Genesis 12 - Listen Online
Read Genesis 12
1 OLUWA si ti wi fun Abramu pe, Jade kuro ni ilẹ rẹ, ati kuro lọdọ awọn ara rẹ, ati kuro ni ile baba rẹ, si ilẹ kan ti emi o fi hàn ọ:
1 Now the LORD had said unto Abram, Get thee out of thy country, and from thy kindred, and from thy father's house, unto a land that I will shew thee:
2 Emi o si sọ ọ di orilẹ-ède nla, emi o si busi i fun ọ, emi o si sọ orukọ rẹ di nla; ibukun ni iwọ o si jasi:
2 And I will make of thee a great nation, and I will bless thee, and make thy name great; and thou shalt be a blessing:
3 Emi o bukun fun awọn ti nsúre fun ọ, ẹniti o nfi ọ ré li emi o si fi ré; ninu rẹ li a o ti bukun fun gbogbo idile aiye.
3 And I will bless them that bless thee, and curse him that curseth thee: and in thee shall all families of the earth be blessed.
4 Bẹ̃li Abramu lọ, bi OLUWA ti sọ fun u; Loti si ba a lọ: Abramu si jẹ ẹni arundilọgọrin ọdún nigbati o jade ni Harani.
4 So Abram departed, as the LORD had spoken unto him; and Lot went with him: and Abram was seventy and five years old when he departed out of Haran.
5 Abramu si mu Sarai aya rẹ̀, ati Loti ọmọ arakunrin rẹ̀, ati gbogbo ini wọn ti nwọn kojọ, enia gbogbo ti nwọn ni ni Harani, nwọn si jade lati lọ si ilẹ Kenaani; ni ilẹ Kenaani ni nwọn si wá si.
5 And Abram took Sarai his wife, and Lot his brother's son, and all their substance that they had gathered, and the souls that they had gotten in Haran; and they went forth to go into the land of Canaan; and into the land of Canaan they came.
6 Abramu si là ilẹ na kọja lọ si ibi ti a npè ni Ṣekemu, si igbo More. Awọn ara Kenaani si wà ni ilẹ na ni ìgba na.
6 And Abram passed through the land unto the place of Sichem, unto the plain of Moreh. And the Canaanite was then in the land.
7 OLUWA si fi ara hàn fun Abramu, o si wipe, Irú-ọmọ rẹ li emi o fi ilẹ yi fun: nibẹ̀ li o si tẹ́ pẹpẹ fun OLUWA ti o fi ara hàn a.
7 And the LORD appeared unto Abram, and said, Unto thy seed will I give this land: and there builded he an altar unto the LORD, who appeared unto him.
8 O si ṣí kuro nibẹ̀ lọ si ori oke kan ni ìha ìla-õrùn Beteli, o si pa agọ́ rẹ̀, Beteli ni ìwọ-õrùn ati Hai ni ìla-õrùn: o si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀ fun OLUWA, o si kepè orukọ OLUWA.
8 And he removed from thence unto a mountain on the east of Bethel, and pitched his tent, having Bethel on the west, and Hai on the east: and there he builded an altar unto the LORD, and called upon the name of the LORD.
9 Abramu si nrìn lọ, o nlọ si ìha gusù sibẹ̀.
9 And Abram journeyed, going on still toward the south.
10 Ìyan kan si mu ni ilẹ na: Abramu si sọkalẹ lọ si Egipti lati ṣe atipo nibẹ̀; nitoriti ìyan na mu gidigidi ni ilẹ na.
10 And there was a famine in the land: and Abram went down into Egypt to sojourn there; for the famine was grievous in the land.
11 O si ṣe, nigbati o kù si dẹ̀dẹ lati wọ̀ Egipti, o wi fun Sarai aya rẹ̀ pe, Kiyesi i nisisiyi, emi mọ̀ pe arẹwà obinrin lati wò ni iwọ:
11 And it came to pass, when he was come near to enter into Egypt, that he said unto Sarai his wife, Behold now, I know that thou art a fair woman to look upon:
12 Nitorina yio si ṣe, nigbati awọn ara Egipti yio ri ọ, nwọn o wipe, aya rẹ̀ li eyi: nwọn o si pa mi, ṣugbọn nwọn o dá ọ si.
12 Therefore it shall come to pass, when the Egyptians shall see thee, that they shall say, This is his wife: and they will kill me, but they will save thee alive.
13 Mo bẹ̀ ọ, wipe, arabinrin mi ni iwọ iṣe: ki o le irọ̀ mi lọrùn nitori rẹ; ọkàn mi yio si yè nitori rẹ.
13 Say, I pray thee, thou art my sister: that it may be well with me for thy sake; and my soul shall live because of thee.
14 O si ṣe nigbati Abramu de Egipti, awọn ara Egipti wò obinrin na pe arẹwà enia gidigidi ni.
14 And it came to pass, that, when Abram was come into Egypt, the Egyptians beheld the woman that she was very fair.
15 Awọn ijoye Farao pẹlu ri i, nwọn si ròhin rẹ̀ niwaju Farao; a si mu obinrin na lọ si ile Farao.
15 The princes also of Pharaoh saw her, and commended her before Pharaoh: and the woman was taken into Pharaoh's house.
16 O si nṣikẹ Abramu gidigidi nitori rẹ̀: on si li agutan, ati akọ-malu, ati akọ-kẹtẹkẹtẹ, ati iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin, abo-kẹtẹkẹtẹ, ati ibakasiẹ.
16 And he entreated Abram well for her sake: and he had sheep, and oxen, and he asses, and menservants, and maidservants, and she asses, and camels.
17 OLUWA si fi iyọnu nla yọ Farao ati awọn ara ile rẹ̀ li ẹnu, nitori Sarai aya Abramu.
17 And the LORD plagued Pharaoh and his house with great plagues because of Sarai Abram's wife.
18 Farao si pè Abramu, o wipe, ewo li eyiti iwọ ṣe si mi yi? ẽṣe ti iwọ kò fi wi fun mi pe, aya rẹ ni iṣe?
18 And Pharaoh called Abram, and said, What is this that thou hast done unto me? why didst thou not tell me that she was thy wife?
19 Ẽṣe ti iwọ fi wipe, arabinrin mi ni iṣe? bẹ̃li emi iba fẹ ẹ li aya mi si: njẹ nisisiyi wò aya rẹ, mu u, ki o si ma ba tirẹ lọ.
19 Why saidst thou, She is my sister? so I might have taken her to me to wife: now therefore behold thy wife, take her, and go thy way.
20 Farao si paṣẹ fun awọn ọkunrin rẹ̀ nitori Abramu: nwọn si sìn i jade lọ, ati aya rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ni.
20 And Pharaoh commanded his men concerning him: and they sent him away, and his wife, and all that he had.