Leviticus 25 - Listen Online
Read Leviticus 25
1 OLUWA si sọ fun Mose li òke Sinai pe,
1 And the LORD spake unto Moses in mount Sinai, saying,
2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba dé ilẹ ti mo fi fun nyin, nigbana ni ki ilẹ na ki o pa isimi kan mọ́ fun OLUWA.
2 Speak unto the children of Israel, and say unto them, When ye come into the land which I give you, then shall the land keep a sabbath unto the LORD.
3 Ọdún mẹfa ni iwọ o fi gbìn oko rẹ, ọdún mẹfa ni iwọ o si fi rẹwọ ọgbà-ajara rẹ, ti iwọ o si kó eso rẹ̀ jọ;
3 Six years thou shalt sow thy field, and six years thou shalt prune thy vineyard, and gather in the fruit thereof;
4 Ṣugbọn ọdún keje ki o si jasi ìgba isimi fun ilẹ na, isimi fun OLUWA: iwọ kò gbọdọ gbìn oko rẹ, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ rẹwọ ọgbà-àjara rẹ.
4 But in the seventh year shall be a sabbath of rest unto the land, a sabbath for the LORD: thou shalt neither sow thy field, nor prune thy vineyard.
5 Eyiti o ba lalẹ̀ hù ninu ikore rẹ iwọ kò gbọdọ ká, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ká eso àjara rẹ ti iwọ kò rẹ́ lọwọ: nitoripe ọdún isimi ni fun ilẹ na.
5 That which groweth of its own accord of thy harvest thou shalt not reap, neither gather the grapes of thy vine undressed: for it is a year of rest unto the land.
6 Ọdún isimi ilẹ na yio si ma ṣe ohunjijẹ fun nyin; fun iwọ, ati fun iranṣẹ rẹ ọkunrin, ati fun iranṣẹ rẹ obinrin, ati fun alagbaṣe rẹ, ati fun alejò rẹ ti nṣe atipo lọdọ rẹ;
6 And the sabbath of the land shall be meat for you; for thee, and for thy servant, and for thy maid, and for thy hired servant, and for thy stranger that sojourneth with thee,
7 Ati fun ohunọ̀sin rẹ, ati fun ẹran ti mbẹ ni ilẹ rẹ, ni ki ibisi rẹ̀ gbogbo ki o ṣe onjẹ fun.
7 And for thy cattle, and for the beast that are in thy land, shall all the increase thereof be meat.
8 Ki iwọ ki o si kà ọdún isimi meje fun ara rẹ, ọdún meje ìgba meje; ati akokò ọdún isimi meje ni yio jẹ́ ọdún mọkandilãdọta fun ọ.
8 And thou shalt number seven sabbaths of years unto thee, seven times seven years; and the space of the seven sabbaths of years shall be unto thee forty and nine years.
9 Ki iwọ ki o si mu ki ipè ki o dún ni ijọ́ kẹwa oṣù keje, li ọjọ́ ètutu ni ki ẹnyin ki o mu ipè na dún ni gbogbo ilẹ nyin.
9 Then shalt thou cause the trumpet of the jubile to sound on the tenth day of the seventh month, in the day of atonement shall ye make the trumpet sound throughout all your land.
10 Ki ẹnyin ki o si yà arãdọta ọdún simimọ́, ki ẹnyin ki o si kede idasilẹ ni ilẹ na fun gbogbo awọn ti ngbé inu rẹ̀: yio si ma jẹ́ jubeli fun nyin; ki ẹnyin ki o si pada olukuluku si ilẹ-iní rẹ̀, ki olukuluku nyin ki o si pada sinu idile rẹ̀.
10 And ye shall hallow the fiftieth year, and proclaim liberty throughout all the land unto all the inhabitants thereof: it shall be a jubile unto you; and ye shall return every man unto his possession, and ye shall return every man unto his family.
11 Ọdún jubeli ni ki arãdọta ọdún ki o jasi fun nyin: ẹnyin kò gbọdọ gbìn, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ká ilalẹ-hù inu rẹ̀, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ká eso àjara rẹ̀ ti a kò rẹ-lọwọ.
11 A jubile shall that fiftieth year be unto you: ye shall not sow, neither reap that which groweth of itself in it, nor gather the grapes in it of thy vine undressed.
12 Nitoripe jubeli ni; mimọ́ ni ki o jasi fun nyin: ibisi rẹ̀ ni ki ẹnyin o ma jẹ lati inu oko wa.
12 For it is the jubile; it shall be holy unto you: ye shall eat the increase thereof out of the field.
13 Li ọdún jubeli yi ni ki olukuluku nyin ki o pada lọ si ilẹ-iní rẹ̀.
13 In the year of this jubile ye shall return every man unto his possession.
14 Bi iwọ ba si tà ọjà fun ẹnikeji rẹ, tabi bi iwọ ba rà lọwọ ẹnikeji rẹ, ẹnyin kò gbọdọ rẹ ara nyin jẹ:
14 And if thou sell ought unto thy neighbour, or buyest ought of thy neighbour's hand, ye shall not oppress one another:
15 Gẹgẹ bi iye ọdún lẹhin jubeli ni ki iwọ ki o rà lọwọ ẹnikeji rẹ, ati gẹgẹ bi iye ọdún ikore rẹ̀ ni ki o tà fun ọ.
15 According to the number of years after the jubile thou shalt buy of thy neighbour, and according unto the number of years of the fruits he shall sell unto thee:
16 Gẹgẹ bi ọ̀pọ ọdún ni ki iwọ ki o bù owo rẹ̀ sí i, ati gẹgẹ bi ọdún rẹ̀ ti fàsẹhin, ni ki iwọ ki o si bù owo rẹ̀ kù; nitoripe gẹgẹ bi iye ọdún ikore ni ki o tà fun ọ.
16 According to the multitude of years thou shalt increase the price thereof, and according to the fewness of years thou shalt diminish the price of it: for according to the number of the years of the fruits doth he sell unto thee.
17 Nitorina ẹnyin kò gbọdọ rẹ ara nyin jẹ; bikoṣe pe ki iwọ ki o bẹ̀ru Ọlọrun rẹ: nitoripe Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.
17 Ye shall not therefore oppress one another; but thou shalt fear thy God: for I am the LORD your God.
18 Nitorina ki ẹnyin ki o ma ṣe ìlana mi, ki ẹ si ma pa ofin mi mọ́, ki ẹ si ma ṣe wọn; ẹnyin o si ma gbé ilẹ na li ailewu.
18 Wherefore ye shall do my statutes, and keep my judgments, and do them; and ye shall dwell in the land in safety.
19 Ilẹ na yio si ma mú ibisi rẹ̀ wá, ẹ o si ma jẹ ajẹyo, ẹ o si ma gbé inu rẹ̀ li ailewu.
19 And the land shall yield her fruit, and he shall eat your fill, and dwell therein in safety.
20 Bi ẹnyin ba si wipe, Kili awa o ha ma jẹ li ọdún keje? sa wo o, awa kò gbọdọ gbìn, bẹ̃li awa kò gbọdọ kó ire wa:
20 And if ye shall say, What shall we eat the seventh year? behold, we shall not sow, nor gather in our increase:
21 Nigbana li emi o fi aṣẹ ibukún mi fun nyin li ọdún kẹfa, on o si so eso jade fun nyin fun ọdún mẹta.
21 Then I will command my blessing upon you in the sixth year, and it shall bring forth fruit for three years.
22 Ẹnyin o si gbìn li ọdún kẹjọ, ẹnyin o si ma jẹ ninu eso lailai titi di ọdún kẹsan, titi eso rẹ̀ yio fi dé ni ẹnyin o ma jẹ ohun isigbẹ.
22 And ye shall sow the eighth year, and eat yet of old fruit until the ninth year; until her fruits come in ye shall eat of the old store.
23 Ẹnyin kò gbọdọ tà ilẹ lailai; nitoripe ti emi ni ilẹ: nitoripe alejò ati atipo ni nyin lọdọ mi.
23 The land shall not be sold for ever: for the land is mine; for ye are strangers and sojourners with me.
24 Ati ni gbogbo ilẹ-iní nyin ki ẹnyin ki o si ma ṣe ìrapada fun ilẹ.
24 And in all the land of your possession ye shall grant a redemption for the land.
25 Bi arakunrin rẹ ba di talakà, ti o ba si tà ninu ilẹ-iní rẹ̀, bi ẹnikan ninu awọn ibatan rẹ̀ ba si wá lati rà a, njẹ ki o rà eyiti arakunrin rẹ̀ ti tà pada.
25 If thy brother be waxen poor, and hath sold away some of his possession, and if any of his kin come to redeem it, then shall he redeem that which his brother sold.
26 Bi ọkunrin na kò ba ní ẹnikan ti yio rà a pada, ti on tikara rẹ̀ ti di olowo ti o ní to lati rà a pada;
26 And if the man have none to redeem it, and himself be able to redeem it;
27 Nigbana ni ki o kà ọdún ìta rẹ̀, ki o si mú elé owo rẹ̀ pada fun ẹniti o tà a fun, ki on ki o le pada lọ si ilẹ-iní rẹ̀.
27 Then let him count the years of the sale thereof, and restore the overplus unto the man to whom he sold it; that he may return unto his possession.
28 Ṣugbọn bi o ba ṣepe on kò le san a pada fun u, njẹ ki ohun ti o tà na ki o gbé ọwọ́ ẹniti o rà a titi di ọdún jubeli: yio si bọ́ ni jubeli, on o si pada lọ si ilẹ-iní rẹ̀.
28 But if he be not able to restore it to him, then that which is sold shall remain in the hand of him that hath bought it until the year of jubile: and in the jubile it shall go out, and he shall return unto his possession.
29 Bi ọkunrin kan ba si tà ile gbigbé kan ni ilu olodi, njẹ ki o rà a pada ni ìwọn ọdún kan lẹhin ti o tà a; ni ìwọn ọdún kan ni ki o rà a pada.
29 And if a man sell a dwelling house in a walled city, then he may redeem it within a whole year after it is sold; within a full year may he redeem it.
30 Bi a kò ba si rà a ni ìwọn ọdún kan gbako, njẹ ki ile na ki o di ti ẹniti o rà a titilai ni iran-iran rẹ̀: ki yio bọ́ ni jubeli.
30 And if it be not redeemed within the space of a full year, then the house that is in the walled city shall be established for ever to him that bought it throughout his generations: it shall not go out in the jubile.
31 Ṣugbọn ile ileto wọnni ti kò ni odi yi wọn ká awọn li a kà si ibi oko ilu: ìrapada li awọn wọnni, nwọn o si bọ́ ni jubeli.
31 But the houses of the villages which have no wall round about them shall be counted as the fields of the country: they may be redeemed, and they shall go out in the jubile.
32 Ṣugbọn niti ilu awọn ọmọ Lefi, ile ilu iní wọn, ni awọn ọmọ Lefi o ma ràpada nigbakugba.
32 Notwithstanding the cities of the Levites, and the houses of the cities of their possession, may the Levites redeem at any time.
33 Bi ẹnikan ba si rà lọwọ awọn ọmọ Lefi, njẹ ile ti a tà na, ni ilu iní rẹ̀, ki o bọ́ ni jubeli: nitoripe ile ilu awọn ọmọ Lefi ni ilẹ-iní wọn lãrin awọn ọmọ Israeli.
33 And if a man purchase of the Levites, then the house that was sold, and the city of his possession, shall go out in the year of jubile: for the houses of the cities of the Levites are their possession among the children of Israel.
34 Ṣugbọn ilẹ ẹba ilu wọn ni nwọn kò gbọdọ tà; nitoripe ilẹ-iní wọn ni titi aiye.
34 But the field of the suburbs of their cities may not be sold; for it is their perpetual possession.
35 Ati bi arakunrin rẹ ba di talakà, ti ọwọ́ rẹ̀ ba si rẹlẹ lọdọ rẹ; njẹ ki iwọ ki o ràn a lọwọ; ibaṣe alejò, tabi atipo; ki on ki o le wà pẹlu rẹ.
35 And if thy brother be waxen poor, and fallen in decay with thee; then thou shalt relieve him: yea, though he be a stranger, or a sojourner; that he may live with thee.
36 Iwọ máṣe gbà elé lọwọ rẹ̀, tabi ẹdá; ṣugbọn bẹ̀ru Ọlọrun rẹ; ki arakunrin rẹ ki o le wà pẹlu rẹ.
36 Take thou no usury of him, or increase: but fear thy God; that thy brother may live with thee.
37 Iwọ kò gbọdọ fi owo rẹ fun u li ẹdá, tabi ki o wín i li onjẹ rẹ fun asanlé.
37 Thou shalt not give him thy money upon usury, nor lend him thy victuals for increase.
38 Emi li OLUWA Ọlọrun nyin, ti o mú nyin lati ilẹ Egipti jade wá, lati fi ilẹ Kenaani fun nyin, ati lati ma ṣe Ọlọrun nyin.
38 I am the LORD your God, which brought you forth out of the land of Egypt, to give you the land of Canaan, and to be your God.
39 Ati bi arakunrin rẹ ti mba ọ gbé ba di talakà, ti o si tà ara rẹ̀ fun ọ; iwọ kò gbọdọ sìn i ni ìsin-ẹrú:
39 And if thy brother that dwelleth by thee be waxen poor, and be sold unto thee; thou shalt not compel him to serve as a bondservant:
40 Bikoṣe bi alagbaṣe, ati bi atipo, ni ki o ma ba ọ gbé, ki o si ma sìn ọ titi di ọdún jubeli:
40 But as an hired servant, and as a sojourner, he shall be with thee, and shall serve thee unto the year of jubile:
41 Nigbana ni ki o lọ kuro lọdọ rẹ, ati on ati awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ki o si pada lọ si idile rẹ̀, ati si ilẹ-iní awọn baba rẹ̀ ni ki o pada si.
41 And then shall he depart from thee, both he and his children with him, and shall return unto his own family, and unto the possession of his fathers shall he return.
42 Nitoripe iranṣẹ mi ni nwọn iṣe, ti mo mú lati ilẹ Egipti jade wá: a kò gbọdọ tà wọn bi ẹni tà ẹrú.
42 For they are my servants, which I brought forth out of the land of Egypt: they shall not be sold as bondmen.
43 Iwọ kò gbọdọ fi irorò sìn i; ṣugbọn ki iwọ ki o bẹ̀ru Ọlọrun rẹ.
43 Thou shalt not rule over him with rigour; but shalt fear thy God.
44 Ati awọn ẹrú rẹ ọkunrin, ati awọn ẹrú rẹ obinrin, ti iwọ o ní; ki nwọn ki o jẹ́ ati inu awọn orilẹ-ède wá ti o yi nyin ká, ninu wọn ni ki ẹnyin ki o ma rà awọn ẹrú-ọkunrin ati awọn ẹrú-obinrin.
44 Both thy bondmen, and thy bondmaids, which thou shalt have, shall be of the heathen that are round about you; of them shall ye buy bondmen and bondmaids.
45 Pẹlupẹlu ninu awọn ọmọ alejò ti nṣe atipo pẹlu nyin, ninu wọn ni ki ẹnyin ki o rà, ati ninu awọn idile wọn ti mbẹ pẹlu nyin, ti nwọn bi ni ilẹ nyin: nwọn o si jẹ iní nyin.
45 Moreover of the children of the strangers that do sojourn among you, of them shall ye buy, and of their families that are with you, which they begat in your land: and they shall be your possession.
46 Ẹnyin o si ma fi wọn jẹ ogún fun awọn ọmọ nyin lẹhin nyin, lati ní wọn ni iní; ẹnyin o si ma sìn wọn lailai: ṣugbọn ninu awọn arakunrin nyin awọn ọmọ Israeli, ẹnikan kò gbọdọ fi irorò sìn ẹnikeji rẹ̀.
46 And ye shall take them as an inheritance for your children after you, to inherit them for a possession; they shall be your bondmen for ever: but over your brethren the children of Israel, ye shall not rule one over another with rigour.
47 Ati bi alejò tabi atipo kan ba di ọlọrọ̀ lọdọ rẹ, ati arakunrin rẹ kan leti ọdọ rẹ̀ ba di talakà, ti o ba si tà ara rẹ̀ fun alejò tabi atipo na leti ọdọ rẹ, tabi fun ibatan idile alejò na:
47 And if a sojourner or stranger wax rich by thee, and thy brother that dwelleth by him wax poor, and sell himself unto the stranger or sojourner by thee, or to the stock of the stranger's family:
48 Lẹhin igbati o tà ara rẹ̀ tán, a si tún le rà a pada; ọkan ninu awọn arakunrin rẹ̀ le rà a:
48 After that he is sold he may be redeemed again; one of his brethren may redeem him:
49 Ibaṣe arakunrin õbi rẹ̀, tabi ọmọ arakunrin õbi rẹ̀, le rà a, tabi ibatan rẹ̀ ninu idile rẹ̀ le rà a; tabi bi o ba di ọlọrọ̀, o le rà ara rẹ̀.
49 Either his uncle, or his uncle's son, may redeem him, or any that is nigh of kin unto him of his family may redeem him; or if he be able, he may redeem himself.
50 Ki o si ba ẹniti o rà a ṣìro lati ọdún ti o ti tà ara rẹ̀ fun u titi di ọdún jubeli: ki iye owo ìta rẹ̀ ki o si ri gẹgẹ bi iye ọdún, gẹgẹ bi ìgba alagbaṣe ni ki o ri fun u.
50 And he shall reckon with him that bought him from the year that he was sold to him unto the year of jubile: and the price of his sale shall be according unto the number of years, according to the time of an hired servant shall it be with him.
51 Bi ọdún rẹ̀ ba kù pupọ̀ sibẹ̀, gẹgẹ bi iye wọn ni ki o si san owo ìrasilẹ rẹ̀ pada ninu owo ti a fi rà a.
51 If there be yet many years behind, according unto them he shall give again the price of his redemption out of the money that he was bought for.
52 Bi o ba si ṣepe kìki ọdún diẹ li o kù titi di ọdún jubeli, njẹ ki o ba a ṣìro, gẹgẹ bi iye ọdún rẹ̀ ni ki o san owo ìrasilẹ rẹ̀ pada.
52 And if there remain but few years unto the year of jubile, then he shall count with him, and according unto his years shall he give him again the price of his redemption.
53 Bi alagbaṣe ọdọdún ni ki o ma ba a gbé: ki on ki o máṣe fi irorò sìn i li oju rẹ.
53 And as a yearly hired servant shall he be with him: and the other shall not rule with rigour over him in thy sight.
54 Bi a kò ba si fi wọnyi rà a silẹ, njẹ ki o jade lọ li ọdún jubeli, ati on, ati awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀.
54 And if he be not redeemed in these years, then he shall go out in the year of jubile, both he, and his children with him.
55 Nitoripe iranṣẹ mi li awọn ọmọ Israeli iṣe; iranṣẹ mi ni nwọn ti mo mú lati ilẹ Egipti jade wá: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.
55 For unto me the children of Israel are servants; they are my servants whom I brought forth out of the land of Egypt: I am the LORD your God.