Skip to content

Genesis 19 - Listen Online

Loading Bible...
Read Genesis 19

1 AWỌN Angeli meji si wá si Sodomu li aṣalẹ; Loti si joko li ẹnu-bode Sodomu: bi Loti si ti ri wọn, o dide lati pade wọn: o si dojubolẹ;

1 And there came two angels to Sodom at even; and Lot sat in the gate of Sodom: and Lot seeing them rose up to meet them; and he bowed himself with his face toward the ground;

2 O si wipe, Kiyesi i nisisiyi, ẹnyin oluwa mi, emi bẹ̀ nyin, ẹ yà si ile ọmọ-ọdọ nyin, ki ẹ si wọ̀, ki ẹ si wẹ̀ ẹsẹ̀ nyin, ẹnyin o si dide ni kùtukutu, ki ẹ si ma ba ti nyin lọ. Nwọn si wipe, Ndao; ṣugbọn awa o joko ni igboro li oru oni.

2 And he said, Behold now, my lords, turn in, I pray you, into your servant's house, and tarry all night, and wash your feet, and ye shall rise up early, and go on your ways. And they said, Nay; but we will abide in the street all night.

3 O si rọ̀ wọn gidigidi; nwọn si yà tọ̀ ọ, nwọn si wọ̀ inu ile rẹ̀; o si sè àse fun wọn, o si dín àkara alaiwu fun wọn, nwọn si jẹ.

3 And he pressed upon them greatly; and they turned in unto him, and entered into his house; and he made them a feast, and did bake unleavened bread, and they did eat.

4 Ṣugbọn ki nwọn ki o to dubulẹ, awọn ọkunrin ara ilu na, awọn ọkunrin Sodomu, nwọn yi ile na ká, ati àgba ati ewe, gbogbo enia lati ori igun mẹrẹrin wá.

4 But before they lay down, the men of the city, even the men of Sodom, compassed the house round, both old and young, all the people from every quarter:

5 Nwọn si pè Loti, nwọn si bi i pe, Nibo li awọn ọkunrin ti o tọ̀ ọ wá li alẹ yi wà? mu wọn jade fun wa wá, ki awa ki o le mọ̀ wọn.

5 And they called unto Lot, and said unto him, Where are the men which came in to thee this night? bring them out unto us, that we may know them.

6 Loti si jade tọ̀ wọn lọ li ẹnu-ọ̀na, o si sé ilẹkun lẹhin rẹ̀.

6 And Lot went out at the door unto them, and shut the door after him,

7 O si wipe, Arakunrin, emi bẹ̀ nyin, ẹ máṣe hùwa buburu bẹ̃.

7 And said, I pray you, brethren, do not so wickedly.

8 Kiyesi i nisisiyi, emi li ọmọbinrin meji ti kò ti imọ̀ ọkunrin: emi bẹ̀ nyin, ẹ jẹ ki nmu wọn jade tọ̀ nyin wá, ki ẹnyin ki o si fi wọn ṣe bi o ti tọ́ loju nyin: ṣugbọn awọn ọkunrin wọnyi ṣa ni ki ẹ má ṣe ni nkan; nitorina ni nwọn sa ṣe wá si abẹ orule mi.

8 Behold now, I have two daughters which have not known man; let me, I pray you, bring them out unto you, and do ye to them as is good in your eyes: only unto these men do nothing; for therefore came they under the shadow of my roof.

9 Nwọn si wipe, Bì sẹhin. Nwọn si tun wipe, Eyiyi wá iṣe atipo, on si fẹ iṣe onidajọ: njẹ iwọ li a o tilẹ ṣe ni buburu jù wọn lọ. Nwọn si rọlù ọkunrin na, ani Loti, nwọn si sunmọ ọ lati fọ́ ilẹkun.

9 And they said, Stand back. And they said again, This one fellow came in to sojourn, and he will needs be a judge: now will we deal worse with thee, than with them. And they pressed sore upon the man, even Lot, and came near to break the door.

10 Ṣugbọn awọn ọkunrin na nà ọwọ́ wọn, nwọn si fà Loti mọ́ ọdọ sinu ile, nwọn si tì ilẹkun.

10 But the men put forth their hand, and pulled Lot into the house to them, and shut to the door.

11 Nwọn si bù ifọju lù awọn ọkunrin ti o wà li ẹnu-ọ̀na ile na, ati ewe ati àgba: bẹ̃ni nwọn dá ara wọn li agara lati ri ẹnu-ọ̀na.

11 And they smote the men that were at the door of the house with blindness, both small and great: so that they wearied themselves to find the door.

12 Awọn ọkunrin na si wi fun Loti pe, Iwọ ni ẹnikan nihin pẹlu? ana rẹ ọkunrin, ati awọn ọmọ rẹ ọkunrin, ati awọn ọmọ rẹ obinrin, ati ohunkohun ti iwọ ni ni ilu, mu wọn jade kuro nihinyi:

12 And the men said unto Lot, Hast thou here any besides? son in law, and thy sons, and thy daughters, and whatsoever thou hast in the city, bring them out of this place:

13 Nitori awa o run ibi yi, nitori ti igbe wọn ndi pupọ̀ niwaju OLUWA; OLUWA si rán wa lati run u.

13 For we will destroy this place, because the cry of them is waxen great before the face of the LORD; and the LORD hath sent us to destroy it.

14 Loti si jade, o si sọ fun awọn ana rẹ̀ ọkunrin, ti nwọn gbe awọn ọmọbinrin rẹ̀ ni iyawo, o wipe, Ẹ dide, ẹ jade kuro nihinyi; nitoriti OLUWA yio run ilu yi. Ṣugbọn o dabi ẹlẹtàn loju awọn ana rẹ̀.

14 And Lot went out, and spake unto his sons in law, which married his daughters, and said, Up, get you out of this place; for the LORD will destroy this city. But he seemed as one that mocked unto his sons in law.

15 Nigbati ọ̀yẹ si nla, nigbana li awọn angeli na le Loti ni ire wipe, Dide, mu aya rẹ, ati awọn ọmọbinrin rẹ mejeji ti o wà nihin; ki iwọ ki o má ba run ninu ìya ẹ̀ṣẹ ilu yi.

15 And when the morning arose, then the angels hastened Lot, saying, Arise, take thy wife, and thy two daughters, which are here; lest thou be consumed in the iniquity of the city.

16 Nigbati o si nlọra, awọn ọkunrin na nawọ mu u li ọwọ́, ati ọwọ́ aya rẹ̀, ati ọwọ́ ọmọbinrin rẹ̀ mejeji; OLUWA sa ṣãnu fun u: nwọn si mu u jade, nwọn si fi i sẹhin odi ilu na.

16 And while he lingered, the men laid hold upon his hand, and upon the hand of his wife, and upon the hand of his two daughters; the LORD being merciful unto him: and they brought him forth, and set him without the city.

17 O si ṣe nigbati nwọn mu wọn jade sẹhin odi tan, li o wipe, Sá asalà fun ẹmi rẹ; máṣe wò ẹhin rẹ, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe duro ni gbogbo pẹtẹlẹ; sá asalà lọ si ori oke, ki iwọ ki o má ba ṣegbe.

17 And it came to pass, when they had brought them forth abroad, that he said, Escape for thy life; look not behind thee, neither stay thou in all the plain; escape to the mountain, lest thou be consumed.

18 Loti si wi fun wọn pe, Bẹ̃kọ, oluwa mi:

18 And Lot said unto them, Oh, not so, my Lord:

19 Kiyesi i na, ọmọ-ọdọ rẹ ti ri ore-ọfẹ gbà li oju rẹ, iwọ si ti gbe ãnu rẹ ga, ti iwọ ti fi hàn mi ni gbigbà ẹmi mi là; ṣugbọn emi ki yio le salọ si ori oke, ki ibi ki o má ba bá mi nibẹ̀, ki emi ki o má ba kú.

19 Behold now, thy servant hath found grace in thy sight, and thou hast magnified thy mercy, which thou hast shewed unto me in saving my life; and I cannot escape to the mountain, lest some evil take me, and I die:

20 Kiyesi i na, ilu yi sunmọ tosi lati sá si, kekere si ni: jọ̃, jẹ ki nsalà si ibẹ, (kekere ha kọ?) ọkàn mi yio si yè.

20 Behold now, this city is near to flee unto, and it is a little one: Oh, let me escape thither, (is it not a little one?) and my soul shall live.

21 O si wi fun u pe, Wò o, mo gbà fun ọ niti ohun kan yi pẹlu pe, emi ki yio run ilu yi, nitori eyiti iwọ ti sọ.

21 And he said unto him, See, I have accepted thee concerning this thing also, that I will not overthrow this city, for the which thou hast spoken.

22 Yara, salà sibẹ̀; nitori emi kò le ṣe ohun kan titi iwọ o fi de ibẹ̀. Nitorina li a ṣe npè orukọ ilu na ni Soari.

22 Haste thee, escape thither; for I cannot do any thing till thou be come thither. Therefore the name of the city was called Zoar.

23 Orùn là sori ilẹ nigbati Loti wọ̀ ilu Soari.

23 The sun was risen upon the earth when Lot entered into Zoar.

24 Nigbana li OLUWA rọ̀jo sulfuri (okuta ina) ati iná lati ọdọ OLUWA lati ọrun wá si ori Sodomu on Gomorra:

24 Then the LORD rained upon Sodom and upon Gomorrah brimstone and fire from the LORD out of heaven;

25 O si run ilu wọnni, ati gbogbo Pẹtẹlẹ, ati gbogbo awọn ara ilu wọnni, ati ohun ti o hù jade ni ilẹ.

25 And he overthrew those cities, and all the plain, and all the inhabitants of the cities, and that which grew upon the ground.

26 Ṣugbọn aya rẹ̀ bojuwò ẹhin lẹhin rẹ̀, o si di ọwọ̀n iyọ̀.

26 But his wife looked back from behind him, and she became a pillar of salt.

27 Abrahamu si dide ni kutukutu owurọ̀, o lọ si ibi ti o gbé duro niwaju OLUWA:

27 And Abraham gat up early in the morning to the place where he stood before the LORD:

28 O si wò ìha Sodomu on Gomorra, ati ìha gbogbo ilẹ àgbegbe wọnni, o si wò o, si kiyesi i, ẽfin ilẹ na rú soke bi ẽfin ileru.

28 And he looked toward Sodom and Gomorrah, and toward all the land of the plain, and beheld, and, lo, the smoke of the country went up as the smoke of a furnace.

29 O si ṣe nigbati Ọlọrun run ilu àgbegbe wọnni ni Ọlọrun ranti Abrahamu, o si rán Loti jade kuro lãrin iparun na, nigbati o run ilu wọnni ninu eyiti Loti gbé ti joko.

29 And it came to pass, when God destroyed the cities of the plain, that God remembered Abraham, and sent Lot out of the midst of the overthrow, when he overthrew the cities in the which Lot dwelt.

30 Loti si jade kuro ni Soari: o si ngbé ori oke, ati awọn ọmọbinrin rẹ̀ mejeji pẹlu rẹ̀; nitoriti o bẹ̀ru ati gbé Soari: o si ngbé inu ihò, on ati awọn ọmọbinrin rẹ̀ mejeji.

30 And Lot went up out of Zoar, and dwelt in the mountain, and his two daughters with him; for he feared to dwell in Zoar: and he dwelt in a cave, he and his two daughters.

31 Eyi akọbi si wi fun atẹle pe, Baba wa gbó, kò si sí ọkunrin kan li aiye mọ́ ti yio wọle tọ̀ wa wá gẹgẹ bi iṣe gbogbo aiye.

31 And the firstborn said unto the younger, Our father is old, and there is not a man in the earth to come in unto us after the manner of all the earth:

32 Wá, jẹ ki a mu baba wa mu ọti-waini, awa o si sùn tì i, ki a le ni irú-ọmọ lati ọdọ baba wa.

32 Come, let us make our father drink wine, and we will lie with him, that we may preserve seed of our father.

33 Nwọn si mu baba wọn mu ọti-waini li oru na: eyi akọbi wọle tọ̀ ọ, o si sùn tì baba rẹ̀; on kò si mọ̀ igbati o dubulẹ, ati igbati o dide.

33 And they made their father drink wine that night: and the firstborn went in, and lay with her father; and he perceived not when she lay down, nor when she arose.

34 O si ṣe, ni ijọ́ keji, ni ẹgbọn wi fun aburo pe, kiyesi i, emi sùn tì baba mi li oru aná: jẹ ki a si mu u mu ọti-waini li oru yi pẹlu: ki iwọ ki o si wọle, ki o si sùn tì i, ki awa ki o le ni irú-ọmọ lati ọdọ baba wa.

34 And it came to pass on the morrow, that the firstborn said unto the younger, Behold, I lay yesternight with my father: let us make him drink wine this night also; and go thou in, and lie with him, that we may preserve seed of our Father.

35 Nwọn si mu baba wọn mu ọti-waini li oru na pẹlu: aburo si dide, o si sùn tì i, on kò si mọ̀ igbati o dubulẹ, ati igbati o dide.

35 And they made their father drink wine that night also: and the younger arose, and lay with him; and he perceived not when she lay down, nor when she arose.

36 Bẹ̃li awọn ọmọbinrin Loti mejeji loyun fun baba wọn.

36 Thus were both the daughters of Lot with child by their father.

37 Eyi akọ́bi si bí ọmọkunrin kan, o si pè orukọ rẹ̀ ni Moabu: on ni baba awọn ara Moabu titi di oni.

37 And the firstborn bare a son, and called his name Moab: the same is the father of the Moabites unto this day.

38 Eyi atẹle, on pẹlu si bí ọmọkunrin kan, o si pè orukọ rẹ̀ ni Ben-ammi: on ni baba awọn ọmọ Ammoni, titi di oni.

38 And the younger, she also bare a son, and called his name Benammi: the same is the father of the children of Ammon unto this day.