Jeremiah 29 - Listen Online
Read Jeremiah 29
1 WỌNYI si li ọ̀rọ iwe ti Jeremiah woli rán lati Jerusalemu si iyokù ninu awọn àgba ti o wà ni igbèkun, ati si awọn alufa, ati awọn woli, ati si gbogbo enia ti Nebukadnessari kó ni igbekun lọ lati Jerusalemu si Babeli.
1 Now these are the words of the letter that Jeremiah the prophet sent from Jerusalem unto the residue of the elders which were carried away captives, and to the priests, and to the prophets, and to all the people whom Nebuchadnezzar had carried away captive from Jerusalem to Babylon;
2 Lẹhin igbati Jekoniah, ọba, ati ayaba, ati awọn iwẹfa, ati awọn ijoye Juda ati Jerusalemu, ati awọn gbẹna-gbẹna pẹlu awọn alagbẹdẹ ti fi Jerusalemu silẹ lọ.
2 (After that Jeconiah the king, and the queen, and the eunuchs, the princes of Judah and Jerusalem, and the carpenters, and the smiths, were departed from Jerusalem;)
3 Nipa ọwọ Elasa, ọmọ Ṣafani, ati Gemariah, ọmọ Hilkiah, (ẹniti Sedekiah, ọba Juda, rán si Babeli tọ Nebukadnessari, ọba Babeli) wipe,
3 By the hand of Elasah the son of Shaphan, and Gemariah the son of Hilkiah, (whom Zedekiah king of Judah sent unto Babylon to Nebuchadnezzar king of Babylon) saying,
4 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi fun gbogbo awọn ti a kó ni igbekun lọ, ti emi mu ki a kó lọ lati Jerusalemu si Babeli;
4 Thus saith the LORD of hosts, the God of Israel, unto all that are carried away captives, whom I have caused to be carried away from Jerusalem unto Babylon;
5 Ẹ kọ́ ile ki ẹ si ma gbe inu wọn; ẹ gbìn ọgba, ki ẹ si mã jẹ eso wọn;
5 Build ye houses, and dwell in them; and plant gardens, and eat the fruit of them;
6 Ẹ fẹ́ aya, ki ẹ si bi ọmọkunrin ati ọmọbinrin; ki ẹ si fẹ́ aya fun awọn ọmọ nyin, ẹ si fi awọn ọmọbinrin nyin fun ọkọ, ki nwọn ki o le mã bi ọmọkunrin ati ọmọbinrin; ki ẹ le mã pọ si i nibẹ, ki ẹ má si dínkù.
6 Take ye wives, and beget sons and daughters; and take wives for your sons, and give your daughters to husbands, that they may bear sons and daughters; that ye may be increased there, and not diminished.
7 Ki ẹ si mã wá alafia ilu na, nibiti emi ti mu ki a kó nyin lọ ni igbekun, ẹ si mã gbadura si Oluwa fun u: nitori ninu alafia rẹ̀ li ẹnyin o ni alafia.
7 And seek the peace of the city whither I have caused you to be carried away captives, and pray unto the LORD for it: for in the peace thereof shall ye have peace.
8 Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi pe, Ẹ máṣe jẹ ki awọn woli nyin ti o wà lãrin nyin ati awọn alafọṣẹ nyin tàn nyin jẹ, ki ẹ má si feti si alá nyin ti ẹnyin lá.
8 For thus saith the LORD of hosts, the God of Israel; Let not your prophets and your diviners, that be in the midst of you, deceive you, neither hearken to your dreams which ye cause to be dreamed.
9 Nitori nwọn sọ asọtẹlẹ eke fun nyin li orukọ mi: emi kò rán wọn, li Oluwa wi.
9 For they prophesy falsely unto you in my name: I have not sent them, saith the LORD.
10 Nitori bayi li Oluwa wi pe, Lẹhin ti ãdọrin ọdun ba pari ni Babeli, li emi o bẹ̀ nyin wò, emi o si mu ọ̀rọ rere mi ṣẹ si nyin, ni mimu nyin pada si ibi yi.
10 For thus saith the LORD, That after seventy years be accomplished at Babylon I will visit you, and perform my good word toward you, in causing you to return to this place.
11 Nitori emi mọ̀ ìro ti mo rò si nyin, li Oluwa wi, ani ìro alafia, kì si iṣe fun ibi, lati fun nyin ni ìgba ikẹhin ati ireti.
11 For I know the thoughts that I think toward you, saith the LORD, thoughts of peace, and not of evil, to give you an expected end.
12 Ẹnyin o si kepe mi, ẹ o si lọ, ẹ o si gbadura si mi, emi o si tẹti si nyin.
12 Then shall ye call upon me, and ye shall go and pray unto me, and I will hearken unto you.
13 Ẹnyin o si ṣafẹri mi, ẹ o si ri mi, nitori ẹ o fi gbogbo ọkàn nyin wá mi.
13 And ye shall seek me, and find me, when ye shall search for me with all your heart.
14 Emi o di ríri fun nyin, li Oluwa wi: emi o si yi igbekun nyin pada kuro, emi o si kó nyin jọ lati gbogbo orilẹ-ède ati lati ibi gbogbo wá, nibiti emi ti lé nyin lọ, li Oluwa wi; emi o si tun mu nyin wá si ibi ti mo ti mu ki a kó nyin ni igbekun lọ.
14 And I will be found of you, saith the LORD: and I will turn away your captivity, and I will gather you from all the nations, and from all the places whither I have driven you, saith the LORD; and I will bring you again into the place whence I caused you to be carried away captive.
15 Nitoriti ẹnyin ti wipe, Oluwa ti gbe awọn woli kalẹ fun wa ni Babeli:
15 Because ye have said, The LORD hath raised us up prophets in Babylon;
16 Pe, Bayi li Oluwa wi niti ọba ti o joko lori itẹ́ Dafidi, ati niti gbogbo enia, ti ngbe ilu yi, ani niti awọn arakunrin nyin ti kò jade lọ pẹlu nyin sinu igbekun.
16 Know that thus saith the LORD of the king that sitteth upon the throne of David, and of all the people that dwelleth in this city, and of your brethren that are not gone forth with you into captivity;
17 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Wò o, emi o rán idà sarin wọn, ìyan, ati àjakalẹ-àrun, emi o ṣe wọn bi eso-ọ̀pọtọ buburu, ti a kò le jẹ, nitori nwọn buru.
17 Thus saith the LORD of hosts; Behold, I will send upon them the sword, the famine, and the pestilence, and will make them like vile figs, that cannot be eaten, they are so evil.
18 Emi o si fi idà, ìyan, ati àjakalẹ-arun lepa wọn; emi o si fi wọn fun iwọsi ni gbogbo ijọba aiye, fun egún, ati iyanu, ati ẹsin, ati ẹ̀gan, lãrin gbogbo orilẹ-ède, nibiti emi o le wọn si.
18 And I will persecute them with the sword, with the famine, and with the pestilence, and will deliver them to be removed to all the kingdoms of the earth, to be a curse, and an astonishment, and an hissing, and a reproach, among all the nations whither I have driven them:
19 Nitoriti nwọn kò gbọ́ ọ̀rọ mi, li Oluwa wi, ti emi rán si wọn nipa awọn ọmọ-ọdọ mi, awọn woli, emi dide ni kutukutu mo si rán wọn; ṣugbọn ẹnyin kò fẹ igbọ́, li Oluwa wi.
19 Because they have not hearkened to my words, saith the LORD, which I sent unto them by my servants the prophets, rising up early and sending them; but ye would not hear, saith the LORD.
20 Njẹ ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, gbogbo ẹnyin igbekun ti emi ti ran jade lati Jerusalemu si Babeli.
20 Hear ye therefore the word of the LORD, all ye of the captivity, whom I have sent from Jerusalem to Babylon:
21 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi, niti Ahabu ọmọ Kolaiah, ati niti Sedekiah ọmọ Maaseiah, ti nsọtẹlẹ eke fun nyin li orukọ mi; wò o, emi fi wọn le ọwọ Nebukadnessari, ọba Babeli; on o si pa wọn li oju nyin;
21 Thus saith the LORD of hosts, the God of Israel, of Ahab the son of Kolaiah, and of Zedekiah the son of Maaseiah, which prophesy a lie unto you in my name; Behold, I will deliver them into the hand of Nebuchadrezzar king of Babylon; and he shall slay them before your eyes;
22 Ati lati ọdọ wọn li a o da ọ̀rọ-egún kan silẹ li ẹnu gbogbo igbekun Juda ti o wà ni Babeli, wipe; Ki Oluwa ki o ṣe ọ bi Sedekiah, ati bi Ahabu, awọn ẹniti ọba Babeli sun ninu iná.
22 And of them shall be taken up a curse by all the captivity of Judah which are in Babylon, saying, The LORD make thee like Zedekiah and like Ahab, whom the king of Babylon roasted in the fire;
23 Nitori nwọn ti hùwa wère ni Israeli, nwọn si ba aya aladugbo wọn ṣe panṣaga, nwọn si ti sọ̀rọ eke li orukọ mi, ti emi kò ti pa li aṣẹ fun wọn: emi tilẹ mọ̀, emi si li ẹlẹri, li Oluwa wi.
23 Because they have committed villany in Israel, and have committed adultery with their neighbours' wives, and have spoken lying words in my name, which I have not commanded them; even I know, and am a witness, saith the LORD.
24 Ati fun Ṣemaiah ara Nehalami, ni iwọ o sọ wipe.
24 Thus shalt thou also speak to Shemaiah the Nehelamite, saying,
25 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, Nitoripe iwọ ti rán iwe li orukọ rẹ si gbogbo enia ti o wà ni Jerusalemu ati si Sefaniah, ọmọ Maaseiah, alufa, ati si gbogbo awọn alufa, wipe,
25 Thus speaketh the LORD of hosts, the God of Israel, saying, Because thou hast sent letters in thy name unto all the people that are at Jerusalem, and to Zephaniah the son of Maaseiah the priest, and to all the priests, saying,
26 Oluwa ti fi ọ jẹ oyè alufa ni ipo Jehoiada, alufa, ki ẹnyin ki o lè jẹ olutọju ni ile Oluwa, nitori olukuluku aṣiwere enia, ati ẹnikẹni ti o sọ asọtẹlẹ ki iwọ ki o le fi wọn sinu tubu ati sinu àba.
26 The LORD hath made thee priest in the stead of Jehoiada the priest, that ye should be officers in the house of the LORD, for every man that is mad, and maketh himself a prophet, that thou shouldest put him in prison, and in the stocks.
27 Njẹ nisisiyi, ẽṣe ti iwọ kò ba Jeremiah ti Anatoti wi, ẹniti o nsọ asọtẹlẹ fun nyin!
27 Now therefore why hast thou not reproved Jeremiah of Anathoth, which maketh himself a prophet to you?
28 Nitorina li o ṣe ranṣẹ si wa ni Babeli, wipe, Akoko yio pẹ: ẹ kọ́ ile, ki ẹ si ma gbe inu wọn, ẹ si gbìn ọgbà, ki ẹ ma jẹ eso wọn.
28 For therefore he sent unto us in Babylon, saying, This captivity is long: build ye houses, and dwell in them; and plant gardens, and eat the fruit of them.
29 Sefaniah, alufa, si ka iwe yi li eti Jeremiah woli.
29 And Zephaniah the priest read this letter in the ears of Jeremiah the prophet.
30 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ Jeremiah wá wipe,
30 Then came the word of the LORD unto Jeremiah, saying,
31 Ranṣẹ si gbogbo awọn igbekun, wipe, Bayi li Oluwa wi niti Ṣemaiah, ara Nehalami, nitoripe Ṣemaiah ti sọtẹlẹ fun nyin, ṣugbọn emi kò ran a, ti on si mu nyin gbẹkẹle eke:
31 Send to all them of the captivity, saying, Thus saith the LORD concerning Shemaiah the Nehelamite; Because that Shemaiah hath prophesied unto you, and I sent him not, and he caused you to trust in a lie:
32 Nitorina, bayi li Oluwa wi: Wò o, emi o bẹ Ṣemaiah, ara Nehalami, wò, ati iru-ọmọ rẹ̀; on kì yio ni ọkunrin kan lati ma gbe ãrin enia yi; bẹ̃ni kì yio ri rere na ti emi o ṣe fun awọn enia mi, li Oluwa wi; nitoripe o ti ṣọ̀tẹ si Oluwa.
32 Therefore thus saith the LORD; Behold, I will punish Shemaiah the Nehelamite, and his seed: he shall not have a man to dwell among this people; neither shall he behold the good that I will do for my people, saith the LORD; because he hath taught rebellion against the LORD.