Skip to content

Yoruba Bible

Orin Dafidi 128

Ìbẹ̀rù OLUWA lérè

1 IBUKÚN ni fun gbogbo ẹniti o bẹ̀ru Oluwa; ti o si nrìn li ọ̀na rẹ̀.

2 Nitori ti iwọ o jẹ iṣẹ́ ọwọ rẹ: ibukún ni fun ọ: yio si dara fun ọ.

3 Obinrin rẹ yio dabi àjara rere eleso pupọ li arin ile rẹ: awọn ọmọ rẹ yio dabi igi olifi yi tabili rẹ ka.

4 Kiyesi i, pe bẹ̃li a o busi i fun ọkunrin na, ti o bẹ̀ru Oluwa.

5 Ki Oluwa ki o busi i fun ọ lati Sioni wá, ki iwọ ki o si ma ri ire Jerusalemu li ọjọ aiye rẹ gbogbo.

6 Bẹ̃ni ki iwọ ki o si ma ri ati ọmọ-de-ọmọ rẹ: ati alafia lara Israeli.

Open Bible reader