Nehemiah 12 - Listen Online
Read Nehemiah 12
1 WỌNYI si ni awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi ti o ba Serubbabeli ọmọ Ṣealtieli goke lọ, ati Jeṣua: Seraiah Jeremiah, Esra,
1 Now these are the priests and the Levites that went up with Zerubbabel the son of Shealtiel, and Jeshua: Seraiah, Jeremiah, Ezra,
2 Amariah, Malluki, Hattuṣi,
2 Amariah, Malluch, Hattush,
3 Ṣekaniah, Rehumu, Meremoti,
3 Shechaniah, Rehum, Meremoth,
4 Iddo, Ginneto, Abijah,
4 Iddo, Ginnetho, Abijah,
5 Miamini, Maadiah, Bilga,
5 Miamin, Maadiah, Bilgah,
6 Ṣemaiah, ati Joiaribu, Jodaiah,
6 Shemaiah, and Joiarib, Jediah,
7 Sallu, Amoku, Hilkiah, Jedaiah. Wọnyi li olori awọn alufa, ati ti awọn arakunrin wọn li ọjọ Jeṣua.
7 Sallu, Amok, Hilkiah, Jedaiah. These were the chief of the priests and of their brethren in the days of Jeshua.
8 Ati awọn ọmọ Lefi: Jeṣua, Binnui, Kadmieli, Ṣerebiah, Juda, ati Mattaniah, ti o wà lori orin idupẹ, on ati awọn arakunrin rẹ̀.
8 Moreover the Levites: Jeshua, Binnui, Kadmiel, Sherebiah, Judah, and Mattaniah, which was over the thanksgiving, he and his brethren.
9 Bakbukiah pẹlu ati Unni, awọn arakunrin wọn, li o kọju si wọn ninu iṣọ.
9 Also Bakbukiah and Unni, their brethren, were over against them in the watches.
10 Jeṣua si bi Joiakimu, Joiakimu si bi Eliaṣibu, Eliaṣibu si bi Joiada,
10 And Jeshua begat Joiakim, Joiakim also begat Eliashib, and Eliashib begat Joiada,
11 Joiada si bi Jonatani, Jonatani si bi Jaddua.
11 And Joiada begat Jonathan, and Jonathan begat Jaddua.
12 Ninu awọn alufa li ọjọ Joiakimu li awọn olori awọn baba wà: ti Seraiah, Meraiah; ti Jeremiah, Hananiah;
12 And in the days of Joiakim were priests, the chief of the fathers: of Seraiah, Meraiah; of Jeremiah, Hananiah;
13 Ti Esra, Meṣullamu; ti Amariah, Jehohanani;
13 Of Ezra, Meshullam; of Amariah, Jehohanan;
14 Ti Meliku, Jonatani; ti Ṣebaniah, Josefu;
14 Of Melicu, Jonathan; of Shebaniah, Joseph;
15 Ti Harimu, Adna; ti Meraioti, Helkai;
15 Of Harim, Adna; of Meraioth, Helkai;
16 Ti Iddo, Sekariah; ti Ginnetoni, Meṣullamu;
16 Of Iddo, Zechariah; of Ginnethon, Meshullam;
17 Ti Abijah, Sikri; ti Miniamini, ti Moadiah, Piltai:
17 Of Abijah, Zichri; of Miniamin, of Moadiah, Piltai;
18 Ti Bilga, Sammua; ti Ṣemaiah, Jehonatani;
18 Of Bilgah, Shammua; of Shemaiah, Jehonathan;
19 Ati ti Joaribu, Mattenai; ti Jedaiah, Ussi;
19 And of Joiarib, Mattenai; of Jedaiah, Uzzi;
20 Ti Sallai, Killai; ti Amoku, Eberi;
20 Of Sallai, Kallai; of Amok, Eber;
21 Ti Hilkiah, Haṣhabiah; ti Jedaiah, Netaneeli;
21 Of Hilkiah, Hashabiah; of Jedaiah, Nethaneel.
22 Ninu awọn ọmọ Lefi li ọjọ Eliaṣibu, Joiada, ati Johanani, ati Jaddua, awọn olori awọn baba: li a kọ sinu iwe pẹlu awọn alufa, titi di ijọba Dariusi ara Perṣia.
22 The Levites in the days of Eliashib, Joiada, and Johanan, and Jaddua, were recorded chief of the fathers: also the priests, to the reign of Darius the Persian.
23 Awọn ọmọ Lefi, olori awọn baba li a kọ sinu iwe itan titi di ọjọ Johanani ọmọ Eliaṣibu.
23 The sons of Levi, the chief of the fathers, were written in the book of the chronicles, even until the days of Johanan the son of Eliashib.
24 Awọn olori awọn ọmọ Lefi si ni Haṣabiah, Ṣerebiah, ati Jeṣua ọmọ Kadmieli, pẹlu awọn arakunrin wọn kọju si ara wọn, lati yìn ati lati dupẹ, gẹgẹ bi aṣẹ Dafidi enia Ọlọrun, li ẹgbẹgbẹ ẹṣọ.
24 And the chief of the Levites: Hashabiah, Sherebiah, and Jeshua the son of Kadmiel, with their brethren over against them, to praise and to give thanks, according to the commandment of David the man of God, ward over against ward.
25 Mattaniah, ati Bakbukiah, Obadiah, Meṣullamu, Talmoni, Akkubu, jẹ adèna lati ma ṣọ ìloro ẹnu-ọ̀na.
25 Mattaniah, and Bakbukiah, Obadiah, Meshullam, Talmon, Akkub, were porters keeping the ward at the thresholds of the gates.
26 Wọnyi wà li ọjọ Joiakimu, ọmọ Jeṣua, ọmọ Josadaki, ati li ọjọ Nehemiah bãlẹ, ati Esra alufa, ti iṣe akọwe.
26 These were in the days of Joiakim the son of Jeshua, the son of Jozadak, and in the days of Nehemiah the governor, and of Ezra the priest, the scribe.
27 Ati nigba yiya odi Jerusalemu si mimọ́, nwọn wá awọn ọmọ Lefi kiri ninu gbogbo ibugbe wọn, lati mu wọn wá si Jerusalemu lati fi ayọ̀ ṣe iyà si mimọ́ na pẹlu idupẹ ati orin, pẹlu simbali, psalteri, ati pẹlu dùru.
27 And at the dedication of the wall of Jerusalem they sought the Levites out of all their places, to bring them to Jerusalem, to keep the dedication with gladness, both with thanksgivings, and with singing, with cymbals, psalteries, and with harps.
28 Awọn ọmọ awọn akọrin si ko ara wọn jọ lati pẹ̀tẹlẹ yi Jerusalemu ka, ati lati ileto Netofati wá;
28 And the sons of the singers gathered themselves together, both out of the plain country round about Jerusalem, and from the villages of Netophathi;
29 Lati ile Gilgali wá pẹlu, ati lati inu ilẹ Geba ati Asmafeti, nitori awọn akọrin ti kọ ileto fun ara wọn yi Jerusalemu kakiri.
29 Also from the house of Gilgal, and out of the fields of Geba and Azmaveth: for the singers had builded them villages round about Jerusalem.
30 Ati awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi wẹ̀ ara wọn mọ́, nwọn si wẹ̀ awọn enia mọ́, ati ẹnu-bode, ati odi.
30 And the priests and the Levites purified themselves, and purified the people, and the gates, and the wall.
31 Nigbana ni mo mu awọn ijoye Juda wá si ori odi, mo si yàn ẹgbẹ nla meji, ninu awọn ti ndupẹ, ẹgbẹ kan lọ si apa ọtun li ori odi, siha ẹnu-bode àtan.
31 Then I brought up the princes of Judah upon the wall, and appointed two great companies of them that gave thanks, whereof one went on the right hand upon the wall toward the dung gate:
32 Hoṣaiah si lọ tẹle wọn ati idaji awọn ijoye Juda.
32 And after them went Hoshaiah, and half of the princes of Judah,
33 Ati Asariah, Esra, ati Meṣullamu,
33 And Azariah, Ezra, and Meshullam,
34 Juda, ati Benjamini, ati Ṣemaiah ati Jeremiah.
34 Judah, and Benjamin, and Shemaiah, and Jeremiah,
35 Ati ninu awọn ọmọ awọn alufa mu fère lọwọ, Sekariah, ọmọ Jonatani, ọmọ Ṣemaiah, ọmọ Mattaniah, ọmọ Mikaiah, ọmọ Sakkuri, ọmọ Asafu:
35 And certain of the priests' sons with trumpets; namely, Zechariah the son of Jonathan, the son of Shemaiah, the son of Mattaniah, the son of Michaiah, the son of Zaccur, the son of Asaph:
36 Ati awọn arakunrin rẹ̀, Ṣemaiah, ati Asaraeli, Milalai, Gilalai, Maai, Netaneeli, ati Juda, Hanani, pẹlu ohun èlo orin Dafidi, enia Ọlọrun, ati Esra akọwe niwaju wọn.
36 And his brethren, Shemaiah, and Azarael, Milalai, Gilalai, Maai, Nethaneel, and Judah, Hanani, with the musical instruments of David the man of God, and Ezra the scribe before them.
37 Ati ni ẹnu-bode orisun eyi ni ibi ti o kọju si i, nwọn ba àtẹgun ilu Dafidi goke lọ, ni ibi odi ti o goke lọ, ni ikọja ile Dafidi, titi de ẹnu-bode omi, niha ila õrùn.
37 And at the fountain gate, which was over against them, they went up by the stairs of the city of David, at the going up of the wall, above the house of David, even unto the water gate eastward.
38 Ati ẹgbẹ keji awọn ti ndupẹ, lọ li odi keji si wọn, ati emi lẹhin wọn, pẹlu idaji awọn enia lori odi, lati ikọja ile iṣọ ileru, titi de odi gbigboro.
38 And the other company of them that gave thanks went over against them, and I after them, and the half of the people upon the wall, from beyond the tower of the furnaces even unto the broad wall;
39 Nwọn si rekọja oke ẹnu-bode Efraimu wá, ati lati oke ẹnu-bode lailai ati li oke ẹnu-bode ẹja, ati ile-iṣọ Hananieli, ati ile-iṣọ Mea, titi de ẹnu-bode agutan, nwọn si duro li ẹnu-bode tubu.
39 And from above the gate of Ephraim, and above the old gate, and above the fish gate, and the tower of Hananeel, and the tower of Meah, even unto the sheep gate: and they stood still in the prison gate.
40 Bayi ni awọn ẹgbẹ meji ti ndupẹ ninu ile Ọlọrun duro, ati emi ati idaji awọn ijoye pẹlu mi.
40 So stood the two companies of them that gave thanks in the house of God, and I, and the half of the rulers with me:
41 Ati awọn alufa: Eliakimu, Maaseiah, Miniamini Mikaiah, Elioenai, Sekariah, Hananiah mu fère lọwọ;
41 And the priests; Eliakim, Maaseiah, Miniamin, Michaiah, Elioenai, Zechariah, and Hananiah, with trumpets;
42 Ati Maaseiah, ati Ṣemaiah, ati Eleasari, ati Ussi, ati Jehohanani, ati Malkijah, ati Elamu, ati Eseri, awọn akọrin kọrin soke, pẹlu Jesrahiah alabojuto.
42 And Maaseiah, and Shemaiah, and Eleazar, and Uzzi, and Jehohanan, and Malchijah, and Elam, and Ezer. And the singers sang loud, with Jezrahiah their overseer.
43 Li ọjọ na pẹlu nwọn ṣe irubọ nla, nwọn si yọ̀ nitori Ọlọrun ti mu wọn yọ̀ ayọ̀ nla, aya wọn ati awọn ọmọde yọ̀ pẹlu, tobẹ̃ ti a si gbọ́ ayọ̀ Jerusalemu li okere reré.
43 Also that day they offered great sacrifices, and rejoiced: for God had made them rejoice with great joy: the wives also and the children rejoiced: so that the joy of Jerusalem was heard even afar off.
44 Li akoko na li a si yàn awọn kan ṣe olori yara iṣura, fun ọrẹ-ẹbọ, fun akọso, ati fun idamẹwa, lati ma ko ipin ti a yàn jọ lati oko ilu wọnni wá, ti ofin fun awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi: nitoriti Juda yọ̀ fun awọn ọmọ Lefi ti o duro.
44 And at that time were some appointed over the chambers for the treasures, for the offerings, for the firstfruits, and for the tithes, to gather into them out of the fields of the cities the portions of the law for the priests and Levites: for Judah rejoiced for the priests and for the Levites that waited.
45 Ati awọn akọrin, ati adèna npa ẹṣọ Ọlọrun wọn mọ, ati ẹṣọ iwẹnumọ́, gẹgẹ bi aṣẹ Dafidi; ati ti Solomoni ọmọ rẹ̀.
45 And both the singers and the porters kept the ward of their God, and the ward of the purification, according to the commandment of David, and of Solomon his son.
46 Nitori li ọjọ Dafidi ati Asafu nigbani awọn olori awọn akọrin wà, ati orin iyìn, ati ọpẹ fun Ọlọrun.
46 For in the days of David and Asaph of old there were chief of the singers, and songs of praise and thanksgiving unto God.
47 Gbogbo Israeli li ọjọ Serubbabeli, ati li ọjọ Nehemiah si fi ipin awọn akọrin, ati ti awọn adèna fun wọn olukuluku ni ipin tirẹ̀ li ojojumọ, nwọn si ya ohun mimọ́ awọn ọmọ Lefi si ọ̀tọ, awọn ọmọ Lefi si yà wọn si ọ̀tọ fun awọn ọmọ Aaroni.
47 And all Israel in the days of Zerubbabel, and in the days of Nehemiah, gave the portions of the singers and the porters, every day his portion: and they sanctified holy things unto the Levites; and the Levites sanctified them unto the children of Aaron.