Skip to content

Yoruba Bible

Orin Dafidi 133

Ìrẹ́pọ̀ Àwọn ará

1 KIYESI i, o ti dara o si ti dùn to fun awọn ará lati ma jumọ gbe ni irẹpọ̀.

2 O dabi ororo ikunra iyebiye li ori, ti o ṣàn de irungbọn, ani irungbọn Aaroni: ti o si ṣàn si eti aṣọ rẹ̀;

3 Bi ìri Hermoni ti o ṣàn sori òke Sioni: nitori nibẹ ni Oluwa gbe paṣẹ ibukún, ani ìye lailai.

Open Bible reader