Skip to content

Psalms 98 - Listen Online

Loading Bible...
Read Psalms 98

1 Ẹ kọrin titun si Oluwa; nitoriti o ti ṣe ohun iyanu: ọwọ ọtún rẹ̀, ati apa rẹ̀ mimọ́ li o ti mu igbala wa fun ara rẹ̀.

1 O sing unto the LORD a new song; for he hath done marvellous things: his right hand, and his holy arm, hath gotten him the victory.

2 Oluwa ti sọ igbala rẹ̀ di mimọ̀: ododo rẹ̀ li o ti fi hàn nigbangba li ojú awọn keferi.

2 The LORD hath made known his salvation: his righteousness hath he openly shewed in the sight of the heathen.

3 O ti ranti ãnu rẹ̀ ati otitọ rẹ̀ si awọn ara ile Israeli: gbogbo opin aiye ti ri igbala Ọlọrun wa.

3 He hath remembered his mercy and his truth toward the house of Israel: all the ends of the earth have seen the salvation of our God.

4 Ẹ ho iho ayọ̀ si Oluwa, gbogbo aiye: ẹ ho yè, ẹ yọ̀, ki ẹ si ma kọrin iyìn.

4 Make a joyful noise unto the LORD, all the earth: make a loud noise, and rejoice, and sing praise.

5 Ẹ ma fi duru kọrin si Oluwa, ati duru pẹlu ohùn orin-mimọ́.

5 Sing unto the LORD with the harp; with the harp, and the voice of a psalm.

6 Pẹlu ipè ati ohùn fere, ẹ ho iho ayọ̀ niwaju Oluwa, Ọba.

6 With trumpets and sound of cornet make a joyful noise before the LORD, the King.

7 Jẹ ki okun ki o ma ho pẹlu ikún rẹ̀; aiye, ati awọn ti mbẹ ninu rẹ̀.

7 Let the sea roar, and the fulness thereof; the world, and they that dwell therein.

8 Jẹ ki odò ki o ma ṣapẹ, ki awọn òke ki o ma ṣe ajọyọ̀.

8 Let the floods clap their hands: let the hills be joyful together

9 Niwaju Oluwa; nitori ti mbọwa iṣe idajọ aiye: pẹlu ododo ni yio fi ṣe idajọ aiye, ati awọn orilẹ-ède li aiṣègbe.

9 Before the LORD; for he cometh to judge the earth: with righteousness shall he judge the world, and the people with equity.