Judges 20 - Listen Online
Read Judges 20
1 NIGBANA ni gbogbo awọn ọmọ Israeli jade lọ, ijọ awọn enia si wọjọ pọ̀ bi ọkunrin kan, lati Dani lọ titi o fi dé Beeri-ṣeba, pẹlu ilẹ Gileadi, si ọdọ OLUWA ni Mispa.
1 Then all the children of Israel went out, and the congregation was gathered together as one man, from Dan even to Beer-sheba, with the land of Gilead, unto the LORD in Mizpeh.
2 Awọn olori gbogbo enia na, ani ti gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli, si pésẹ̀ larin ijọ awọn enia Ọlọrun, ogún ọkẹ ọkunrin ẹlẹsẹ̀ ti o kọ idà.
2 And the chief of all the people, even of all the tribes of Israel, presented themselves in the assembly of the people of God, four hundred thousand footmen that drew sword.
3 (Awọn ọmọ Benjamini si gbọ́ pe awọn ọmọ Israeli gòke lọ si Mispa.) Awọn ọmọ Israeli si wipe, Sọ fun wa, bawo ni ti ìwabuburu yi ti ri?
3 (Now the children of Benjamin heard that the children of Israel were gone up to Mizpeh.) Then said the children of Israel, Tell us, how was this wickedness?
4 Ọkunrin Lefi na, bale obinrin na ti a pa, dahùn wipe, Mo wá si Gibea ti iṣe ti Benjamini, emi ati àle mi, lati wọ̀.
4 And the Levite, the husband of the woman that was slain, answered and said, I came into Gibeah that belongeth to Benjamin, I and my concubine, to lodge.
5 Awọn ọkunrin Gibea si dide si mi, nwọn si yi ile na ká mọ́ mi li oru; nwọn si rò lati pa mi, nwọn si ba àle mi ṣe iṣekuṣe, o si kú.
5 And the men of Gibeah rose against me, and beset the house round about upon me by night, and thought to have slain me: and my concubine have they forced, that she is dead.
6 Mo si mú àle mi, mo ke e wẹ́wẹ, mo si rán a lọ si gbogbo ilẹ-iní Israeli: nitoriti nwọn hù ìwakiwa ati ìwa wère ni Israeli.
6 And I took my concubine, and cut her in pieces, and sent her throughout all the country of the inheritance of Israel: for they have committed lewdness and folly in Israel.
7 Kiyesi i, ọmọ Israeli ni gbogbo nyin ṣe, ẹ mú èro ati ìmọran nyin wá.
7 Behold, ye are all children of Israel; give here your advice and counsel.
8 Gbogbo awọn enia na si dide bi ọkunrin kan, wipe, Kò sí ẹnikẹni ninu wa ti yio wọ̀ inu agọ́ rẹ̀ lọ, bẹ̃ni kò sí ẹnikẹni ti yio pada si ile rẹ̀.
8 And all the people arose as one man, saying, We will not any of us go to his tent, neither will we any of us turn into his house.
9 Ṣugbọn nisisiyi eyi li ohun ti a o ṣe si Gibea; awa ṣẹ keké, awa o si gòke lọ sibẹ̀;
9 But now this shall be the thing which we will do to Gibeah; we will go up by lot against it;
10 Awa o si mú ọkunrin mẹwa ninu ọgọrun jalẹ ni gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli, ati ọgọrun ninu ẹgbẹrun, ati ẹgbẹrun ninu ẹgbãrun, lati mú onjẹ fun awọn enia na wá, ki nwọn ki o le ṣe, nigbati nwọn ba dé Gibea ti Benjamini, gẹgẹ bi gbogbo ìwa-wère ti nwọn hù ni Israeli.
10 And we will take ten men of an hundred throughout all the tribes of Israel, and an hundred of a thousand, and a thousand out of ten thousand, to fetch victual for the people, that they may do, when they come to Gibeah of Benjamin, according to all the folly that they have wrought in Israel.
11 Bẹ̃ni gbogbo ọkunrin Israeli dó tì ilu na, nwọn fi ìmọ ṣọkan bi enia kan.
11 So all the men of Israel were gathered against the city, knit together as one man.
12 Awọn ẹ̀ya Israeli si rán ọkunrin si gbogbo ẹ̀ya Benjamini, wipe, Ìwa buburu kili eyiti a hù lãrin nyin yi?
12 And the tribes of Israel sent men through all the tribe of Benjamin, saying, What wickedness is this that is done among you?
13 Njẹ nisisiyi ẹ mu awọn ọkunrin na fun wa wá, awọn ọmọ Beliali, ti nwọn wà ni Gibea, ki awa ki o le pa wọn, ki awa ki o le mú ìwabuburu kuro ni Israeli. Ṣugbọn awọn ọmọ Benjamini kò fẹ́ fetisi ohùn awọn ọmọ Israeli awọn arakunrin wọn.
13 Now therefore deliver us the men, the children of Belial, which are in Gibeah, that we may put them to death, and put away evil from Israel. But the children of Benjamin would not hearken to the voice of their brethren the children of Israel:
14 Awọn ọmọ Benjamini si kó ara wọn jọ lati ilu wọnni wá si Gibea, lati jade lọ ibá awọn ọmọ Israeli jagun.
14 But the children of Benjamin gathered themselves together out of the cities unto Gibeah, to go out to battle against the children of Israel.
15 A si kà awọn ọmọ Benjamini li ọjọ́ na, lati ilu wọnni wá, nwọn jẹ́ ẹgbã mẹtala ọkunrin ti nkọ idà, lẹhin awọn ara Gibea ti a kà, ẹdẹgbẹrin àṣayan ọkunrin.
15 And the children of Benjamin were numbered at that time out of the cities twenty and six thousand men that drew sword, beside the inhabitants of Gibeah, which were numbered seven hundred chosen men.
16 Ninu gbogbo awọn enia yi, a ri ẹdẹgbẹrin àṣayan ọkunrin aṣòsi; olukuluku wọn le gbọ̀n kànakana ba fọnrán owu li aitase.
16 Among all this people there were seven hundred chosen men lefthanded; every one could sling stones at an hair breadth, and not miss.
17 Ati awọn ọkunrin Israeli, li àika Benjamini, si jẹ́ ogún ọkẹ enia ti o nkọ idà: gbogbo awọn wọnyi si jẹ́ ologun.
17 And the men of Israel, beside Benjamin, were numbered four hundred thousand men that drew sword: all these were men of war.
18 Awọn ọmọ Israeli si dide, nwọn si lọ si Beti-eli nwọn si bère lọdọ Ọlọrun, wipe, Tani ninu wa ti yio tètekọ gòke lọ ibá awọn ọmọ Benjamini jà? OLUWA si wipe, Juda ni yio tète gòke lọ.
18 And the children of Israel arose, and went up to the house of God, and asked counsel of God, and said, Which of us shall go up first to the battle against the children of Benjamin? And the LORD said, Judah shall go up first.
19 Awọn ọmọ Israeli si dide li owurọ̀, nwọn si dótì Gibea.
19 And the children of Israel rose up in the morning, and encamped against Gibeah.
20 Awọn ọkunrin Israeli si jade lọ ibá Benjamini jà; awọn ọkunrin Israeli si tẹ́gun dè wọn ni Gibea.
20 And the men of Israel went out to battle against Benjamin; and the men of Israel put themselves in array to fight against them at Gibeah.
21 Awọn ọmọ Benjamini si ti Gibea jade wá, nwọn si pa ẹgba mọkanla enia ninu awọn ọmọ Israeli.
21 And the children of Benjamin came forth out of Gibeah, and destroyed down to the ground of the Israelites that day twenty and two thousand men.
22 Awọn enia na, awọn ọkunrin Israeli si gbà ara wọn niyanju, nwọn si tun tẹ́gun ni ibi ti nwọn kọ́ tẹ́gun si ni ijọ́ kini.
22 And the people the men of Israel encouraged themselves, and set their battle again in array in the place where they put themselves in array the first day.
23 (Awọn ọmọ Israeli si gòke lọ, nwọn si sọkun niwaju OLUWA titi di aṣalẹ, nwọn si bère lọdọ OLUWA wipe, Ki emi ki o si tun lọ ibá awọn ọmọ Benjamini arakunrin mi jà bi? OLUWA si wipe, Ẹ gòke tọ̀ ọ.)
23 (And the children of Israel went up and wept before the LORD until even, and asked counsel of the LORD, saying, Shall I go up again to battle against the children of Benjamin my brother? And the LORD said, Go up against him.)
24 Awọn ọmọ Israeli si sunmọ awọn ọmọ Benjamini ni ijọ́ keji.
24 And the children of Israel came near against the children of Benjamin the second day.
25 Benjamini si jade si wọn lati Gibea wa ni ijọ́ keji, nwọn si pa ninu awọn ọmọ Israeli ẹgba mẹsan ọkunrin; gbogbo awọn wọnyi li o nkọ idà.
25 And Benjamin went forth against them out of Gibeah the second day, and destroyed down to the ground of the children of Israel again eighteen thousand men; all these drew the sword.
26 Nigbana ni gbogbo awọn ọmọ Israeli, ati gbogbo awọn enia na gòke lọ, nwọn wá si Beti-eli, nwọn sọkun, nwọn si joko nibẹ̀ niwaju OLUWA, nwọn si gbàwẹ li ọjọ́ na titi di aṣalẹ; nwọn si ru ẹbọ sisun ati ẹbọ alafia niwaju OLUWA.
26 Then all the children of Israel, and all the people, went up, and came unto the house of God, and wept, and sat there before the LORD, and fasted that day until even, and offered burnt offerings and peace offerings before the LORD.
27 Awọn ọmọ Israeli si bère lọdọ OLUWA, (nitori ti apoti majẹmu Ọlọrun mbẹ nibẹ̀ li ọjọ́ wọnni.
27 And the children of Israel inquired of the LORD, (for the ark of the covenant of God was there in those days,
28 Finehasi ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni si nduro niwaju rẹ̀ li ọjọ́ wọnni,) wipe, Ki emi ki o ha si tun gbogun jade si Benjamini arakunrin mi bi? tabi ki emi ki o dẹkun? OLUWA si wipe, Ẹ gòke lọ; nitoripe li ọla emi o fi i lé ọ lọwọ.
28 And Phinehas, the son of Eleazar, the son of Aaron, stood before it in those days,) saying, Shall I yet again go out to battle against the children of Benjamin my brother, or shall I cease? And the LORD said, Go up; for to morrow I will deliver them into thine hand.
29 Israeli si yàn awọn enia ti o ba yi Gibea ká.
29 And Israel set liers in wait round about Gibeah.
30 Awọn ọmọ Israeli si gòke tọ̀ awọn ọmọ Benjamini lọ ni ijọ́ kẹta, nwọn si tẹ́gun si Gibea, gẹgẹ bi ìgba iṣaju.
30 And the children of Israel went up against the children of Benjamin on the third day, and put themselves in array against Gibeah, as at other times.
31 Awọn ọmọ Benjamini si jade tọ̀ awọn enia na lọ, a si fà wọn kuro ni ilu; nwọn si bẹ̀rẹsi kọlù ninu awọn enia, nwọn npa, gẹgẹ bi ìgba iṣaju; li opópo wọnni ti o lọ si Beti-eli, ati ekeji si Gibea, ni pápa, nwọn pa ìwọn ọgbọ̀n ọkunrin ninu Israeli.
31 And the children of Benjamin went out against the people, and were drawn away from the city; and they began to smite of the people, and kill, as at other times, in the highways, of which one goeth up to the house of God, and the other to Gibeah in the field, about thirty men of Israel.
32 Awọn ọmọ Benjamini si wipe, A lù wọn bolẹ niwaju wa, gẹgẹ bi ìgba iṣaju. Ṣugbọn awọn ọmọ Israeli wipe, Ẹ jẹ ki a sá, ki a si fà wọn kuro ni ìlú si opópo.
32 And the children of Benjamin said, They are smitten down before us, as at the first. But the children of Israel said, Let us flee, and draw them from the city unto the highways.
33 Gbogbo awọn ọkunrin Israeli si dide kuro ni ipò wọn, nwọn si tẹ́gun ni Baali-tamari: awọn ti o wà ni ibuba ninu awọn enia Israeli si dide kuro ni ipo wọn, lati pápa Gibea wá.
33 And all the men of Israel rose up out of their place, and put themselves in array at Baal-tamar: and the liers in wait of Israel came forth out of their places, even out of the meadows of Gibeah.
34 Ẹgba marun ọkunrin ti a ti yàn ninu gbogbo Israeli si lọ si Gibea, ìja na si le gidigidi: ṣugbọn nwọn kò si mọ̀ pe ibi sunmọ wọn.
34 And there came against Gibeah ten thousand chosen men out of all Israel, and the battle was sore: but they knew not that evil was near them.
35 OLUWA si kọlù Benjamini niwaju Israeli: awọn ọmọ Israeli si pa ẹgba mejila ọkunrin o le ẹdẹgbẹfa li ọjọ́ na ninu awọn enia Benjamini: gbogbo awọn wọnyi li o kọ́ idà.
35 And the LORD smote Benjamin before Israel: and the children of Israel destroyed of the Benjamites that day twenty and five thousand and an hundred men: all these drew the sword.
36 Bẹ̃li awọn ọmọ Benjamini wa ri pe a ṣẹgun wọn: nitoriti awọn ọkunrin Israeli bìsẹhin fun awọn ara Benjamini nitoriti nwọn gbẹkẹle awọn ti o wà ni ibùba, ti nwọn yàn si eti Gibea.
36 So the children of Benjamin saw that they were smitten: for the men of Israel gave place to the Benjamites, because they trusted unto the liers in wait which they had set beside Gibeah.
37 Awọn ti o wà ni ibùba si yára, nwọn rọ́wọ̀ Gibea; awọn ti o wà ni ibuba si papọ̀, nwọn si fi oju idà kọlù gbogbo ilu na.
37 And the liers in wait hasted, and rushed upon Gibeah; and the liers in wait drew themselves along, and smote all the city with the edge of the sword.
38 Njẹ àmi ti o wà lãrin awọn ọkunrin Israeli, ati awọn ti o wà ni ibùba ni pe, ki nwọn jẹ ki ẹ̃fi nla ki o rú soke lati ilu na wá.
38 Now there was an appointed sign between the men of Israel and the liers in wait, that they should make a great flame with smoke rise up out of the city.
39 Nigbati awọn ọkunrin Israeli si pẹhinda ni ibi ìja na, Benjamini si bẹ̀rẹsi kọlù ninu awọn ọkunrin Israeli, o si pa bi ọgbọ̀n enia: nitoriti nwọn wipe, Nitõtọ a lù wọn bolẹ niwaju wa, gẹgẹ bi ìja iṣaju.
39 And when the men of Israel retired in the battle, Benjamin began to smite and kill of the men of Israel about thirty persons: for they said, Surely they are smitten down before us, as in the first battle.
40 Ṣugbọn nigbati awọsanma bẹ̀rẹsi rú soke lati ilu na wá pẹlu gọ́gọ ẹ̃fi, awọn ara Benjamini wò ẹhin wọn, si kiyesi i, ẹ̃fi gbogbo ilu na gòke lọ si ọrun.
40 But when the flame began to arise up out of the city with a pillar of smoke, the Benjamites looked behind them, and, behold, the flame of the city ascended up to heaven.
41 Awọn ọkunrin Israeli si yipada, awọn ọkunrin Benjamini si damu: nitoriti nwọn ri pe ibi déba wọn.
41 And when the men of Israel turned again, the men of Benjamin were amazed: for they saw that evil was come upon them.
42 Nitorina, nwọn pẹhinda niwaju awọn ọkunrin Israeli si ọ̀na ijù; ṣugbọn ogun na lepa wọn kikan; ati awọn ti o ti ilu wọnni jade wá ni nwọn pa lãrin wọn.
42 Therefore they turned their backs before the men of Israel unto the way of the wilderness; but the battle overtook them; and them which came out of the cities they destroyed in the midst of them.
43 Bẹ̃ni nwọn rọgba yi Benjamini ká, nwọn lepa wọn, nwọn tẹ̀ wọn mọlẹ ni ibi isimi, li ọkankan Gibea si ìha ila-õrùn.
43 Thus they inclosed the Benjamites round about, and chased them, and trode them down with ease over against Gibeah toward the sunrising.
44 Ẹgba mẹsan ọkunrin li o si ṣubu ninu awọn enia Benjamini, gbogbo awọn wọnyi li akọni ọkunrin.
44 And there fell of Benjamin eighteen thousand men; all these were men of valour.
45 Nwọn si yipada nwọn sálọ si ìha ijù sori okuta Rimmoni: nwọn si ṣà ẹgbẹdọgbọ̀n ọkunrin ninu wọn li opópo; nwọn lepa wọn kikan dé Gidomu, nwọn si pa ẹgba ọkunrin ninu wọn.
45 And they turned and fled toward the wilderness unto the rock of Rimmon: and they gleaned of them in the highways five thousand men; and pursued hard after them unto Gidom, and slew two thousand men of them.
46 Bẹ̃ni gbogbo awọn ni o ṣubu ni ijọ́ na ninu awọn ara Benjamini jẹ́ ẹgba mejila ọkunrin o le ẹgbẹrun ti o nkọ idà; gbogbo awọn wọnyi li akọni ọkunrin.
46 So that all which fell that day of Benjamin were twenty and five thousand men that drew the sword; all these were men of valour.
47 Ṣugbọn ẹgbẹta ọkunrin yipada, nwọn si sá si ìha ijù si ibi okuta Rimmoni, nwọn si joko sinu okuta Rimmoni li oṣù mẹrin.
47 But six hundred men turned and fled to the wilderness unto the rock Rimmon, and abode in the rock Rimmon four months.
48 Awọn ọkunrin Israeli si pada tọ̀ awọn ọmọ Benjamini, nwọn si fi oju idà kọlù gbogbo ilu, ati ẹran, ati ohun gbogbo ti nwọn ní: gbogbo ilu ti nwọn ri ni nwọn fi iná kun pẹlu.
48 And the men of Israel turned again upon the children of Benjamin, and smote them with the edge of the sword, as well the men of every city, as the beast, and all that came to hand: also they set on fire all the cities that they came to.