yio si kãnu gidigidi, ati Ekroni: nitori oju o tì ireti rẹ̀: ọba yio si ṣegbe kuro ni Gasa, a kì o si gbe Aṣkeloni.
5 Ashkelon shall see it, and fear; Gaza also shall see it, and be very sorrowful, and Ekron; for her expectation shall be ashamed; and the king shall perish from Gaza, and Ashkelon shall not be inhabited.
6 Ọmọ alè yio si gbe inu Aṣdodi, emi o si ke irira awọn Filistini kuro.
6 And a bastard shall dwell in Ashdod, and I will cut off the pride of the Philistines.
7 Emi o si mu ẹ̀jẹ rẹ̀ kuro li ẹnu rẹ̀, ati ohun irira rẹ̀ wọnni kuro lãrin ehín rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o kù, ani on na yio jẹ ti Ọlọrun wa, yio si jẹ bi bãlẹ kan ni Juda, ati Ekroni bi Jebusi.
7 And I will take away his blood out of his mouth, and his abominations from between his teeth: but he that remaineth, even he, shall be for our God, and he shall be as a governor in Judah, and Ekron as a Jebusite.
8 Emi o si dó yi ilẹ mi ka nitori ogun, nitori ẹniti nkọja lọ, ati nitori ẹniti npada bọ̀: kò si aninilara ti yio là wọn já mọ: nitori nisisiyi ni mo fi oju mi ri.
8 And I will encamp about mine house because of the army, because of him that passeth by, and because of him that returneth: and no oppressor shall pass through them any more: for now have I seen with mine eyes.
9 Yọ̀ gidigidi, iwọ ọmọbinrin Sioni; ho, Iwọ ọmọbinrin Jerusalemu: kiye si i, Ọba rẹ mbọ̀wá sọdọ rẹ: ododo li on, o si ni igbalà; o ni irẹ̀lẹ, o si ngùn kẹtẹkẹtẹ, ani ọmọ kẹtẹkẹtẹ.
9 Rejoice greatly, O daughter of Zion; shout, O daughter of Jerusalem: behold, thy King cometh unto thee: he is just, and having salvation; lowly, and riding upon an ass, and upon a colt the foal of an ass.
10 Emi o si ke kẹkẹ́ kuro ni Efraimu, ati ẹṣin kuro ni Jerusalemu, a o si ké ọrun ogun kuro: yio si sọ̀rọ alafia si awọn keferi: ijọba rẹ̀ yio si jẹ lati okun de okun, ati lati odo titi de opin aiye.
10 And I will cut off the chariot from Ephraim, and the horse from Jerusalem, and the battle bow shall be cut off: and he shall speak peace unto the heathen: and his dominion shall be from sea even to sea, and from river even to the ends of the earth.
11 Ni tirẹ pẹlu, emi o fi ẹjẹ majẹmu rẹ rán awọn igbèkun rẹ jade kuro ninu ihò ti kò li omi.
11 As for thee also, by the blood of thy covenant I have sent forth thy prisoners out of the pit wherein is no water.
12 Ẹ pada si odi agbara, ẹnyin onde ireti: ani loni yi emi sọ pe, emi o san a fun ọ ni igbàmejì.
12 Turn you to the strong hold, ye prisoners of hope: even to day do I declare that I will render double unto thee;
13 Nitori mo fa Juda le bi ọrun mi, mo si fi Efraimu kún u, mo si gbe awọn ọmọ rẹ ọkunrin dide, iwọ Sioni, si awọn ọmọ rẹ ọkunrin, iwọ ilẹ Griki, mo ṣe ọ bi idà alagbara.
13 When I have bent Judah for me, filled the bow with Ephraim, and raised up thy sons, O Zion, against thy sons, O Greece, and made thee as the sword of a mighty man.
14 Oluwa yio si fi ara rẹ̀ hàn lori wọn, ọfà rẹ̀ yio si jade lọ bi mànamána: Oluwa Ọlọrun yio si fun ipè, yio si lọ ti on ti ãjà gusù.
14 And the LORD shall be seen over them, and his arrow shall go forth as the lightning: and the LORD GOD shall blow the trumpet, and shall go with whirlwinds of the south.
15 Oluwa awọn ọmọ-ogun yio dãbo bò wọn; nwọn o si jẹ ni run, nwọn o si tẹ̀ okuta kànna-kànna mọlẹ; nwọn o si mu, nwọn o si pariwo bi nipa ọti-waini; nwọn o si kún bi ọpọ́n, ati bi awọn igun pẹpẹ.
15 The LORD of hosts shall defend them; and they shall devour, and subdue with sling stones; and they shall drink, and make a noise as through wine; and they shall be filled like bowls, and as the corners of the altar.
16 Oluwa Ọlọrun wọn yio si gbà wọn là li ọjọ na bi agbo enia rẹ̀: nitori nwọn o dabi awọn okuta ade, ti a gbe soke bi àmi lori ilẹ rẹ̀.
16 And the LORD their God shall save them in that day as the flock of his people: for they shall be as the stones of a crown, lifted up as an ensign upon his land.
17 Nitori ore rẹ̀ ti tobi to, ẹwà rẹ̀ si ti pọ̀ to! ọkà yio mu ọdọmọkunrin darayá, ati ọti-waini titún yio mu awọn ọdọmọbinrin ṣe bẹ̃ pẹlu.
17 For how great is his goodness, and how great is his beauty! corn shall make the young men cheerful, and new wine the maids.