Zechariah 3 - Listen Online
Read Zechariah 3
1 O sì fi Joṣua olori alufa hàn mi, o duro niwaju angeli Oluwa, Satani si duro lọwọ ọtun rẹ̀ lati kọju ijà si i.
1 And he shewed me Joshua the high priest standing before the angel of the LORD, and Satan standing at his right hand to resist him.
2 Oluwa si wi fun Satani pe, Oluwa ba ọ wi, iwọ Satani; ani Oluwa ti o ti yàn Jerusalemu, o ba ọ wi: igi iná kọ eyi ti a mu kuro ninu iná?
2 And the LORD said unto Satan, The LORD rebuke thee, O Satan; even the LORD that hath chosen Jerusalem rebuke thee: is not this a brand plucked out of the fire?
3 A si wọ̀ Joṣua li aṣọ ẽri, o si duro niwaju angeli na.
3 Now Joshua was clothed with filthy garments, and stood before the angel.
4 O si dahùn o wi fun awọn ti o duro niwaju rẹ̀ pe, Bọ aṣọ ẽri nì kuro li ara rẹ̀. O si wi fun u pe, Wò o, mo mu ki aiṣedẽde rẹ kuro lọdọ rẹ, emi o si wọ̀ ọ li aṣọ ẹyẹ.
4 And he answered and spake unto those that stood before him, saying, Take away the filthy garments from him. And unto him he said, Behold, I have caused thine iniquity to pass from thee, and I will clothe thee with change of raiment.
5 Mo si wipe, Jẹ ki wọn fi lawàni mimọ́ wé e li ori. Nwọn si fi lawàni mimọ́ wé e lori, nwọn si fi aṣọ wọ̀ ọ. Angeli Oluwa si duro tì i.
5 And I said, Let them set a fair mitre upon his head. So they set a fair mitre upon his head, and clothed him with garments. And the angel of the LORD stood by.
6 Angeli Oluwa si tẹnu mọ fun Joṣua pe,
6 And the angel of the LORD protested unto Joshua, saying,
7 Bayi ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; bi iwọ o ba rìn li ọ̀na mi, bi iwọ o ba si pa aṣẹ mi mọ, iwọ o si ṣe idajọ ile mi pẹlu, iwọ o si pa ãfin mi mọ pẹlu, emi o si fun ọ li àye ati rìn lãrin awọn ti o duro yi.
7 Thus saith the LORD of hosts; If thou wilt walk in my ways, and if thou wilt keep my charge, then thou shalt also judge my house, and shalt also keep my courts, and I will give thee places to walk among these that stand by.
8 Gbọ́ na, iwọ Joṣua olori alufa, iwọ, ati awọn ẹgbẹ́ rẹ ti o joko niwaju rẹ: nitori ẹni iyanu ni nwọn: nitori kiyesi i, emi o mu iranṣẹ mi, ẸKA, wá.
8 Hear now, O Joshua the high priest, thou, and thy fellows that sit before thee: for they are men wondered at: for, behold, I will bring forth my servant the BRANCH.
9 Nitori kiyesi i, okuta ti mo ti gbe kalẹ niwaju Joṣua; lori okuta kan ni oju meje o wà: kiyesi i, emi o fin finfin rẹ̀, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, emi o si mu aiṣedẽde ilẹ na kuro ni ijọ kan.
9 For behold the stone that I have laid before Joshua; upon one stone shall be seven eyes: behold, I will engrave the graving thereof, saith the LORD of hosts, and I will remove the iniquity of that land in one day.
10 Oluwa awọn ọmọ-ogun wipe, ni ọjọ na ni olukuluku yio pe ẹnikeji rẹ̀ sabẹ igi àjara ati sabẹ igi ọpọ̀tọ.
10 In that day, saith the LORD of hosts, shall ye call every man his neighbour under the vine and under the fig tree.