Ezekiel 16 - Listen Online
Read Ezekiel 16
1 Ọ̀RỌ Oluwa tún tọ̀ mi wá, wipe,
1 Again the word of the LORD came unto me, saying,
2 Ọmọ enia, jẹ ki Jerusalemu mọ̀ ohun irira rẹ̀.
2 Son of man, cause Jerusalem to know her abominations,
3 Si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi si Jerusalemu; Ibi rẹ ati ilẹ ibi rẹ ni ati ilẹ Kenaani wá; ará Amori ni baba rẹ, ará Hiti si ni iyá rẹ.
3 And say, Thus saith the Lord GOD unto Jerusalem; Thy birth and thy nativity is of the land of Canaan; thy father was an Amorite, and thy mother an Hittite.
4 Ati niti ìbi rẹ, a kò da ọ ni iwọ́ ni ijọ ti a bi ọ, bẹ̃ni a kò wẹ̀ ọ ninu omi lati mu ọ mọ́, a kò fi iyọ̀ pa ọ lara rara, bẹ̃ni a kò fi ọja wé ọ rara.
4 And as for thy nativity, in the day thou wast born thy navel was not cut, neither wast thou washed in water to supple thee; thou wast not salted at all, nor swaddled at all.
5 Kò si oju ti o kãnu fun ọ, lati ṣe ọkan ninu nkan wọnyi fun ọ, lati ṣe iyọnu si ọ; ṣugbọn ninu igbẹ li a gbe ọ sọ si, fun ikorira ara rẹ, ni ijọ ti a bi ọ.
5 None eye pitied thee, to do any of these unto thee, to have compassion upon thee; but thou wast cast out in the open field, to the lothing of thy person, in the day that thou wast born.
6 Nigbati mo si kọja lọdọ rẹ, ti mo si ri ọ, ti a tẹ̀ ọ mọlẹ ninu ẹjẹ ara rẹ, mo wi fun ọ nigbati iwọ wà ninu ẹjẹ rẹ pe, Yè: nitõtọ, mo wi fun ọ nigbati iwọ wà ninu ẹjẹ rẹ pe, Yè.
6 And when I passed by thee, and saw thee polluted in thine own blood, I said unto thee when thou wast in thy blood, Live; yea, I said unto thee when thou wast in thy blood, Live.
7 Emi ti mu ọ bi si i bi irudi itàna ìgbẹ; iwọ si ti pọ̀ si i, o si ti di nla, iwọ si gbà ohun ọṣọ́ ti o ti inu ọṣọ́ wá: a ṣe ọmú rẹ yọ, irun rẹ si dagba, nigbati o jẹ pe iwọ ti wà nihoho ti o si wà goloto.
7 I have caused thee to multiply as the bud of the field, and thou hast increased and waxen great, and thou art come to excellent ornaments: thy breasts are fashioned, and thine hair is grown, whereas thou wast naked and bare.
8 Nigbati mo si kọja lọdọ rẹ, ti mo si wò ọ; kiye si i, ìgba rẹ jẹ ìgba ifẹ; mo si nà aṣọ mi bò ọ, mo si bo ihoho rẹ: nitõtọ, mo bura fun ọ, mo si ba ọ da majẹmu, ni Oluwa Ọlọrun wi, iwọ si di temi.
8 Now when I passed by thee, and looked upon thee, behold, thy time was the time of love; and I spread my skirt over thee, and covered thy nakedness: yea, I sware unto thee, and entered into a covenant with thee, saith the Lord GOD, and thou becamest mine.
9 Nigbana ni mo fi omi wẹ̀ ọ; nitõtọ, mo wẹ ẹjẹ rẹ kuro lara rẹ patapata, mo si fi ororo kùn ọ lara.
9 Then washed I thee with water; yea, I throughly washed away thy blood from thee, and I anointed thee with oil.
10 Mo wọ̀ ọ laṣọ oniṣẹ-ọnà pẹlu, mo si fi awọ̀ badgeri wọ̀ ọ ni bàta, mo si fi aṣọ ọ̀gbọ daradara di ọ ni amure yika, mo si fi aṣọ ṣẹ́dà bò ọ.
10 I clothed thee also with broidered work, and shod thee with badgers' skin, and I girded thee about with fine linen, and I covered thee with silk.
11 Mo fi ohun-ọṣọ ṣe ọ lọṣọ pẹlu, mo si fi júfu bọ̀ ọ lọwọ, mo si fi ẹ̀wọn kọ́ ọ li ọrùn.
11 I decked thee also with ornaments, and I put bracelets upon thy hands, and a chain on thy neck.
12 Mo si fi oruka si ọ ni imú, mo si fi oruka bọ̀ ọ leti, mo si fi ade daradara de ọ lori.
12 And I put a jewel on thy forehead, and earrings in thine ears, and a beautiful crown upon thine head.
13 Bayi ni a fi wura ati fadaka ṣe ọ lọṣọ; aṣọ rẹ si jẹ ọgbọ̀ daradara, ati ṣẹ́dà, ati aṣọ oniṣẹ-ọnà; iwọ jẹ iyẹfun daradara ati oyin, ati ororo: iwọ si ni ẹwà gidigidi, iwọ si gbilẹ di ijọba kan.
13 Thus wast thou decked with gold and silver; and thy raiment was of fine linen, and silk, and broidered work; thou didst eat fine flour, and honey, and oil: and thou wast exceeding beautiful, and thou didst prosper into a kingdom.
14 Okiki rẹ si kan lãrin awọn keferi nitori ẹwà rẹ: nitori iwọ pé nipa ẹwà mi, ti mo fi si ọ lara, ni Oluwa Ọlọrun wi.
14 And thy renown went forth among the heathen for thy beauty: for it was perfect through my comeliness, which I had put upon thee, saith the Lord GOD.
15 Ṣugbọn iwọ gbẹkẹle ẹwà ara rẹ, o si huwa panṣaga nitori okìki rẹ, o si dà gbogbo agbere rẹ sori olukuluku ẹniti nkọja: tirẹ̀ ni.
15 But thou didst trust in thine own beauty, and playedst the harlot because of thy renown, and pouredst out thy fornications on every one that passed by; his it was.
16 Iwọ si mu ninu ẹwù rẹ, iwọ si fi aṣọ alaràbarà ṣe ibi giga rẹ lọṣọ, o si hùwa panṣaga nibẹ: iru nkan bẹ̃ kì yio de, bẹ̃ni kì yio ri bẹ̃.
16 And of thy garments thou didst take, and deckedst thy high places with divers colours, and playedst the harlot thereupon: the like things shall not come, neither shall it be so.
17 Iwọ si mu ohun ọṣọ́ ẹlẹwà rẹ ninu wura mi, ati ninu fadaka mi, ti mo ti fun ọ, iwọ si ṣe àworán ọkunrin fun ara rẹ, o si fi wọn ṣe panṣaga,
17 Thou hast also taken thy fair jewels of my gold and of my silver, which I had given thee, and madest to thyself images of men, and didst commit whoredom with them,
18 Iwọ si mu ẹwù oniṣẹ-ọnà rẹ, o si fi bò wọn: iwọ si gbe ororo mi ati turari mi kalẹ niwaju wọn.
18 And tookest thy broidered garments, and coveredst them: and thou hast set mine oil and mine incense before them.
19 Onjẹ mi pẹlu ti mo ti fun ọ, iyẹfun daradara, ati ororo, ati oyin, ti mo fi bọ́ ọ, iwọ tilẹ gbe e kalẹ niwaju wọn fun õrùn didùn: bayi li o si ri, ni Oluwa Ọlọrun wi.
19 My meat also which I gave thee, fine flour, and oil, and honey, wherewith I fed thee, thou hast even set it before them for a sweet savour: and thus it was, saith the Lord GOD.
20 Pẹlupẹlu iwọ ti mu awọn ọmọ rẹ ọkunrin ati awọn ọmọ rẹ obinrin, ti iwọ ti bi fun mi, awọn wọnyi ni iwọ si ti fi rubọ si wọn lati jẹ. Ohun kekere ha ni eyi ninu ìwa panṣaga rẹ,
20 Moreover thou hast taken thy sons and thy daughters, whom thou hast borne unto me, and these hast thou sacrificed unto them to be devoured. Is this of thy whoredoms a small matter,
21 Ti iwọ ti pa awọn ọmọ mi, ti o si fi wọn fun ni lati mu wọn kọja lãrin iná fun wọn?
21 That thou hast slain my children, and delivered them to cause them to pass through the fire for them?
22 Ati ni gbogbo ohun irira rẹ, ati panṣaga rẹ, iwọ kò ranti ọjọ ewe rẹ, nigbati iwọ wà nihoho ti o si wà goloto, ti a si bà ọ jẹ ninu ẹjẹ rẹ.
22 And in all thine abominations and thy whoredoms thou hast not remembered the days of thy youth, when thou wast naked and bare, and wast polluted in thy blood.
23 O si ṣe lẹhin gbogbo ìwa buburu rẹ, (Egbe, egbe ni fun ọ! ni Oluwa Ọlọrun wi;)
23 And it came to pass after all thy wickedness, (woe, woe unto thee! saith the Lord GOD;)
24 Ti iwọ si kọ́ ile giga fun ara rẹ, ti iwọ si ṣe ibi giga ni gbogbo ita fun ara rẹ.
24 That thou hast also built unto thee an eminent place, and hast made thee an high place in every street.
25 Iwọ ti kọ́ ibi giga rẹ ni gbogbo ikórita, o si ti sọ ẹwà rẹ di ikorira, o si ti ya ẹsẹ rẹ si gbogbo awọn ti nkọja, o si sọ panṣaga rẹ di pupọ.
25 Thou hast built thy high place at every head of the way, and hast made thy beauty to be abhorred, and hast opened thy feet to every one that passed by, and multiplied thy whoredoms.
26 Iwọ ti ba awọn ara Egipti aladugbo rẹ, ti o sanra ṣe agbere, o si ti sọ panṣaga rẹ di pupọ, lati mu mi binu.
26 Thou hast also committed fornication with the Egyptians thy neighbours, great of flesh; and hast increased thy whoredoms, to provoke me to anger.
27 Kiye si i, emi si ti nawọ mi le ọ lori, mo si ti bu onjẹ rẹ kù, mo si fi ọ fun ifẹ awọn ti o korira rẹ, awọn ọmọbinrin Filistia, ti ìwa ifẹkufẹ rẹ tì loju.
27 Behold, therefore I have stretched out my hand over thee, and have diminished thine ordinary food, and delivered thee unto the will of them that hate thee, the daughters of the Philistines, which are ashamed of thy lewd way.
28 Iwọ ti ba awọn ara Assiria ṣe panṣaga pẹlu, nitori iwọ kò ni itẹlọrun; nitotọ, iwọ ti ba wọn ṣe panṣaga, sibẹsibẹ kò si le tẹ́ ọ lọrùn,
28 Thou hast played the whore also with the Assyrians, because thou wast unsatiable; yea, thou hast played the harlot with them, and yet couldest not be satisfied.
29 Iwọ si ti sọ agbere rẹ di pupọ lati ilẹ Kenaani de Kaldea; sibẹsibẹ eyi kò si tẹ́ ọ lọrun nihinyi.
29 Thou hast moreover multiplied thy fornication in the land of Canaan unto Chaldea; and yet thou wast not satisfied herewith.
30 Oluwa Ọlọrun wipe, aiyà rẹ ti ṣe alailera to, ti iwọ nṣe nkan wọnyi, iṣe agídi panṣaga obinrin;
30 How weak is thine heart, saith the Lord GOD, seeing thou doest all these things, the work of an imperious whorish woman;
31 Nitipe iwọ kọ́ ile giga rẹ ni gbogbo ikoríta, ti o si ṣe ibi giga rẹ ni gbogbo ita; iwọ kò si wa dabi panṣaga obinrin, nitipe iwọ gan ọ̀ya.
31 In that thou buildest thine eminent place in the head of every way, and makest thine high place in every street; and hast not been as an harlot, in that thou scornest hire;
32 Ṣugbọn gẹgẹ bi aya ti o ṣe panṣaga, ti o gbà alejo dipo ọkọ rẹ̀!
32 But as a wife that committeth adultery, which taketh strangers instead of her husband!
33 Nwọn nfi ẹbùn fun gbogbo awọn panṣaga, ṣugbọn iwọ fi ẹbùn rẹ fun gbogbo awọn olufẹ rẹ, iwọ si ta wọn lọrẹ, ki nwọn le tọ̀ ọ wá ni ihà gbogbo fun panṣaga rẹ.
33 They give gifts to all whores: but thou givest thy gifts to all thy lovers, and hirest them, that they may come unto thee on every side for thy whoredom.
34 Eyiti o yatọ si ti awọn obinrin miran si mbẹ ninu rẹ, ninu panṣaga rẹ, ti ẹnikan kò tẹ̀le ọ lati ṣe panṣaga: ati nitipe iwọ ntọrẹ, ti a kò si tọrẹ fun ọ nitorina iwọ yatọ.
34 And the contrary is in thee from other women in thy whoredoms, whereas none followeth thee to commit whoredoms: and in that thou givest a reward, and no reward is given unto thee, therefore thou art contrary.
35 Nitorina, iwọ panṣaga, gbọ́ ọ̀rọ Oluwa:
35 Wherefore, O harlot, hear the word of the LORD:
36 Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Nitoriti a dà ẹgbin rẹ jade, ti a si ri ihoho rẹ nipa panṣaga rẹ pẹlu awọn olufẹ rẹ, ati pẹlu gbogbo oriṣa irira rẹ, ati nipa ẹjẹ awọn ọmọ rẹ, ti iwọ fi fun wọn:
36 Thus saith the Lord GOD; Because thy filthiness was poured out, and thy nakedness discovered through thy whoredoms with thy lovers, and with all the idols of thy abominations, and by the blood of thy children, which thou didst give unto them;
37 Si kiye si i, Emi o kó gbogbo awọn olufẹ rẹ jọ, awọn ẹniti iwọ ti ba jaiye, ati gbogbo awọn ti iwọ ti fẹ, pẹlu gbogbo awọn ti iwọ ti korira; ani emi o gbá wọn jọ kakiri si ọ, emi o si fi ihoho rẹ hàn wọn, ki nwọn ki o le ri gbogbo ihoho rẹ.
37 Behold, therefore I will gather all thy lovers, with whom thou hast taken pleasure, and all them that thou hast loved, with all them that thou hast hated; I will even gather them round about against thee, and will discover thy nakedness unto them, that they may see all thy nakedness.
38 Emi o si dá ọ lẹjọ, gẹgẹ bi a ti da awọn obinrin lẹjọ ti o ba igbeyawo jẹ ti nwọn si ta ẹjẹ silẹ; emi o si fi ẹjẹ fun ọ, ni irúnu ati ni ijowu.
38 And I will judge thee, as women that break wedlock and shed blood are judged; and I will give thee blood in fury and jealousy.
39 Emi o si fi ọ le wọn lọwọ pẹlu, nwọn o si wo ibi giga rẹ, nwọn o si wo ibi giga rẹ palẹ: nwọn o si bọ aṣọ rẹ pẹlu, nwọn o si gbà ohun ọṣọ rẹ didara, nwọn o si fi ọ silẹ ni ihoho, ati ni goloto.
39 And I will also give thee into their hand, and they shall throw down thine eminent place, and shall break down thy high places: they shall strip thee also of thy clothes, and shall take thy fair jewels, and leave thee naked and bare.
40 Nwọn o mu ẹgbẹ́ kan wá si ọ pẹlu, nwọn o si sọ ọ li okuta, nwọn o si fi idà wọn gún ọ yọ.
40 They shall also bring up a company against thee, and they shall stone thee with stones, and thrust thee through with their swords.
41 Nwọn o si fi iná kun gbogbo ile rẹ; nwọn o si mu idajọ ṣẹ si ọ lara niwaju obinrin pupọ; emi o si jẹ ki o fi panṣaga rẹ mọ, iwọ pẹlu kì yio si funni ni ọ̀ya mọ.
41 And they shall burn thine houses with fire, and execute judgments upon thee in the sight of many women: and I will cause thee to cease from playing the harlot, and thou also shalt give no hire any more.
42 Bẹ̃ni emi o jẹ ki irúnu mi si ọ ki o dá, owú mi yio si kuro lọdọ rẹ, emi o si dakẹjẹ, emi kì yio binu mọ.
42 So will I make my fury toward thee to rest, and my jealousy shall depart from thee, and I will be quiet, and will be no more angry.
43 Nitoripe iwọ kò ranti ọjọ ewe rẹ, ṣugbọn o si mu mi kanra ninu gbogbo nkan wọnyi; si kiye si i, nitorina emi pẹlu o san ẹsan ọ̀na rẹ si ọ lori, ni Oluwa Ọlọrun wi: iwọ kì yio si ṣe ifẹkufẹ yi lori gbogbo ohun irira rẹ mọ.
43 Because thou hast not remembered the days of thy youth, but hast fretted me in all these things; behold, therefore I also will recompense thy way upon thine head, saith the Lord GOD: and thou shalt not commit this lewdness above all thine abominations.
44 Kiyesi i, olukuluku ẹniti npowe ni yio powe yi si ọ, wipe, Bi iyá ti ri, bẹ̃ni ọmọ rẹ̀ obinrin.
44 Behold, every one that useth proverbs shall use this proverb against thee, saying, As is the mother, so is her daughter.
45 Iwọ ni ọmọ iyá rẹ ti o kọ̀ ọkọ rẹ̀, ati awọn ọmọ rẹ̀; iwọ ni arabinrin awọn arabinrin rẹ, ti o kọ̀ awọn ọkọ wọn ati awọn ọmọ wọn: ará Hiti ni iyá rẹ, ará Amori si ni baba rẹ.
45 Thou art thy mother's daughter, that lotheth her husband and her children; and thou art the sister of thy sisters, which lothed their husbands and their children: your mother was an Hittite, and your father an Amorite.
46 Ẹgbọn rẹ obinrin si ni Samaria, on ati awọn ọmọbinrin rẹ ti ngbe ọwọ́ osì rẹ: ati aburo rẹ obinrin ti ngbe ọwọ́ ọ̀tun rẹ ni Sodomu ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin.
46 And thine elder sister is Samaria, she and her daughters that dwell at thy left hand: and thy younger sister, that dwelleth at thy right hand, is Sodom and her daughters.
47 Ṣugbọn iwọ kò rin ni ọ̀na wọn, iwọ kò si ṣe gẹgẹ bi irira wọn: ṣugbọn, bi ẹnipe ohun kekere ni eyini, iwọ bajẹ jù wọn lọ ni gbogbo ọ̀na rẹ.
47 Yet hast thou not walked after their ways, nor done after their abominations: but, as if that were a very little thing, thou wast corrupted more than they in all thy ways.
48 Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà, Sodomu arabinrin rẹ, on, tabi awọn ọmọ rẹ̀ obinrin kò ṣe gẹgẹ bi iwọ ti ṣe, iwọ ati awọn ọmọ rẹ obinrin.
48 As I live, saith the Lord GOD, Sodom thy sister hath not done, she nor her daughters, as thou hast done, thou and thy daughters.
49 Kiyesi i, ẹ̀ṣẹ Sodomu arabinrin rẹ niyi, irera, onjẹ ajẹyo, ati ọ̀pọlọpọ orayè wà ninu rẹ̀, ati ninu awọn ọmọ rẹ̀ obinrin; bẹ̃ni on kò mu ọwọ́ talaka ati alaini lokun.
49 Behold, this was the iniquity of thy sister Sodom, pride, fulness of bread, and abundance of idleness was in her and in her daughters, neither did she strengthen the hand of the poor and needy.
50 Nwọn si gberaga, nwọn si ṣe ohun irira niwaju mi: nitorina ni mo mu wọn kuro gẹgẹ bi mo ti ri pe o dara.
50 And they were haughty, and committed abomination before me: therefore I took them away as I saw good.
51 Bẹ̃ni Samaria kò dá abọ̀ ẹ̀ṣẹ rẹ: ṣugbọn iwọ sọ ohun irira rẹ di pupọ jù wọn lọ, o si ti da awọn arabinrin rẹ lare ninu gbogbo ohun irira rẹ ti iwọ ti ṣe.
51 Neither hath Samaria committed half of thy sins; but thou hast multiplied thine abominations more than they, and hast justified thy sisters in all thine abominations which thou hast done.
52 Iwọ pẹlu, ti o ti da awọn arabinrin rẹ lẹbi, ru itiju ara rẹ, nitori ẹ̀ṣẹ rẹ ti iwọ ti ṣe ni iṣe irira jù wọn lọ: awọn ṣe olododo jù iwọ lọ; nitotọ, ki iwọ ki o dãmu pẹlu, si ru itiju rẹ, nitipe iwọ dá awọn arabinrin rẹ lare.
52 Thou also, which hast judged thy sisters, bear thine own shame for thy sins that thou hast committed more abominable than they: they are more righteous than thou: yea, be thou confounded also, and bear thy shame, in that thou hast justified thy sisters.
53 Nigbati mo ba tun mu igbèkun wọn wá, igbèkun Sodomu ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin, pẹlu igbèkun Samaria ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin, nigbana li emi o tun mu igbèkun awọn onde rẹ wá lãrin wọn:
53 When I shall bring again their captivity, the captivity of Sodom and her daughters, and the captivity of Samaria and her daughters, then will I bring again the captivity of thy captives in the midst of them:
54 Ki iwọ ki o le ru itiju ara rẹ, ki o si le dãmu ni gbogbo eyi ti o ti ṣe, nitipe iwọ jẹ itunu fun wọn.
54 That thou mayest bear thine own shame, and mayest be confounded in all that thou hast done, in that thou art a comfort unto them.
55 Nigbati awọn arabinrin rẹ Sodomu, ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin, ba pada si ipò wọn iṣaju, ti Samaria ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin ba pada si ipò wọn iṣaju, nigbana ni iwọ ati awọn ọmọ rẹ obinrin yio pada si ipò nyin iṣaju.
55 When thy sisters, Sodom and her daughters, shall return to their former estate, and Samaria and her daughters shall return to their former estate, then thou and thy daughters shall return to your former estate.
56 Nitori ẹnu rẹ kò da orukọ Sodomu arabinrin rẹ li ọjọ irera rẹ,
56 For thy sister Sodom was not mentioned by thy mouth in the day of thy pride,
57 Ki a to ri ìwa buburu rẹ, bi akoko ti awọn ọmọbinrin Siria gàn ọ, ati gbogbo awọn ti o wà yi i ka, awọn ọmọbinrin Filistia ti o gàn ọ ka kiri.
57 Before thy wickedness was discovered, as at the time of thy reproach of the daughters of Syria, and all that are round about her, the daughters of the Philistines, which despise thee round about.
58 Iwọ ti ru ifẹkufẹ rẹ ati ohun irira rẹ, ni Oluwa wi.
58 Thou hast borne thy lewdness and thine abominations, saith the LORD.
59 Nitori bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Emi o tilẹ ba ọ lò gẹgẹ bi iwọ ti ṣe, ti iwọ ti gàn ibura nipa biba majẹmu jẹ.
59 For thus saith the Lord GOD; I will even deal with thee as thou hast done, which hast despised the oath in breaking the covenant.
60 Ṣugbọn emi o ranti majẹmu mi pẹlu rẹ, ni ọjọ ewe rẹ, emi o si gbe majẹmu aiyeraiye kalẹ fun ọ.
60 Nevertheless I will remember my covenant with thee in the days of thy youth, and I will establish unto thee an everlasting covenant.
61 Iwọ o si ranti ọ̀na rẹ, oju o si tì ọ, nigbati iwọ ba gba awọn arabinrin rẹ, ẹgbọ́n rẹ ati aburò rẹ: emi o si fi wọn fun ọ bi ọmọbinrin, ṣugbọn ki iṣe nipa majẹmu rẹ.
61 Then thou shalt remember thy ways, and be ashamed, when thou shalt receive thy sisters, thine elder and thy younger: and I will give them unto thee for daughters, but not by thy covenant.
62 Emi o si gbe majẹmu mi kalẹ pẹlu rẹ; iwọ o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
62 And I will establish my covenant with thee; and thou shalt know that I am the LORD:
63 Ki iwọ ki o le ranti, ki o si le dãmu, ki iwọ ki o má si le yà ẹnu rẹ mọ nitori itiju rẹ, nigbati inu mi ba tutù si ọ, nitori ohun ti iwọ ti ṣe, ni Oluwa Ọlọrun wi.
63 That thou mayest remember, and be confounded, and never open thy mouth any more because of thy shame, when I am pacified toward thee for all that thou hast done, saith the Lord GOD.