Acts 16 - Listen Online
Read Acts 16
1 O si wá si Derbe on Listra: si kiyesi i, ọmọ-ẹhin kan wà nibẹ̀, ti a npè ni Timotiu, ọmọ obinrin kan ti iṣe Ju, ti o gbagbọ́; ṣugbọn Hellene ni baba rẹ̀:
1 Then came he to Derbe and Lystra: and, behold, a certain disciple was there, named Timotheus, the son of a certain woman, which was a Jewess, and believed; but his father was a Greek:
2 Ẹniti a rohin rẹ̀ rere lọdọ awọn arakunrin ti o wà ni Listra ati Ikonioni.
2 Which was well reported of by the brethren that were at Lystra and Iconium.
3 On ni Paulu fẹ ki o ba on lọ; o si mu u, o si kọ ọ ni ilà, nitori awọn Ju ti o wà li àgbegbe wọnni: nitori gbogbo wọn mọ̀ pe, Hellene ni baba rẹ̀.
3 Him would Paul have to go forth with him; and took and circumcised him because of the Jews which were in those quarters: for they knew all that his father was a Greek.
4 Bi nwọn si ti nlà awọn ilu lọ, nwọn nfi awọn aṣẹ ti a ti pinnu le wọn lọwọ lati mã pa wọn mọ, lati ọdọ awọn aposteli ati awọn àgbagbà wá ti o wà ni Jerusalemu.
4 And as they went through the cities, they delivered them the decrees for to keep, that were ordained of the apostles and elders which were at Jerusalem.
5 Bẹ̃ni awọn ijọ si fẹsẹmulẹ ni igbagbọ́, nwọn si npọ̀ si i ni iye lojojumọ.
5 And so were the churches established in the faith, and increased in number daily.
6 Nwọn si là ẹkùn Frigia já, ati Galatia, ti a ti ọdọ Ẹmí Mimọ́ kọ̀ fun wọn lati sọ ọ̀rọ na ni Asia.
6 Now when they had gone throughout Phrygia and the region of Galatia, and were forbidden of the Holy Ghost to preach the word in Asia,
7 Nigbati nwọn de ọkankan Misia, nwọn gbé e wò lati lọ si Bitinia: ṣugbọn Ẹmí Jesu kò gbà fun wọn.
7 After they were come to Mysia, they assayed to go into Bithynia: but the Spirit suffered them not.
8 Nigbati nwọn si kọja lẹba Misia, nwọn sọkalẹ lọ si Troasi.
8 And they passing by Mysia came down to Troas.
9 Iran kan si hàn si Paulu li oru: ọkunrin kan ara Makedonia duro, o si mbẹ̀ ẹ, wipe, Rekọja wá si Makedonia, ki o si ran wa lọwọ.
9 And a vision appeared to Paul in the night; There stood a man of Macedonia, and prayed him, saying, Come over into Macedonia, and help us.
10 Nigbati o si ti ri iran na, lọgán awa mura lati lọ si Makedonia, a si gbà pe, Oluwa ti pè wa lati wasu ihinrere fun wọn.
10 And after he had seen the vision, immediately we endeavored to go into Macedonia, assuredly gathering that the Lord had called us for to preach the gospel unto them.
11 Nitorina nigbati awa ṣikọ̀ ni Troasi a ba ọ̀na tàra lọ si Samotrakea, ni ijọ keji a si de Neapoli;
11 Therefore loosing from Troas, we came with a straight course to Samothracia, and the next day to Neapolis;
12 Lati ibẹ̀ awa si lọ si Filippi, ti iṣe ilu Makedonia, olu ilu ìha ibẹ, ilu labẹ Romani: awa si joko ni ilu yi fun ijọ melokan.
12 And from thence to Philippi, which is the chief city of that part of Macedonia, and a colony: and we were in that city abiding certain days.
13 Lọjọ isimi, awa si jade lọ si ẹhin odi ilu na, lẹba odò kan, nibiti a rò pe ibi adura wà; awa si joko, a si ba awọn obinrin ti o pejọ sọrọ.
13 And on the sabbath we went out of the city by a river side, where prayer was wont to be made; and we sat down, and spake unto the women which resorted thither.
14 Ati obinrin kan ti orukọ rẹ̀ ijẹ Lidia, elesè àluko, ara ilu Tiatira, ẹniti o nsìn Ọlọrun, o gbọ́ ọ̀rọ wa: ọkàn ẹniti Oluwa ṣí, fetísi ohun ti a ti ẹnu Paulu sọ.
14 And a certain woman named Lydia, a seller of purple, of the city of Thyatira, which worshipped God, heard us: whose heart the Lord opened, that she attended unto the things which were spoken of Paul.
15 Nigbati a si baptisi rẹ̀, ati awọn ará ile rẹ̀, o bẹ̀ wa, wipe, Bi ẹnyin ba kà mi li olõtọ si Oluwa, ẹ wá si ile mi, ki ẹ si wọ̀ nibẹ̀. O si rọ̀ wa.
15 And when she was baptized, and her household, she besought us, saying, If ye have judged me to be faithful to the Lord, come into my house, and abide there. And she constrained us.
16 O si ṣe, bi awa ti nlọ si ibi adura na, ọmọbinrin kan ti o li ẹmi afọṣẹ, pade wa, ẹniti o fi afọṣẹ mu ère pipọ fun awọn oluwa rẹ̀ wá:
16 And it came to pass, as we went to prayer, a certain damsel possessed with a spirit of divination met us, which brought her masters much gain by soothsaying:
17 On na li o ntọ̀ Paulu ati awa lẹhin, o si nkigbe, wipe, Awọn ọkunrin wọnyi ni iranṣẹ Ọlọrun Ọgá-ogo, ti nkede ọ̀na igbala fun nyin.
17 The same followed Paul and us, and cried, saying, These men are the servants of the most high God, which shew unto us the way of salvation.
18 O si nṣe eyi li ọjọ pipọ. Ṣugbọn nigbati inu Paulu bajẹ, ti o si yipada, o wi fun ẹmí na pe, Mo paṣẹ fun ọ li orukọ Jesu Kristi kí o jade kuro lara rẹ̀. O si jade ni wakati kanna.
18 And this did she many days. But Paul, being grieved, turned and said to the spirit, I command thee in the name of Jesus Christ to come out of her. And he came out the same hour.
19 Nigbati awọn oluwa rẹ̀ si ri pe, igbẹkẹle ère wọn pin, nwọn mu Paulu on Sila, nwọn si wọ́ wọn lọ si ọjà tọ̀ awọn ijoye lọ;
19 And when her masters saw that the hope of their gains was gone, they caught Paul and Silas, and drew them into the marketplace unto the rulers,
20 Nigbati nwọn si mu wọn tọ̀ awọn onidajọ lọ, nwọn wipe, Awọn ọkunrin wọnyi ti iṣe Ju, nwọn nyọ ilu wa lẹnu jọjọ;
20 And brought them to the magistrates, saying, These men, being Jews, do exceedingly trouble our city,
21 Nwọn si nkọni li àṣa ti kò yẹ fun wa, awa ẹniti iṣe ara Romu, lati gbà, ati lati tẹle.
21 And teach customs, which are not lawful for us to receive, neither to observe, being Romans.
22 Ọpọ enia si jumọ dide si wọn: awọn olori si fà wọn li aṣọ ya, nwọn si paṣẹ pe, ki a fi ọgọ lù wọn.
22 And the multitude rose up together against them: and the magistrates rent off their clothes, and commanded to beat them.
23 Nigbati nwọn si lù wọn pupọ, nwọn sọ wọn sinu tubu, nwọn kìlọ fun onitubu ki o pa wọn mọ́ daradara:
23 And when they had laid many stripes upon them, they cast them into prison, charging the jailor to keep them safely:
24 Nigbati o gbọ́ irú ikilọ bẹ̃, o sọ wọn sinu tubu ti inu lọhun, o si kàn ãbà mọ wọn li ẹsẹ.
24 Who, having received such a charge, thrust them into the inner prison, and made their feet fast in the stocks.
25 Ṣugbọn larin ọganjọ Paulu on Sila ngbadura, nwọn si nkọrin iyìn si Ọlọrun: awọn ara tubu si ntẹti si wọn.
25 And at midnight Paul and Silas prayed, and sang praises unto God: and the prisoners heard them.
26 Lojiji iṣẹlẹ nla si ṣẹ̀, tobẹ̃ ti ipilẹ ile tubu mi titi: lọgan gbogbo ilẹkun si ṣí, ìde gbogbo wọn si tu silẹ.
26 And suddenly there was a great earthquake, so that the foundations of the prison were shaken: and immediately all the doors were opened, and every one's bands were loosed.
27 Nigbati onitubu si tají, ti o si ri pe, awọn ikẹkun tubu ti ṣí silẹ, o fà idà rẹ̀ yọ, o si fẹ pa ara rẹ̀, o ṣebi awọn ara tubu ti sá lọ.
27 And the keeper of the prison awaking out of his sleep, and seeing the prison doors open, he drew out his sword, and would have killed himself, supposing that the prisoners had been fled.
28 Ṣugbọn Paulu kọ kàrá, wipe, Máṣe pa ara rẹ lara: nitori gbogbo wa mbẹ nihinyi.
28 But Paul cried with a loud voice, saying, Do thyself no harm: for we are all here.
29 Nigbati o si bere iná, o bẹ́ sinu ile, o nwariri, o wolẹ niwaju Paulu on Sila.
29 Then he called for a light, and sprang in, and came trembling, and fell down before Paul and Silas,
30 O si mu wọn jade, o ni, Alàgba, kini ki emi ki o ṣe ki ng le là?
30 And brought them out, and said, Sirs, what must I do to be saved?
31 Nwọn si wi fun u pe, Gbà Jesu Kristi Oluwa gbọ́, a o si gbà ọ là, iwọ ati awọn ará ile rẹ pẹlu.
31 And they said, Believe on the Lord Jesus Christ, and thou shalt be saved, and thy house.
32 Nwọn si sọ ọ̀rọ Oluwa fun u, ati fun gbogbo awọn ará ile rẹ̀.
32 And they spake unto him the word of the Lord, and to all that were in his house.
33 O si mu wọn ni wakati na li oru, o wẹ̀ ọgbẹ wọn; a si baptisi rẹ̀, ati gbogbo awọn enia rẹ̀ lojukanna.
33 And he took them the same hour of the night, and washed their stripes; and was baptized, he and all his, straightway.
34 O si mu wọn wá si ile rẹ̀, o si gbé onjẹ kalẹ niwaju wọn, o si yọ̀ gidigidi pẹlu gbogbo awọn ará ile rẹ̀, nitori o gbà Ọlọrun gbọ.
34 And when he had brought them into his house, he set meat before them, and rejoiced, believing in God with all his house.
35 Ṣugbọn nigbati ilẹ mọ́, awọn onidajọ rán awọn ọlọpa pe, Da awọn enia wọnni silẹ.
35 And when it was day, the magistrates sent the serjeants, saying, Let those men go.
36 Onitubu si sọ ọrọ na fun Paulu, wipe, Awọn onidajọ ranṣẹ pe ki a dá nyin silẹ: njẹ nisisiyi ẹ jade ki ẹ si mã lọ li alafia.
36 And the keeper of the prison told this saying to Paul, The magistrates have sent to let you go: now therefore depart, and go in peace.
37 Ṣugbọn Paulu wi fun wọn pe, Nwọn lù wa ni gbangba, nwọn si sọ wa sinu tubu li aijẹbi, awa ẹniti iṣe ara Romu: nisisiyi nwọn si fẹ ti wa jade nikọ̀kọ? agbẹdọ; ṣugbọn ki awọn tikarawọn wá mu wa jade.
37 But Paul said unto them, They have beaten us openly uncondemned, being Romans, and have cast us into prison; and now do they thrust us out privily? nay verily; but let them come themselves and fetch us out.
38 Awọn ọlọpa si sọ ọrọ wọnyi fun awọn onidajọ: ẹ̀ru si bà wọn, nigbati nwọn gbọ́ pe ara Romu ni nwọn.
38 And the serjeants told these words unto the magistrates: and they feared, when they heard that they were Romans.
39 Nwọn si wá, nwọn ṣìpẹ fun wọn, nwọn si mu wọn jade, nwọn si bẹ̀ wọn pe, ki nwọn ki o jade kuro ni ilu na.
39 And they came and besought them, and brought them out, and desired them to depart out of the city.
40 Nwọn si jade ninu tubu, nwọn si wọ̀ ile Lidia lọ: nigbati nwọn si ti ri awọn arakunrin, nwọn tù wọn ninu, nwọn si jade kuro.
40 And they went out of the prison, and entered into the house of Lydia and when they had seen the brethren, they comforted them, and departed.