Acts 18 - Listen Online
Read Acts 18
1 LẸHIN nkan wọnyi, Paulu jade kuro ni Ateni, o si lọ si Korinti;
1 After these things Paul departed from Athens, and came to Corinth;
2 O si ri Ju kan ti a npè ni Akuila, ti a bí ni Pontu, ti o ti Itali de nilọ̃lọ̃, pẹlu Priskilla aya rẹ̀; nitoriti Klaudiu paṣẹ pe, ki gbogbo awọn Ju ki o jade kuro ni Romu: o si tọ̀ wọn wá.
2 And found a certain Jew named Aquila, born in Pontus, lately come from Italy, with his wife Priscilla; (because that Claudius had commanded all Jews to depart from Rome:) and came unto them.
3 Ati itori ti iṣe oniṣẹ ọnà kanna, o ba wọn joko, o si nṣiṣẹ: nitori agọ́ pipa ni iṣẹ ọnà wọn.
3 And because he was of the same craft, he abode with them, and wrought: for by their occupation they were tentmakers.
4 O si nfọ̀rọ̀ we ọrọ fun wọn ninu sinagogu li ọjọjọ isimi, o si nyi awọn Ju ati awọn Hellene li ọkàn pada.
4 And he reasoned in the synagogue every sabbath, and persuaded the Jews and the Greeks.
5 Nigbati Sila on Timotiu si ti Makedonia wá, ọrọ na ká Paulu lara, o nfi hàn, o sọ fun awọn Ju pe, Jesu ni Kristi na.
5 And when Silas and Timotheus were come from Macedonia, Paul was pressed in the spirit, and testified to the Jews that Jesus was Christ.
6 Nigbati nwọn si wà li òdi, ti nwọn si nsọrọ-odi, o gbọ̀n aṣọ rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Ẹ̀jẹ nyin mbẹ lori ara nyin; ọrùn emi mọ́: lati isisiyi lọ emi o tọ̀ awọn Keferi lọ.
6 And when they opposed themselves, and blasphemed, he shook his raiment, and said unto them, Your blood be upon your own heads; I am clean: from henceforth I will go unto the Gentiles.
7 O si lọ kuro nibẹ̀, o wọ̀ ile ọkunrin kan ti a npè ni Titu Justu, ẹniti o nsìn Ọlọrun ti ile rẹ̀ fi ara mọ́ sinagogu tímọ́tímọ́.
7 And he departed thence, and entered into a certain man's house, named Justus, one that worshipped God, whose house joined hard to the synagogue.
8 Ati Krispu, olori sinagogu, o gbà Oluwa gbọ́ pẹlu gbogbo ile rẹ̀; ati ọ̀pọ ninu awọn ara Korinti, nigbati nwọn gbọ́, nwọn gbagbọ́, a si baptisi wọn.
8 And Crispus, the chief ruler of the synagogue, believed on the Lord with all his house; and many of the Corinthians hearing believed, and were baptized.
9 Oluwa si sọ fun Paulu li oru li ojuran pe, Má bẹ̀ru, sá mã sọ, má si ṣe pa ẹnu rẹ mọ́:
9 Then spake the Lord to Paul in the night by a vision, Be not afraid, but speak, and hold not thy peace:
10 Nitoriti emi wà pẹlu rẹ, kò si si ẹniti yio dide si ọ lati pa ọ lara: nitori mo li enia pipọ ni ilu yi.
10 For I am with thee, and no man shall set on thee to hurt thee: for I have much people in this city.
11 O si joko nibẹ̀ li ọdún kan on oṣù mẹfa, o nkọ́ni li ọ̀rọ Ọlọrun lãrin wọn.
11 And he continued there a year and six months, teaching the word of God among them.
12 Nigbati Gallioni si jẹ bãlẹ Akaia, awọn Ju fi ọkàn kan dide si Paulu, nwọn si mu u wá siwaju itẹ idajọ.
12 And when Gallio was the deputy of Achaia, the Jews made insurrection with one accord against Paul, and brought him to the judgment seat,
13 Nwọn wipe, ọkunrin yi nyi awọn enia li ọkàn pada, lati mã sin Ọlọrun lodi si ofin.
13 Saying, This fellow persuadeth men to worship God contrary to the law.
14 Nigbati Paulu nfẹ ati dahùn, Gallioni wi fun awọn Ju pe, Ibaṣepe ọ̀ran buburu tabi ti jagidijagan kan ni, bi ọ̀rọ ti ri, ẹnyin Ju, emi iba gbè nyin:
14 And when Paul was now about to open his mouth, Gallio said unto the Jews, If it were a matter of wrong or wicked lewdness, O ye Jews, reason would that I should bear with you:
15 Ṣugbọn bi o ba ṣe ọ̀ran nipa ọ̀rọ ati orukọ, ati ti ofin nyin ni, ki ẹnyin ki o bojuto o fun ara nyin, nitoriti emi kò fẹ ṣe onidajọ nkan bawọnni.
15 But if it be a question of words and names, and of your law, look ye to it; for I will be no judge of such matters.
16 O si lé wọn kuro ni ibi itẹ idajọ.
16 And he drave them from the judgment seat.
17 Gbogbo awọn Hellene si mu Sostene, olori sinagogu, nwọn si lù u niwaju itẹ idajọ. Gallioni kò si ṣú si nkan wọnyi.
17 Then all the Greeks took Sosthenes, the chief ruler of the synagogue, and beat him before the judgment seat. And Gallio cared for none of those things.
18 Paulu si duro si i nibẹ̀ li ọjọ pipọ, nigbati o si dágbere fun awọn arakunrin, o ba ti ọkọ̀ lọ si Siria, ati Priskilla ati Akuila pẹlu rẹ̀; o ti fá ori rẹ̀ ni Kenkrea: nitoriti o ti jẹjẹ.
18 And Paul after this tarried there yet a good while, and then took his leave of the brethren, and sailed thence into Syria, and with him Priscilla and Aquila; having shorn his head in Cenchrea: for he had a vow.
19 O si sọkalẹ wá si Efesu, o si fi wọn silẹ nibẹ̀: ṣugbọn on tikararẹ̀ wọ̀ inu sinagogu lọ, o si ba awọn Ju fi ọrọ we ọrọ.
19 And he came to Ephesus, and left them there: but he himself entered into the synagogue, and reasoned with the Jews.
20 Nigbati nwọn si bẹ̀ ẹ pe, ki o ba awọn joko diẹ si i, o kọ̀;
20 When they desired him to tarry longer time with them, he consented not;
21 Ṣugbọn o dágbere fun wọn, o si wipe, Emi kò gbọdọ ṣaima ṣe ajọ ọdún ti mbọ̀ yi ni Jerusalemu bi o ti wù ki o ri: ṣugbọn emi ó tún pada tọ̀ nyin wá, bi Ọlọrun ba fẹ. O si ṣikọ̀ ni Efesu.
21 But bade them farewell, saying, I must by all means keep this feast that cometh in Jerusalem: but I will return again unto you, if God will. And he sailed from Ephesus.
22 Nigbati o si ti gúnlẹ ni Kesarea, ti o goke, ti o si ki ijọ, o sọkalẹ lọ si Antioku.
22 And when he had landed at Caesarea, and gone up, and saluted the church, he went down to Antioch.
23 Nigbati o si gbé ọjọ diẹ nibẹ̀, o lọ, o si kọja ni ilẹ Galatia on Frigia lẹsẹsẹ, o nmu gbogbo awọn ọmọ-ẹhin li ọkàn le.
23 And after he had spent some time there, he departed, and went over all the country of Galatia and Phrygia in order, strengthening all the disciples.
24 Ju kan si wà ti a npè ni Apollo, ti a bí ni Aleksandria, ọkunrin ọlọrọ li ẹnu, ti o pọ̀ ni iwe-mimọ́, o wá si Efesu.
24 And a certain Jew named Apollos, born at Alexandria, an eloquent man, and mighty in the scriptures, came to Ephesus.
25 Ọkunrin yi li a ti kọ́ ni ọ̀na ti Oluwa; o si ṣe ẹniti o gboná li ọkàn, o nfi ãyan nsọ̀rọ, o si nkọ́ni ni nkan ti Oluwa; kìki baptismu ti Johanu li o mọ̀.
25 This man was instructed in the way of the Lord; and being fervent in the spirit, he spake and taught diligently the things of the Lord, knowing only the baptism of John.
26 O si bẹ̀rẹ si fi igboiya sọrọ ni sinagogu: nigbati Akuila on Priskilla ti gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀, nwọn mu u si ọdọ nwọn si tubọ sọ idi ọ̀na Ọlọrun fun u dajudaju.
26 And he began to speak boldly in the synagogue: whom when Aquila and Priscilla had heard, they took him unto them, and expounded unto him the way of God more perfectly.
27 Nigbati o si nfẹ kọja lọ si Akaia, awọn arakunrin gba a ni iyanju, nwọn si kọwe si awọn ọmọ-ẹhin ki nwọn ki o gba a: nigbati o si de, o ràn awọn ti o gbagbọ́ nipa ore-ọfẹ lọwọ pupọ.
27 And when he was disposed to pass into Achaia, the brethren wrote, exhorting the disciples to receive him: who, when he was come, helped them much which had believed through grace:
28 Nitoriti o sọ asọye fun awọn Ju ni gbangba, o nfi i hàn ninu iwe-mimọ́ pe, Jesu ni Kristi.
28 For he mightily convinced the Jews, and that publickly, shewing by the scriptures that Jesus was Christ.