Skip to content

Psalms 149 - Listen Online

Loading Bible...
Read Psalms 149

1 Ẹ fi iyìn fun Oluwa. Ẹ kọ orin titun si Oluwa, ati iyìn rẹ̀ ninu ijọ awọn enia-mimọ́.

1 Praise ye the LORD. Sing unto the LORD a new song, and his praise in the congregation of saints.

2 Jẹ ki Israeli ki o yọ̀ si ẹniti o dá a; jẹ ki awọn ọmọ Sioni ki o kún fun ayọ̀ si Ọba wọn.

2 Let Israel rejoice in him that made him: let the children of Zion be joyful in their King.

3 Jẹ ki nwọn ki o yìn orukọ rẹ̀ ninu ijó: jẹ ki nwọn ki o fi ìlu ati dùru kọrin iyìn si i.

3 Let them praise his name in the dance: let them sing praises unto him with the timbrel and harp.

4 Nitori ti Oluwa ṣe inudidùn si awọn enia rẹ̀; yio fi igbala ṣe awọn onirẹlẹ li ẹwà.

4 For the LORD taketh pleasure in his people: he will beautify the meek with salvation.

5 Jẹ ki awọn enia mimọ́ ki o kún fun ayọ̀ ninu ogo; ki nwọn ki o mã kọrin kikan lori ẹni wọn.

5 Let the saints be joyful in glory: let them sing aloud upon their beds.

6 Ki iyìn Ọlọrun ki o wà li ẹnu wọn, ati idà oloju meji li ọwọ wọn;

6 Let the high praises of God be in their mouth, and a twoedged sword in their hand;

7 Lati san ẹsan lara awọn keferi, ati ijiya lara awọn enia.

7 To execute vengeance upon the heathen, and punishments upon the people;

8 Lati fi ẹ̀wọn dè awọn ọba wọn, ati lati fi ṣẹkẹṣẹkẹ irin dè awọn ọlọ̀tọ wọn;

8 To bind their kings with chains, and their nobles with fetters of iron;

9 Lati ṣe idajọ wọn, ti a ti kọwe rẹ̀, ọlá yi ni gbogbo enia mimọ́ rẹ̀ ni. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.

9 To execute upon them the judgment written: this honour have all his saints. Praise ye the LORD.