Jeremiah 45 - Listen Online
Read Jeremiah 45
1 Ọ̀RỌ ti Jeremiah, woli, sọ fun Baruku, ọmọ Neriah nigbati o ti kọ ọ̀rọ wọnyi sinu iwe tan li ẹnu Jeremiah li ọdun kẹrin Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọba Juda, wipe,
1 The word that Jeremiah the prophet spake unto Baruch the son of Neriah, when he had written these words in a book at the mouth of Jeremiah, in the fourth year of Jehoiakim the son of Josiah king of Judah, saying,
2 Bayi li Oluwa, Ọlọrun Israeli, wi fun ọ, iwọ Baruku;
2 Thus saith the LORD, the God of Israel, unto thee, O Baruch;
3 Iwọ wipe, Egbé ni fun mi nisisiyi! nitori ti Oluwa ti fi ibanujẹ kún ikãnu mi; ãrẹ̀ mu mi ninu ẹ̀dun mi, emi kò si ri isimi.
3 Thou didst say, Woe is me now! for the LORD hath added grief to my sorrow; I fainted in my sighing, and I find no rest.
4 Bayi ni ki iwọ sọ fun u, Oluwa wi bayi; pe, Wò o, eyi ti emi ti kọ́, li emi o wo lulẹ, ati eyi ti emi ti gbìn li emi o fà tu, ani gbogbo ilẹ yi.
4 Thus shalt thou say unto him, The LORD saith thus; Behold, that which I have built will I break down, and that which I have planted I will pluck up, even this whole land.
5 Iwọ ha si mbere ohun nla fun ara rẹ? máṣe bere: nitori, wò o, emi o mu ibi wá sori gbogbo ẹran-ara, li Oluwa wi: ṣugbọn ẹmi rẹ li emi o fi fun ọ bi ikogun ni gbogbo ibiti iwọ ba lọ si.
5 And seekest thou great things for thyself? seek them not: for, behold, I will bring evil upon all flesh, saith the LORD: but thy life will I give unto thee for a prey in all places whither thou goest.