Judges 9 - Listen Online
Read Judges 9
1 ABIMELEKI ọmọ Jerubbaali si lọ si Ṣekemu sọdọ awọn arakunrin iya rẹ̀, o si bá wọn sọ̀rọ, ati gbogbo idile ile baba iya rẹ̀, wipe,
1 And Abimelech the son of Jerubbaal went to Shechem unto his mother's brethren, and communed with them, and with all the family of the house of his mother's father, saying,
2 Emi bẹ̀ nyin, ẹ sọ li etí gbogbo awọn ọkunrin Ṣekemu pe, Ẽwo li o rọ̀run fun nyin, ki gbogbo awọn ọmọ Jerubbaali, ãdọrin enia, ki o ṣe olori nyin, tabi ki ẹnikan ki o ṣe olori nyin? ki ẹnyin ki o ranti pẹlu pe, emi li egungun nyin, ati ẹran ara nyin.
2 Speak, I pray you, in the ears of all the men of Shechem, Whether is better for you, either that all the sons of Jerubbaal, which are threescore and ten persons, reign over you, or that one reign over you? remember also that I am your bone and your flesh.
3 Awọn arakunrin iya rẹ̀ si sọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi nitori rẹ̀ li etí gbogbo awọn ọkunrin Ṣekemu: àiya wọn si tẹ̀ si ti Abimeleki; nitori nwọn wipe, Arakunrin wa ni iṣe.
3 And his mother's brethren spake of him in the ears of all the men of Shechem all these words: and their hearts inclined to follow Abimelech; for they said, He is our brother.
4 Nwọn si fun u li ãdọrin owo fadakà lati inu ile Baali-beriti wá, Abimeleki si fi i bẹ̀ awọn enia lasan ati alainilari li ọ̀wẹ, nwọn si ntẹ̀le e.
4 And they gave him threescore and ten pieces of silver out of the house of Baal-berith, wherewith Abimelech hired vain and light persons, which followed him.
5 On si lọ si ile baba rẹ̀ ni Ofra, o si pa awọn arakunrin rẹ̀ awọn ọmọ Jerubbaali, ãdọrin enia, lori okuta kan: ṣugbọn o kù Jotamu abikẹhin ọmọ Jerubbaali; nitoriti o sapamọ́.
5 And he went unto his father's house at Ophrah, and slew his brethren the sons of Jerubbaal, being threescore and ten persons, upon one stone: notwithstanding yet Jotham the youngest son of Jerubbaal was left; for he hid himself.
6 Gbogbo awọn ọkunrin Ṣekemu si kó ara wọn jọ, ati gbogbo awọn ara ile Millo, nwọn lọ nwọn si fi Abimeleki jẹ́ ọba, ni ibi igi-oaku ile-ẹṣọ́ ti mbẹ ni Ṣekemu.
6 And all the men of Shechem gathered together, and all the house of Millo, and went, and made Abimelech king, by the plain of the pillar that was in Shechem.
7 Nigbati nwọn si sọ fun Jotamu, on si lọ o si duro lori òke Gerisimu, o si gbé ohùn rẹ̀ soke, o kigbe, o si wi fun wọn pe, Ẹ fetisi ti emi, ẹnyin ọkunrin Ṣekemu, ki Ọlọrun ki o le fetisi ti nyin.
7 And when they told it to Jotham, he went and stood in the top of mount Gerizim, and lifted up his voice, and cried, and said unto them, Hearken unto me, ye men of Shechem, that God may hearken unto you.
8 Awọn igi lọ li akokò kan ki nwọn ki o le fi ọba jẹ́ lori wọn; nwọn si wi fun igi olifi pe, Wá jọba lori wa.
8 The trees went forth on a time to anoint a king over them; and they said unto the olive tree, Reign thou over us.
9 Ṣugbọn igi olifi wi fun wọn pe, Emi ha le fi ọrá mi silẹ, nipa eyiti nwọn nfi mi bù ọlá fun Ọlọrun ati enia, ki emi ki o si wá ṣe olori igi?
9 But the olive tree said unto them, Should I leave my fatness, wherewith by me they honour God and man, and go to be promoted over the trees?
10 Awọn igi si wi fun igi ọpọtọ́ pe, Iwọ wá jọba lori wa.
10 And the trees said to the fig tree, Come thou, and reign over us.
11 Ṣugbọn igi ọpọtọ́ wi fun wọn pe, Emi le fi adùn mi silẹ, ati eso mi daradara, ki emi ki o si wá ṣe olori awọn igi?
11 But the fig tree said unto them, Should I forsake my sweetness, and my good fruit, and go to be promoted over the trees?
12 Awọn igi si wi fun àjara pe, Iwọ wá jọba lori wa.
12 Then said the trees unto the vine, Come thou, and reign over us.
13 Àjara si wi fun wọn pe, Ki emi ki o fi ọti-waini mi silẹ, eyiti nmu inu Ọlọrun ati enia dùn, ki emi ki o si wá ṣe olori awọn igi?
13 And the vine said unto them, Should I leave my wine, which cheereth God and man, and go to be promoted over the trees?
14 Nigbana ni gbogbo igi si wi fun igi-ẹgún pe, Iwọ wá jọba lori wa.
14 Then said all the trees unto the bramble, Come thou, and reign over us.
15 Igi-ẹgún si wi fun awọn igi pe, Bi o ba ṣepe nitõtọ li ẹnyin fi emi jẹ́ ọba lori nyin, njẹ ẹ wá sá si abẹ ojiji mi: bi kò ba si ṣe bẹ̃, jẹ ki iná ki o ti inu igi-ẹgún jade wá, ki o si jó awọn igi-kedari ti Lebanoni run.
15 And the bramble said unto the trees, If in truth ye anoint me king over you, then come and put your trust in my shadow: and if not, let fire come out of the bramble, and devour the cedars of Lebanon.
16 Njẹ nitorina, bi ẹnyin ba ṣe otitọ, ati eyiti o pé, ni ti ẹnyin fi Abimeleki jẹ ọba, ati bi ẹnyin ba si ṣe rere si Jerubbaali ati si ile rẹ̀, ti ẹnyin si ṣe si i gẹgẹ bi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀;
16 Now therefore, if ye have done truly and sincerely, in that ye have made Abimelech king, and if ye have dealt well with Jerubbaal and his house, and have done unto him according to the deserving of his hands;
17 (Nitoriti baba mi jà fun nyin, o si fi ẹmi rẹ̀ wewu, o si gbà nyin kuro li ọwọ Midiani:
17 (For my father fought for you, and adventured his life far, and delivered you out of the hand of Midian:
18 Ẹnyin si dide si ile baba mi li oni, ẹnyin si pa awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ãdọrin enia, lori okuta kan, ẹnyin si fi Abimeleki, ọmọ iranṣẹbinrin rẹ̀ jẹ́ ọba lori awọn Ṣekemu, nitoriti arakunrin nyin ni iṣe;)
18 And ye are risen up against my father's house this day, and have slain his sons, threescore and ten persons, upon one stone, and have made Abimelech, the son of his maidservant, king over the men of Shechem, because he is your brother;)
19 Njẹ bi ẹnyin ba ṣe otitọ, ati eyiti o pé si Jerubbaali ati si ile rẹ̀ li oni yi, njẹ ki ẹnyin ki o ma yọ̀ si Abimeleki, ki on pẹlu si ma yọ̀ si nyin:
19 If ye then have dealt truly and sincerely with Jerubbaal and with his house this day, then rejoice ye in Abimelech, and let him also rejoice in you:
20 Ṣugbọn bi kò ba si ri bẹ̃, jẹ ki iná ki o ti ọdọ Abimeleki jade wá, ki o si jó awọn ọkunrin Ṣekemu run, ati ile Millò: jẹ ki iná ki o si ti ọdọ awọn ọkunrin Ṣekemu ati ile Millo jade wá, ki o si jó Abimeleki run.
20 But if not, let fire come out from Abimelech, and devour the men of Shechem, and the house of Millo; and let fire come out from the men of Shechem, and from the house of Millo, and devour Abimelech.
21 Jotamu si ṣí, o sálọ, o si lọ si Beeri, o si joko sibẹ̀, nitori ìbẹru Abimeleki arakunrin rẹ̀.
21 And Jotham ran away, and fled, and went to Beer, and dwelt there, for fear of Abimelech his brother.
22 Abimeleki sí ṣe olori awọn ọmọ Israeli li ọdún mẹta.
22 When Abimelech had reigned three years over Israel,
23 Ọlọrun si rán ẹmi buburu sãrin Abimeleki ati awọn ọkunrin Ṣekemu; awọn ọkunrin Ṣekemu si fi arekereke bá Abimeleki lò:
23 Then God sent an evil spirit between Abimelech and the men of Shechem; and the men of Shechem dealt treacherously with Abimelech:
24 Ki ìwa-ìka ti a ti hù si awọn ãdọrin ọmọ Jerubbaali ki o le wá, ati ẹ̀jẹ wọn sori Abimeleki arakunrin wọn, ẹniti o pa wọn; ati sori awọn ọkunrin Ṣekemu, awọn ẹniti o ràn a lọwọ lati pa awọn arakunrin rẹ̀.
24 That the cruelty done to the threescore and ten sons of Jerubbaal might come, and their blood be laid upon Abimelech their brother, which slew them; and upon the men of Shechem, which aided him in the killing of his brethren.
25 Awọn ọkunrin Ṣekemu si yàn awọn enia ti o ba dè e lori òke, gbogbo awọn ti nkọja lọdọ wọn ni nwọn si njà a li ole: nwọn si sọ fun Abimeleki.
25 And the men of Shechem set liers in wait for him in the top of the mountains, and they robbed all that came along that way by them: and it was told Abimelech.
26 Gaali ọmọ Ebedi si wá ti on ti awọn arakunrin rẹ̀, nwọn si kọja lọ si Ṣekemu: awọn ọkunrin Ṣekemu si gbẹkẹ wọn le e.
26 And Gaal the son of Ebed came with his brethren, and went over to Shechem: and the men of Shechem put their confidence in him.
27 Nwọn si jade lọ si oko, nwọn si ká eso-àjara wọn, nwọn si fọ́n eso na, nwọn si nṣe ariya, nwọn si lọ si ile oriṣa wọn, nwọn si jẹ, nwọn si mu, nwọn si fi Abimeleki ré.
27 And they went out into the fields, and gathered their vineyards, and trode the grapes, and made merry, and went into the house of their god, and did eat and drink, and cursed Abimelech.
28 Gaali ọmọ Ebedi si wipe, Tani Abimeleki? ta si ni Ṣekemu, ti awa o fi ma sìn i? Ṣe ọmọ Jerubbaali ni iṣe? ati Sebulu ijoye rẹ̀? ẹ mã sìn awọn ọkunrin Hamoru baba Ṣekemu: ṣugbọn nitori kili awa o ha ṣe ma sìn on?
28 And Gaal the son of Ebed said, Who is Abimelech, and who is Shechem, that we should serve him? is not he the son of Jerubbaal? and Zebul his officer? serve the men of Hamor the father of Shechem: for why should we serve him?
29 Awọn enia wọnyi iba wà ni ikawọ mi! nigbana ni emi iba ṣí Abimeleki ni ipò. On si wi fun Abimeleki pe, Gbá ogun kún ogun rẹ, ki o si jade.
29 And would to God this people were under my hand! then would I remove Abimelech. And he said to Abimelech, Increase thine army, and come out.
30 Nigbati Sebulu alaṣẹ ilu na si gbọ́ ọ̀rọ Gaali ọmọ Ebedi, o binu gidigidi.
30 And when Zebul the ruler of the city heard the words of Gaal the son of Ebed, his anger was kindled.
31 On si rán awọn onṣẹ ìkọkọ si Abimeleki, wipe, Kiyesi i, Gaali ọmọ Ebedi ati awọn arakunrin rẹ̀ wá si Ṣekemu; si kiyesi i, nwọn rú ilú na sokè si ọ.
31 And he sent messengers unto Abimelech privily, saying, Behold, Gaal the son of Ebed and his brethren be come to Shechem; and, behold, they fortify the city against thee.
32 Njẹ nitorina, dide li oru, iwọ ati awọn enia ti o wà pẹlu rẹ, ki ẹnyin ki o si ba sinu oko:
32 Now therefore up by night, thou and the people that is with thee, and lie in wait in the field:
33 Yio si ṣe, li owurọ̀, lojukanna bi õrùn ba si ti là, ki iwọ ki o dide ni kùtukutu owurọ̀, ki iwọ ki o si kọlù ilu na: si kiyesi i, nigbati on ati awọn enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀ ba jade tọ̀ ọ, nigbana ni ki iwọ ki o ṣe si wọn bi iwọ ba ti ri pe o yẹ.
33 And it shall be, that in the morning, as soon as the sun is up, thou shalt rise early, and set upon the city: and, behold, when he and the people that is with him come out against thee, then mayest thou do to them as thou shalt find occasion.
34 Abimeleki si dide, ati gbogbo awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ li oru, nwọn si ba ni ipa mẹrin leti Ṣekemu.
34 And Abimelech rose up, and all the people that were with him, by night, and they laid wait against Shechem in four companies.
35 Gaali ọmọ Ebedi si jade, o si duro li ẹnu-ọ̀na ibode ilu na: Abimeleki si dide, ati awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀, kuro ni ibùba.
35 And Gaal the son of Ebed went out, and stood in the entering of the gate of the city: and Abimelech rose up, and the people that were with him, from lying in wait.
36 Nigbati Gaali si ri awọn enia na, o wi fun Sebulu pe, Wò o, awọn enia nti ori òke sọkalẹ wa. Sebulu si wi fun u pe, Ojiji òke wọnni ni iwọ ri bi ẹnipe enia.
36 And when Gaal saw the people, he said to Zebul, Behold, there come people down from the top of the mountains. And Zebul said unto him, Thou seest the shadow of the mountains as if they were men.
37 Gaali si tun wipe, Wò o, awọn enia nti òke sọkalẹ li agbedemeji ilẹ wá, ẹgbẹ kan si nti ọ̀na igi-oaku Meonenimu wá.
37 And Gaal spake again and said, See there come people down by the middle of the land, and another company come along by the plain of Meonenim.
38 Nigbana ni Sebulu wi fun u pe, Nibo li ẹnu rẹ wà nisisiyi, ti iwọ fi wipe, Tani Abimeleki, ti awa o fi ma sìn i? awọn enia ti iwọ ti gàn kọ́ ni iwọnyi? jọwọ jade lọ, nisisiyi, ki o si bà wọn jà.
38 Then said Zebul unto him, Where is now thy mouth, wherewith thou saidst, Who is Abimelech, that we should serve him? is not this the people that thou hast despised? go out, I pray now, and fight with them.
39 Gaali si jade niwaju awọn ọkunrin Ṣekemu, o si bá Abimeleki jà.
39 And Gaal went out before the men of Shechem, and fought with Abimelech.
40 Abimeleki si lé e, on si sá niwaju rẹ̀, ọ̀pọlọpọ ninu nwọn ti o gbọgbẹ si ṣubu, titi dé ẹnu-ọ̀na ibode.
40 And Abimelech chased him, and he fled before him, and many were overthrown and wounded, even unto the entering of the gate.
41 Abimeleki si joko ni Aruma: Sebulu si tì Gaali ati awọn arakunrin rẹ̀ jade, ki nwọn ki o má ṣe joko ni Ṣekemu.
41 And Abimelech dwelt at Arumah: and Zebul thrust out Gaal and his brethren, that they should not dwell in Shechem.
42 O si ṣe ni ijọ keji, ti awọn enia si jade lọ sinu oko; nwọn si sọ fun Abimeleki.
42 And it came to pass on the morrow, that the people went out into the field; and they told Abimelech.
43 On si mu awọn enia, o si pín wọn si ipa mẹta, o si ba ninu oko: o si wò, si kiyesi i, awọn enia nti ilu jade wá; on si dide si wọn, o si kọlù wọn.
43 And he took the people, and divided them into three companies, and laid wait in the field, and looked, and, behold, the people were come forth out of the city; and he rose up against them, and smote them.
44 Abimeleki, ati ẹgbẹ́ ti o wà lọdọ rẹ̀ sure siwaju, nwọn si duro li ẹnu-ọ̀na ibode ilu na: ẹgbẹ meji si sure si gbogbo awọn enia na ti o wà ninu oko, nwọn si kọlù wọn.
44 And Abimelech, and the company that was with him, rushed forward, and stood in the entering of the gate of the city: and the two other companies ran upon all the people that were in the fields, and slew them.
45 Abimeleki si bá ilu na jà ni gbogbo ọjọ́ na; on si kó ilu na, o si pa awọn enia ti o wà ninu rẹ̀, o si wó ilu na palẹ, o si fọn iyọ̀ si i.
45 And Abimelech fought against the city all that day; and he took the city, and slew the people that was therein, and beat down the city, and sowed it with salt.
46 Nigbati gbogbo awọn ọkunrin ile-ẹṣọ́ Ṣekemu gbọ́, nwọn si wọ̀ inu ile-ẹṣọ́ oriṣa Eliberiti lọ.
46 And when all the men of the tower of Shechem heard that, they entered into an hold of the house of the god Berith.
47 A si sọ fun Abimeleki pe, gbogbo awọn ọkunrin ile-ẹṣọ́ Ṣekemu kó ara wọn jọ pọ̀.
47 And it was told Abimelech, that all the men of the tower of Shechem were gathered together.
48 Abimeleki si gùn ori òke Salmoni lọ, on ati gbogbo enia ti o wà pẹlu rẹ̀; Abimeleki si mu ãke kan li ọwọ́ rẹ̀, o si ke ẹka kan kuro lara igi, o si mú u, o si gbé e lé èjika rẹ̀, o si wi fun awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ pe, Ohun ti ẹnyin ri ti emi ṣe, ẹ yára, ki ẹ si ṣe bi emi ti ṣe.
48 And Abimelech gat him up to mount Zalmon, he and all the people that were with him; and Abimelech took an axe in his hand, and cut down a bough from the trees, and took it, and laid it on his shoulder, and said unto the people that were with him, What ye have seen me do, make haste, and do as I have done.
49 Gbogbo awọn enia na pẹlu, olukuluku si ke ẹka tirẹ̀, nwọn si ntọ̀ Abimeleki lẹhin, nwọn si fi wọn sinu ile-ẹṣọ́ na, nwọn si tinabọ ile na mọ́ wọn lori, tobẹ̃ ti gbogbo awọn ọkunrin ile-ẹṣọ́ Ṣekemu fi kú pẹlu, ìwọn ẹgbẹrun enia, ọkunrin ati obinrin.
49 And all the people likewise cut down every man his bough, and followed Abimelech, and put them to the hold, and set the hold on fire upon them; so that all the men of the tower of Shechem died also, about a thousand men and women.
50 Nigbana ni Abimeleki lọ si Tebesi, o si dótì Tebesi, o si kó o.
50 Then went Abimelech to Thebez, and encamped against Thebez, and took it.
51 Ṣugbọn ile-ẹṣọ́ ti o lagbara wà ninu ilu na, nibẹ̀ ni gbogbo awọn ọkunrin ati awọn obinrin, ati gbogbo awọn ẹniti o wà ni ilu na gbé sá si, nwọn si fara wọn mọ́ ibẹ̀; nwọn si gòke ile-ẹṣọ́ na lọ.
51 But there was a strong tower within the city, and thither fled all the men and women, and all they of the city, and shut it to them, and gat them up to the top of the tower.
52 Abimeleki si wá si ibi ile-ẹṣọ́ na, o si bá a jà, o si sunmọ ẹnu-ọ̀na ile-ẹṣọ na lati fi iná si i.
52 And Abimelech came unto the tower, and fought against it, and went hard unto the door of the tower to burn it with fire.
53 Obinrin kan si sọ ọlọ lù Abimeleki li ori, o si fọ́ ọ li agbári.
53 And a certain woman cast a piece of a millstone upon Abimelech's head, and all to brake his skull.
54 Nigbana li o pè ọmọkunrin ti nrù ihamọra rẹ̀ kánkan, o si wi fun u pe, Fà idà rẹ yọ, ki o si pa mi, ki awọn enia ki o má ba wi nipa ti emi pe, Obinrin li o pa a. Ọmọkunrin rẹ̀ si gún u, bẹ̃li o si kú.
54 Then he called hastily unto the young man his armourbearer, and said unto him, Draw thy sword, and slay me, that men say not of me, A woman slew him. And his young man thrust him through, and he died.
55 Nigbati awọn ọkunrin Israeli si ri pe, Abimeleki kú, nwọn si lọ olukuluku si ipò rẹ̀.
55 And when the men of Israel saw that Abimelech was dead, they departed every man unto his place.
56 Bayi li Ọlọrun san ìwa buburu Abimeleki, ti o ti hù si baba rẹ̀, niti pe, o pa ãdọrin awọn arakunrin rẹ̀:
56 Thus God rendered the wickedness of Abimelech, which he did unto his father, in slaying his seventy brethren:
57 Ati gbogbo ìwa buburu awọn ọkunrin Ṣekemu li Ọlọrun si múpada sori wọn: egún Jotamu ọmọ Jerubbaali si ṣẹ sori wọn.
57 And all the evil of the men of Shechem did God render upon their heads: and upon them came the curse of Jotham the son of Jerubbaal.