Leviticus 13 - Listen Online
Read Leviticus 13
1 OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe,
1 And the LORD spake unto Moses and Aaron, saying,
2 Nigbati enia kan ba ní iwú, apá, tabi àmi didán kan li awọ ara rẹ̀, ti o si mbẹ li awọ ara rẹ̀ bi àrun ẹ̀tẹ; nigbana ni ki a mú u tọ̀ Aaroni alufa wá, tabi ọkan ninu awọn ọmọ rẹ̀, alufa:
2 When a man shall have in the skin of his flesh a rising, a scab, or a bright spot, and it be in the skin of his flesh like the plague of leprosy; then he shall be brought unto Aaron the priest, or unto one of his sons the priests:
3 Alufa yio si wò àrun ti mbẹ li awọ ara rẹ̀: bi irun ti mbẹ li oju àrun na ba si di funfun, ati ti àrun na li oju rẹ̀ ba jìn jù awọ ara rẹ̀ lọ, àrun ẹ̀tẹ ni: ki alufa ki o si wò o, ki o si pè e li alaimọ́.
3 And the priest shall look on the plague in the skin of the flesh: and when the hair in the plague is turned white, and the plague in sight be deeper than the skin of his flesh, it is a plague of leprosy: and the priest shall look on him, and pronounce him unclean.
4 Bi àmi didán na ba funfun li awọ ara rẹ̀, ati li oju rẹ̀ ti kò si jìn jù awọ lọ, ti irun rẹ̀ kò di funfun, nigbana ni ki alufa ki o sé alarun na mọ́ ni ijọ́ meje:
4 If the bright spot be white in the skin of his flesh, and in sight be not deeper than the skin, and the hair thereof be not turned white; then the priest shall shut up him that hath the plague seven days:
5 Ki alufa ki o si wò o ni ijọ́ keje: si kiyesi i, bi àrun na ba duro li oju rẹ̀, ti àrun na kò ba si ràn li ara rẹ̀, nigbana ni ki alufa ki o sé e mọ́ ni ijọ́ meje si i:
5 And the priest shall look on him the seventh day: and, behold, if the plague in his sight be at a stay, and the plague spread not in the skin; then the priest shall shut him up seven days more:
6 Ki alufa ki o si tun wò o ni ijọ́ keje: si kiyesi i, bi àrun na ba ṣe bi ẹni wodú, ti àrun na kò si ràn si i li awọ ara, ki alufa ki o pè e ni mimọ́: kìki apá ni: ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o jẹ́ mimọ́.
6 And the priest shall look on him again the seventh day: and, behold, if the plague be somewhat dark, and the plague spread not in the skin, the priest shall pronounce him clean: it is but a scab: and he shall wash his clothes, and be clean.
7 Ṣugbọn bi apá na ba ràn pupọ̀ si i li awọ ara, lẹhin igbati alufa ti ri i tán fun mimọ́ rẹ̀, alufa yio si tun wò o.
7 But if the scab spread much abroad in the skin, after that he hath been seen of the priest for his cleansing, he shall be seen of the priest again:
8 Alufa yio wò o, kiyesi i, apá na ràn li awọ ara rẹ̀, nigbana ni ki alufa ki o pè e li alaimọ́: ẹ̀tẹ ni.
8 And if the priest see that, behold, the scab spreadeth in the skin, then the priest shall pronounce him unclean: it is a leprosy.
9 Nigbati àrun ẹ̀tẹ ba mbẹ li ara enia, nigbana ni ki a mú u tọ̀ alufa wá;
9 When the plague of leprosy is in a man, then he shall be brought unto the priest;
10 Ki alufa ki o si wò o, si kiyesi i, bi iwú na ba funfun li awọ ara rẹ̀, ti o si sọ irun rẹ̀ di funfun, ti õju si mbẹ ninu iwú na,
10 And the priest shall see him: and, behold, if the rising be white in the skin, and it have turned the hair white, and there be quick raw flesh in the rising;
11 Ẹ̀tẹ lailai ni li awọ ara rẹ̀, ki alufa ki o pè e li alaimọ́: ki o máṣe sé e mọ́; nitoripe alaimọ́ ni.
11 It is an old leprosy in the skin of his flesh, and the priest shall pronounce him unclean, and shall not shut him up: for he is unclean.
12 Bi ẹ̀tẹ ba si sọ jade kakiri li awọ ara, ti ẹ̀tẹ na ba si bò gbogbo ara ẹniti o ní àrun na, lati ori rẹ̀ titi dé ẹsẹ̀ rẹ̀, nibikibi ti alufa ba wò;
12 And if a leprosy break out abroad in the skin, and the leprosy cover all the skin of him that hath the plague from his head even to his foot, wheresoever the priest looketh;
13 Nigbana ni ki alufa ki o wò o: si kiyesi i, bi ẹ̀tẹ na ba bò gbogbo ara rẹ̀, ki o pè àlarun na ni mimọ́; gbogbo rẹ̀ di funfun: mimọ́ li on.
13 Then the priest shall consider: and, behold, if the leprosy have covered all his flesh, he shall pronounce him clean that hath the plague: it is all turned white: he is clean.
14 Ṣugbọn ni ijọ́ ti õju na ba hàn ninu rẹ̀, ki o jẹ́ alaimọ́.
14 But when raw flesh appeareth in him, he shall be unclean.
15 Ki alufa ki o wò õju na, ki o si pè e li alaimọ́: nitoripe aimọ́ li õju: ẹ̀tẹ ni.
15 And the priest shall see the raw flesh, and pronounce him to be unclean: for the raw flesh is unclean: it is a leprosy.
16 Tabi bi õju na ba yipada, ti o si di funfun, ki o si tọ̀ alufa wá,
16 Or if the raw flesh turn again, and be changed unto white, he shall come unto the priest;
17 Alufa yio si wò o: si kiyesi i, bi àrun na ba di funfun, nigbana ni ki alufa ki o pè àlarun na ni mimọ́: mimọ́ li on.
17 And the priest shall see him: and, behold, if the plague be turned into white; then the priest shall pronounce him clean that hath the plague: he is clean.
18 Ara pẹlu, ninu eyi, ani li awọ ara ti õwo ti sọ, ti o si jiná,
18 The flesh also, in which, even in the skin thereof, was a boil, and is healed,
19 Ati ni apá õwo na bi iwú funfun ba mbẹ nibẹ̀, tabi àmi didán, funfun ti o si ṣe bi ẹni pọ́n ki a si fi i hàn alufa;
19 And in the place of the boil there be a white rising, or a bright spot, white, and somewhat reddish, and it be shewed to the priest;
20 Alufa yio wò o, si kiyesi i, li oju rẹ̀ bi o ba jìn jù awọ ara lọ, ti irun rẹ̀ si di funfun, ki alufa ki o pè e li alaimọ́: àrun ẹ̀tẹ li o sọ jade ninu õwo na.
20 And if, when the priest seeth it, behold, it be in sight lower than the skin, and the hair thereof be turned white; the priest shall pronounce him unclean: it is a plague of leprosy broken out of the boil.
21 Ṣugbọn bi alufa na ba wò o, si kiyesi i, ti irun funfun kò si sí ninu rẹ̀, bi kò ba si jìn jù awọ ara lọ, ti o si dabi ẹni wodú, nigbana ni ki alufa ki o sé e mọ́ ni ijọ́ meje:
21 But if the priest look on it, and, behold, there be no white hairs therein, and if it be not lower than the skin, but be somewhat dark; then the priest shall shut him up seven days:
22 Bi o ba si ràn siwaju li awọ ara rẹ̀, nigbana ni ki alufa ki o pè e ni alaimọ́: àrun ni.
22 And if it spread much abroad in the skin, then the priest shall pronounce him unclean: it is a plague.
23 Ṣugbọn bi àmi didán na ba duro ni ipò rẹ̀, ti kò si ràn, õwo tita ni; ki alufa ki o si pè e ni mimọ́.
23 But if the bright spot stay in his place, and spread not, it is a burning boil; and the priest shall pronounce him clean.
24 Tabi bi ara kan ba mbẹ, ninu awọ ara eyiti ijóni bi iná ba wà, ti ojú jijóna na ba ní àmi funfun didán, ti o ṣe bi ẹni pọn rusurusu tabi funfun;
24 Or if there be any flesh, in the skin whereof there is a hot burning, and the quick flesh that burneth have a white bright spot, somewhat reddish, or white;
25 Nigbana ni ki alufa ki o wò o: si kiyesi i, bi irun ninu àmi didán na ba di funfun, ti o ba si jìn jù awọ ara lọ li oju; ẹ̀tẹ li o ti inu ijóni nì sọ jade; nitorina ni ki alufa ki o pè e ni alaimọ́: àrun ẹ̀tẹ ni.
25 Then the priest shall look upon it: and, behold, if the hair in the bright spot be turned white, and it be in sight deeper than the skin; it is a leprosy broken out of the burning: wherefore the priest shall pronounce him unclean: it is the plague of leprosy.
26 Ṣugbọn bi alufa ba wò o, si kiyesi i, ti kò sí irun funfun li apá didán na, ti kò si jìn jù awọ ara iyokù lọ, ṣugbọn ti o ṣe bi ẹni ṣújú; nigbana ni ki alufa ki o sé e mọ́ ni ijọ́ meje:
26 But if the priest look on it, and, behold, there be no white hair in the bright spot, and it be no lower than the other skin, but be somewhat dark; then the priest shall shut him up seven days:
27 Ki alufa ki o si wò o ni ijọ́ keje: bi o ba si ràn siwaju li awọ ara rẹ̀, nigbana ni ki alufa ki o pè e li alaimọ́; àrun ẹ̀tẹ ni.
27 And the priest shall look upon him the seventh day: and if it be spread much abroad in the skin, then the priest shall pronounce him unclean: it is the plague of leprosy.
28 Bi àmi didán na ba si duro ni ipò rẹ̀, ti kò si ràn si i li awọ ara, ṣugbọn ti o dabi ẹni sújú: iwú ijóni ni, ki alufa ki o si pè e ni mimọ́: nitoripe ijóni tita ni.
28 And if the bright spot stay in his place, and spread not in the skin, but it be somewhat dark; it is a rising of the burning, and the priest shall pronounce him clean: for it is an inflammation of the burning.
29 Bi ọkunrin tabi obinrin kan ba ní àrun li ori rẹ̀ tabi li àgbọn,
29 If a man or woman have a plague upon the head or the beard;
30 Nigbana ni ki alufa ki o wò àrun na: si kiyesi i, bi o ba jìn jù awọ ara lọ li oju, bi irun tinrin pupa ba mbẹ ninu rẹ̀, nigbana ni ki alufa ki o pè e li aimọ́: ipẹ́ gbigbẹ ni, ani ẹ̀tẹ li ori tabi li àgbọn ni.
30 Then the priest shall see the plague: and, behold, if it be in sight deeper than the skin; and there be in it a yellow thin hair; then the priest shall pronounce him unclean: it is a dry scall, even a leprosy upon the head or beard.
31 Bi alufa ba si wò àrun pipa na, si kiyesi i, ti kò ba jìn jù awọ ara lọ li oju, ti kò si sí irun dudu ninu rẹ̀, nigbana ni ki alufa ki o sé àlarun pipa na mọ́ ni ijọ́ meje:
31 And if the priest look on the plague of the scall, and, behold, it be not in sight deeper than the skin, and that there is no black hair in it; then the priest shall shut up him that hath the plague of the scall seven days:
32 Ni ijọ́ keje ki alufa ki o si wò àrun na: si kiyesi i, bi pipa na kò ba ràn, ti kò si sí irun pupa ninu rẹ̀, ti pipa na kò si jìn jù awọ ara lọ li oju,
32 And in the seventh day the priest shall look on the plague: and, behold, if the scall spread not, and there be in it no yellow hair, and the scall be not in sight deeper than the skin;
33 Ki o fári, ṣugbọn ki o máṣe fá ibi pipa na; ki alufa ki o si sé ẹni pipa nì mọ́ ni ijọ́ meje si i:
33 He shall be shaven, but the scall shall he not shave; and the priest shall shut up him that hath the scall seven days more:
34 Ni ijọ́ keje ki alufa ki o si wò pipa na; si kiyesi i bi pipa na kò ba ràn si awọ ara, ti kò ba jìn jù awọ ara lọ li oju; nigbana ni ki alufa ki o pè e ni mimọ́: ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ mimọ́.
34 And in the seventh day the priest shall look on the scall: and, behold, if the scall be not spread in the skin, nor be in sight deeper than the skin; then the priest shall pronounce him clean: and he shall wash his clothes, and be clean.
35 Ṣugbọn bi pipa na ba ràn siwaju li awọ ara rẹ̀ lẹhin ìpenimimọ́ rẹ̀;
35 But if the scall spread much in the skin after his cleansing;
36 Nigbana ni ki alufa ki o wò o: si kiyesi i, bi pipa na ba ràn siwaju li awọ ara, ki alufa ki o máṣe wá irun pupa mọ́; alaimọ́ ni.
36 Then the priest shall look on him: and, behold, if the scall be spread in the skin, the priest shall not seek for yellow hair; he is unclean.
37 Ṣugbọn li oju rẹ̀ bi pipa na ba duro, ti irun dudu si hù ninu rẹ̀; pipa na jiná, mimọ́ li on: ki alufa ki o pè e ni mimọ́.
37 But if the scall be in his sight at a stay, and that there is black hair grown up therein; the scall is healed, he is clean: and the priest shall pronounce him clean.
38 Bi ọkunrin kan tabi obinrin kan ba ní àmi didán li awọ ara wọn, ani àmi funfun didán;
38 If a man also or a woman have in the skin of their flesh bright spots, even white bright spots;
39 Nigbana ni ki alufa ki o wò o: si kiyesi i, bi àmi didán li awọ ara wọn ba ṣe bi ẹni ṣe funfun ṣe dudu; ifinra li o sọ jade li ara; mimọ́ li on.
39 Then the priest shall look: and, behold, if the bright spots in the skin of their flesh be darkish white; it is a freckled spot that groweth in the skin; he is clean.
40 Ati ọkunrin ti irun rẹ̀ ba re kuro li ori rẹ̀, apari ni; ṣugbọn mimọ́ li on.
40 And the man whose hair is fallen off his head, he is bald; yet is he clean.
41 Ẹniti irun rẹ̀ ba re silẹ ni ìha iwaju rẹ̀, o pari ni iwaju; ṣugbọn mimọ́ li on.
41 And he that hath his hair fallen off from the part of his head toward his face, he is forehead bald: yet is he clean.
42 Bi õju funfun-pupa rusurusu ba mbẹ li ori pipa na, tabi iwaju ori pipa na; ẹ̀tẹ li o sọ jade ninu pipa ori na, tabi ni pipá iwaju na.
42 And if there be in the bald head, or bald forehead, a white reddish sore; it is a leprosy sprung up in his bald head, or his bald forehead.
43 Nigbana ni ki alufa ki o wò o: si kiyesi i, bi iwú õju na ba funfun-pupa rusurusu ni pipa ori rẹ̀, tabi pipa iwaju rẹ̀, bi ẹ̀tẹ ti ihàn li awọ ara;
43 Then the priest shall look upon it: and, behold, if the rising of the sore be white reddish in his bald head, or in his bald forehead, as the leprosy appeareth in the skin of the flesh;
44 Ẹlẹtẹ ni, alaimọ́ ni: ki alufa ki o pè e li aimọ́ patapata; àrun rẹ̀ mbẹ li ori rẹ̀.
44 He is a leprous man, he is unclean: the priest shall pronounce him utterly unclean; his plague is in his head.
45 Ati adẹ́tẹ na, li ara ẹniti àrun na gbé wà, ki o fà aṣọ rẹ̀ ya, ki o si fi ori rẹ̀ silẹ ni ìhoho, ki o si fi ìbo bò ète rẹ̀ òke, ki o si ma kepe, Alaimọ́, alaimọ́.
45 And the leper in whom the plague is, his clothes shall be rent, and his head bare, and he shall put a covering upon his upper lip, and shall cry, Unclean, unclean.
46 Ni gbogbo ọjọ́ ti àrun na mbẹ li ara rẹ̀ ni ki o jẹ́ elẽri; alaimọ́ ni: on nikan ni ki o ma gbé; lẹhin ibudó ni ibujoko rẹ̀ yio gbé wà.
46 All the days wherein the plague shall be in him he shall be defiled; he is unclean: he shall dwell alone; without the camp shall his habitation be.
47 Ati aṣọ ti àrun ẹ̀tẹ mbẹ ninu rẹ̀, iba ṣe aṣọ kubusu, tabi aṣọ ọ̀gbọ;
47 The garment also that the plague of leprosy is in, whether it be a woollen garment, or a linen garment;
48 Iba ṣe ni ita, tabi ni iwun; ti ọ̀gbọ, tabi ti kubusu; iba ṣe li awọ, tabi ohun kan ti a fi awọ ṣe;
48 Whether it be in the warp, or woof; of linen, or of woollen; whether in a skin, or in any thing made of skin;
49 Bi àrun na ba ṣe bi ọbẹdo tabi bi pupa lara aṣọ na, tabi lara awọ na, iba ṣe ni ita, tabi ni iwun, tabi ninu ohunèlo awọ kan; àrun ẹ̀tẹ ni, ki a si fi i hàn alufa:
49 And if the plague be greenish or reddish in the garment, or in the skin, either in the warp, or in the woof, or in any thing of skin; it is a plague of leprosy, and shall be shewed unto the priest:
50 Ki alufa ki o si wò àrun na, ki o si sé ohun ti o ní àrun na mọ́ ni ijọ́ meje:
50 And the priest shall look upon the plague, and shut up it that hath the plague seven days:
51 Ki o si wò àrun na ni ijọ́ keje: bi àrun na ba ràn sara aṣọ na, iba ṣe ni ita, tabi ni iwun, tabi ninu awọ, tabi ninu ohun ti a fi awọ ṣe; àrun oun ẹ̀tẹ kikẹ̀ ni; alaimọ́ ni.
51 And he shall look on the plague on the seventh day: if the plague be spread in the garment, either in the warp, or in the woof, or in a skin, or in any work that is made of skin; the plague is a fretting leprosy; it is unclean.
52 Nitorina ki o fi aṣọ na jóna, iba ṣe ita, tabi iwun, ni kubusu tabi li ọ̀gbọ, tabi ninu ohunèlo awọ kan, ninu eyiti àrun na gbé wà: nitoripe ẹ̀tẹ kikẹ̀ ni; ki a fi jóna.
52 He shall therefore burn that garment, whether warp or woof, in woollen or in linen, or any thing of skin, wherein the plague is: for it is a fretting leprosy; it shall be burnt in the fire.
53 Bi alufa ba si wò, si kiyesi i, ti àrun na kò ba tàn sara aṣọ na, iba ṣe ni ita, tabi ni iwun, tabi ninu ohunèlo kan ti a fi awọ ṣe;
53 And if the priest shall look, and, behold, the plague be not spread in the garment, either in the warp, or in the woof, or in any thing of skin;
54 Nigbana ni ki alufa ki o paṣẹ ki nwọn ki o fọ̀ ohun na ninu eyiti àrun na gbé wà, ki o si sé e mọ́ ni ijọ meje si i.
54 Then the priest shall command that they wash the thing wherein the plague is, and he shall shut it up seven days more:
55 Ki alufa ki o si wò àrun na, lẹhin igbati a fọ̀ ọ tán: si kiyesi i, bi àrun na kò ba pa awọ rẹ̀ dà, ti àrun na kò si ràn si i, alaimọ́ ni; ninu iná ni ki iwọ ki o sun u; o kẹ̀ ninu, iba gbo ninu tabi lode.
55 And the priest shall look on the plague, after that it is washed: and, behold, if the plague have not changed his colour, and the plague be not spread; it is unclean; thou shalt burn it in the fire; it is fret inward, whether it be bare within or without.
56 Bi alufa ba si wò, si kiyesi i, ti àrun na ba ṣe bi ẹni wodú lẹhin igbati o ba fọ̀ ọ tán; nigbana ni ki o fà a ya kuro ninu aṣọ na, tabi ninu awọ na, tabi ninu ita, tabi ninu iwun:
56 And if the priest look, and, behold, the plague be somewhat dark after the washing of it; then he shall rend it out of the garment, or out of the skin, or out of the warp, or out of the woof:
57 Bi o ba si hàn sibẹ̀ ninu aṣọ na, iba ṣe ni ita, tabi ni iwun, tabi ninu ohunèlo kan ti a fi awọ ṣe, àrun riràn ni: ki iwọ ki o fi iná sun ohun ti àrun na wà ninu rẹ̀.
57 And if it appear still in the garment, either in the warp, or in the woof, or in any thing of skin; it is a spreading plague: thou shalt burn that wherein the plague is with fire.
58 Ati aṣọ na, iba ṣe ni ita, tabi ni iwun, tabi ninu ohunkohun ti a fi awọ ṣe, ti iwọ ba fọ̀, bi àrun na ba wọ́n kuro ninu wọn nigbana ni ki a tun fọ̀ ọ lẹkeji, on o si jẹ́ mimọ́.
58 And the garment, either warp, or woof, or whatsoever thing of skin it be, which thou shalt wash, if the plague be departed from them, then it shall be washed the second time, and shall be clean.
59 Eyi li ofin àrun ẹ̀tẹ, ninu aṣọ, kubusu tabi ti ọ̀gbọ, iba ṣe ni ita, tabi ni iwun, tabi ohunkohun èlo awọ kan, lati pè e ni mimọ́, tabi lati pè e li aimọ́.
59 This is the law of the plague of leprosy in a garment of woollen or linen, either in the warp, or woof, or any thing of skins, to pronounce it clean, or to pronounce it unclean.