Skip to content

Isaiah 4 - Listen Online

Loading Bible...
Read Isaiah 4

1 ATI li ọjọ na obinrin meje yio dimọ́ ọkunrin kan, wipe, Awa o jẹ onjẹ ara wa, awa o si wọ̀ aṣọ ara wa: kìkì pe, jẹ ki a fi orukọ rẹ pè wa, lati mu ẹgàn wa kuro.

1 And in that day seven women shall take hold of one man, saying, We will eat our own bread, and wear our own apparel: only let us be called by thy name, to take away our reproach.

2 Li ọjọ na ni ẹka Oluwa yio ni ẹwà on ogo, eso ilẹ yio si ni ọla, yio si dara fun awọn ti o sálà ni Israeli.

2 In that day shall the branch of the LORD be beautiful and glorious, and the fruit of the earth shall be excellent and comely for them that are escaped of Israel.

3 Yio si ṣe, pe, ẹniti a fi silẹ ni Sioni, ati ẹniti o kù ni Jerusalemu, li a o pè ni mimọ́, ani orukọ olukuluku ẹniti a kọ pẹlu awọn alãye ni Jerusalemu.

3 And it shall come to pass, that he that is left in Zion, and he that remaineth in Jerusalem, shall be called holy, even every one that is written among the living in Jerusalem:

4 Nigbati Oluwa ba ti wẹ̀ ẹgbin awọn ọmọbinrin Sioni nù, ti o si ti fọ ẹ̀jẹ Jerusalemu kuro li ãrin rẹ̀ nipa ẹmi idajọ, ati nipa ẹmi ijoná.

4 When the Lord shall have washed away the filth of the daughters of Zion, and shall have purged the blood of Jerusalem from the midst thereof by the spirit of judgment, and by the spirit of burning.

5 Lori olukuluku ibùgbe oke Sioni, ati lori awọn apejọ rẹ̀, li Oluwa yio si da awọsanma, ati ẹ̃fin li ọsan, ati didan ọwọ́ iná li oru: nitori àbò yio wá lori gbogbo ogo.

5 And the LORD will create upon every dwelling place of mount Zion, and upon her assemblies, a cloud and smoke by day, and the shining of a flaming fire by night: for upon all the glory shall be a defence.

6 Agọ kan yio si wà fun ojiji li ọsan kuro ninu oru, ati fun ibi isasi, ati fun ãbo kuro ninu ijì, ati kuro ninu ojò.

6 And there shall be a tabernacle for a shadow in the daytime from the heat, and for a place of refuge, and for a covert from storm and from rain.