Judges 13 - Listen Online
Read Judges 13
1 AWỌN ọmọ Israeli si tun ṣe eyiti iṣe buburu li oju OLUWA; OLUWA si fi wọn lé awọn Filistini li ọwọ́ li ogoji ọdún.
1 And the children of Israel did evil again in the sight of the LORD; and the LORD delivered them into the hand of the Philistines forty years.
2 Ọkunrin kan ara Sora si wà, ti iṣe idile Dani, orukọ rẹ̀ si ni Manoa, obinrin rẹ̀ si yàgan, kò si bimọ.
2 And there was a certain man of Zorah, of the family of the Danites, whose name was Manoah; and his wife was barren, and bare not.
3 Angeli OLUWA si farahàn obinrin na, o si wi fun u pe, Sá kiyesi i, iwọ yàgan, iwọ kò si bimọ: ṣugbọn iwọ o lóyun, iwọ o si bi ọmọkunrin kan.
3 And the angel of the LORD appeared unto the woman, and said unto her, Behold now, thou art barren, and bearest not: but thou shalt conceive, and bear a son.
4 Njẹ nitorina kiyesara, emi bẹ̀ ọ, máṣe mu ọti-waini tabi ọti lile, má si ṣe jẹ ohun aimọ́ kan:
4 Now therefore beware, I pray thee, and drink not wine nor strong drink, and eat not any unclean thing:
5 Nitori kiyesi i, iwọ o lóyun, iwọ o si bi ọmọkunrin kan; ki abẹ ki o má ṣe kàn a lori: nitori Nasiri Ọlọrun li ọmọ na o jẹ́ lati inu wá: on o bẹ̀rẹsi gbà Israeli li ọwọ́ awọn Filistini.
5 For, lo, thou shalt conceive, and bear a son; and no rasor shall come on his head: for the child shall be a Nazarite unto God from the womb: and he shall begin to deliver Israel out of the hand of the Philistines.
6 Nigbana obinrin na wá, o si rò fun ọkọ rẹ̀, wipe, Enia Ọlọrun kan wá sọdọ mi, irí rẹ̀ si dabi irí angeli Ọlọrun, o ní ẹ̀ru gidigidi; ṣugbọn emi kò bilère ibiti o ti wá, bẹ̃li on kò si sọ orukọ rẹ̀ fun mi:
6 Then the woman came and told her husband, saying, A man of God came unto me, and his countenance was like the countenance of an angel of God, very terrible: but I asked him not whence he was, neither told he me his name:
7 Ṣugbọn on sọ fun mi pe, Kiyesi i, iwọ o lóyun, iwọ o si bi ọmọkunrin kan; nitorina má ṣe mu ọti-waini tabi ọti lile, bẹ̃ni ki o má ṣe jẹ ohun aimọ́ kan: nitori Nasiri Ọlọrun li ọmọ na o jẹ́ lati inu wá titi di ọjọ́ ikú rẹ̀.
7 But he said unto me, Behold, thou shalt conceive, and bear a son; and now drink no wine nor strong drink, neither eat any unclean thing: for the child shall be a Nazarite to God from the womb to the day of his death.
8 Nigbana ni Manoa bẹ̀ OLUWA, o si wipe, OLUWA, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki enia Ọlọrun, ti iwọ rán tun tọ̀ wa wá, ki o le kọ́ wa li ohun ti awa o ṣe si ọmọ na ti a o bi.
8 Then Manoah intreated the LORD, and said, O my Lord, let the man of God which thou didst send come again unto us, and teach us what we shall do unto the child that shall be born.
9 Ọlọrun si gbọ ohùn Manoa; angeli Ọlọrun na si tun tọ̀ obinrin na wá, bi on ti joko ninu oko; ṣugbọn Manoa ọkọ rẹ̀ kò sí nibẹ̀ pẹlu rẹ̀.
9 And God hearkened to the voice of Manoah; and the angel of God came again unto the woman as she sat in the field: but Manoah her husband was not with her.
10 Obinrin na si yara kánkán, o si sure, o si sọ fun ọkọ rẹ̀, o si wi fun u pe, Kiyesi i, ọkunrin ti o tọ̀ mi wá ni ijelo farahàn mi.
10 And the woman made haste, and ran, and shewed her husband, and said unto him, Behold, the man hath appeared unto me, that came unto me the other day.
11 Manoa si dide, o si tẹle aya rẹ̀, o si wá sọdọ ọkunrin na, o si bi i pe, Iwọ li ọkunrin na ti o bá obinrin na sọ̀rọ? On si wipe, Emi ni.
11 And Manoah arose, and went after his wife, and came to the man, and said unto him, Art thou the man that spakest unto the woman? And he said, I am.
12 Manoa si wipe, Njẹ ki ọ̀rọ rẹ ki o ṣẹ: ìwa ọmọ na yio ti jẹ́, iṣẹ rẹ̀ yio ti jẹ́?
12 And Manoah said, Now let thy words come to pass. How shall we order the child, and how shall we do unto him?
13 Angeli OLUWA si wi fun Manoa pe, Ni gbogbo eyiti mo sọ fun obinrin na ni ki o kiyesi.
13 And the angel of the LORD said unto Manoah, Of all that I said unto the woman let her beware.
14 Ki o má ṣe jẹ ohun kan ti o ti inu àjara wá, ki o má ṣe mu ọti-waini tabi ọti lile, bẹ̃ni kò gbọdọ jẹ ohun aimọ́ kan; gbogbo eyiti mo palaṣẹ fun u ni ki o kiyesi.
14 She may not eat of any thing that cometh of the vine, neither let her drink wine or strong drink, nor eat any unclean thing: all that I commanded her let her observe.
15 Manoa si wi fun angeli OLUWA na pe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki awa ki o da ọ duro, titi awa o si fi pèse ọmọ ewurẹ kan fun ọ.
15 And Manoah said unto the angel of the LORD, I pray thee, let us detain thee, until we shall have made ready a kid for thee.
16 Angeli OLUWA na si wi fun Manoa pe, Bi iwọ tilẹ da mi duro, emi ki yio jẹ ninu àkara rẹ: bi iwọ o ba si ru ẹbọ sisun kan, OLUWA ni ki iwọ ki o ru u si. Nitori Manoa kò mọ̀ pe angeli OLUWA ni iṣe.
16 And the angel of the LORD said unto Manoah, Though thou detain me, I will not eat of thy bread: and if thou wilt offer a burnt offering, thou must offer it unto the LORD. For Manoah knew not that he was an angel of the LORD.
17 Manoa si wi fun angeli OLUWA na pe, Orukọ rẹ, nitori nigbati ọ̀rọ rẹ ba ṣẹ ki awa ki o le bọlá fun ọ?
17 And Manoah said unto the angel of the LORD, What is thy name, that when thy sayings come to pass we may do thee honour?
18 Angeli OLUWA na si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi mbère orukọ mi, kiyesi i, Iyanu ni.
18 And the angel of the LORD said unto him, Why askest thou thus after my name, seeing it is secret?
19 Manoa si mú ọmọ ewurẹ kan pẹlu ẹbọ ohunjijẹ, o si ru u lori apata kan si OLUWA: angeli na si ṣe ohun iyanu, Manoa ati obinrin rẹ̀ si nwò o.
19 So Manoah took a kid with a meat offering, and offered it upon a rock unto the LORD: and the angel did wondrously; and Manoah and his wife looked on.
20 O si ṣe ti ọwọ́-iná na nlọ soke ọrun lati ibi-pẹpẹ na wá, angeli OLUWA na si gòke ninu ọwọ́-iná ti o ti ibi-pẹpẹ jade wá. Manoa ati aya rẹ̀ si nwò o; nwọn si dojubolẹ.
20 For it came to pass, when the flame went up toward heaven from off the altar, that the angel of the LORD ascended in the flame of the altar. And Manoah and his wife looked on it, and fell on their faces to the ground.
21 Ṣugbọn angeli OLUWA na kò si tun farahàn fun Manoa tabi aya rẹ̀ mọ́. Nigbana ni Manoa to wa mọ̀ pe, angeli OLUWA ni iṣe.
21 But the angel of the LORD did no more appear to Manoah and to his wife. Then Manoah knew that he was an angel of the LORD.
22 Manoa si wi fun aya rẹ̀ pe, Kikú li awa o kú yi, nitoriti awa ti ri Ọlọrun.
22 And Manoah said unto his wife, We shall surely die, because we have seen God.
23 Aya rẹ̀ si wi fun u pe, Ibaṣepe o wù OLUWA lati pa wa, on kì ba ti gbà ẹbọ sisun ati ẹbọ ohunjijẹ li ọwọ́ wa, bẹ̃li on kì ba ti fi gbogbo nkan wọnyi hàn wa, bẹ̃li on kì ba ti sọ̀rọ irú nkan wọnyi fun wa li akokò yi.
23 But his wife said unto him, If the LORD were pleased to kill us, he would not have received a burnt offering and a meat offering at our hands, neither would he have shewed us all these things, nor would as at this time have told us such things as these.
24 Obinrin na si bi ọmọkunrin kan, o si sọ orukọ rẹ̀ ni Samsoni: ọmọ na si dàgba, OLUWA si bukún u.
24 And the woman bare a son, and called his name Samson: and the child grew, and the LORD blessed him.
25 Ẹmi OLUWA si bẹ̀rẹsi ṣiṣẹ ninu rẹ̀ ni Mahane-dani, li agbedemeji Sora ati Eṣtaolu.
25 And the Spirit of the LORD began to move him at times in the camp of Dan between Zorah and Eshtaol.