Skip to content

Yoruba Bible

Orin Dafidi 123

Adura Àánú

1 IWỌ ni mo gbé oju mi soke si, iwọ ti ngbe inu ọrun.

2 Kiyesi i, bi oju awọn iranṣẹkunrin ti ima wò ọwọ awọn baba wọn, ati bi oju iranṣẹ-birin ti ima wò ọwọ iya rẹ̀; bẹ̃li oju wa nwò Oluwa Ọlọrun wa, titi yio fi ṣãnu fun wa.

3 Oluwa, ṣãnu fun wa, ṣãnu fun wa: nitori ti a kún fun ẹ̀gan pupọ̀-pupọ̀.

4 Ọkàn wa kún pupọ̀-pupọ̀ fun ẹ̀gan awọn onirera, ati fun ẹ̀gan awọn agberaga.

Open Bible reader