Skip to content

Yoruba Bible

Orin Dafidi 129

Kí ojú ti ọ̀tá

1 IGBA pupọ̀ ni nwọn ti npọ́n mi loju lati igba-ewe mi wá, ni ki Israeli ki o wi nisisiyi.

2 Igba pupọ̀ ni nwọn ti npọ́n mi loju lati igba-ewe mi wá: sibẹ nwọn kò ti ibori mi.

3 Awọn awalẹ̀ walẹ si ẹhin mi: nwọn si la aporo wọn gigun.

4 Olododo li Oluwa: o ti ke okùn awọn enia buburu kuro.

5 Ki gbogbo awọn ti o korira Sioni ki o dãmu, ki nwọn ki o si yi ẹhin pada.

6 Ki nwọn ki o dabi koriko ori-ile ti o gbẹ danu, ki o to dagba soke:

7 Eyi ti oloko pipa kò kún ọwọ rẹ̀; bẹ̃li ẹniti ndi ití, kò kún apa rẹ̀.

8 Bẹ̃li awọn ti nkọja lọ kò wipe, Ibukún Oluwa ki o pẹlu nyin: awa sure fun nyin li orukọ Oluwa.

Open Bible reader