Joshua 9 - Listen Online
Read Joshua 9
1 O si ṣe, nigbati gbogbo awọn ọba ti mbẹ li apa ihin Jordani, li ori òke, ati li afonifoji, ati ni gbogbo àgbegbe okun nla ti o kọjusi Lebanoni, awọn Hitti, ati awọn Amori, awọn Kenaani, awọn Perissi, awọn Hifi, ati awọn Jebusi, gbọ́ ọ;
1 And it came to pass, when all the kings which were on this side Jordan, in the hills, and in the valleys, and in all the coasts of the great sea over against Lebanon, the Hittite, and the Amorite, the Canaanite, the Perizzite, the Hivite, and the Jebusite, heard thereof;
2 Nwọn si kó ara wọn jọ, lati fi ìmọ kan bá Joṣua ati Israeli jà.
2 That they gathered themselves together, to fight with Joshua and with Israel, with one accord.
3 Ṣugbọn nigbati awọn ara Gibeoni gbọ́ ohun ti Joṣua ṣe si Jeriko ati si Ai,
3 And when the inhabitants of Gibeon heard what Joshua had done unto Jericho and to Ai,
4 Nwọn ṣe ẹ̀tan, nwọn si lọ nwọn si ṣe bi ẹnipe onṣẹ ni nwọn, nwọn si mú ogbologbo àpo kà ori kẹtẹkẹtẹ wọn, ati ìgo-awọ ọti-waini ti lailai, ti o ya, ti a si dì;
4 They did work wilily, and went and made as if they had been ambassadors, and took old sacks upon their asses, and wine bottles, old, and rent, and bound up;
5 Ati bàta gbigbo ati lilẹ̀ li ẹsẹ̀ wọn, ati ẹ̀wu gbigbo li ara wọn; ati gbogbo àkara èse wọn o gbẹ o si hùkasi.
5 And old shoes and clouted upon their feet, and old garments upon them; and all the bread of their provision was dry and mouldy.
6 Nwọn si tọ̀ Joṣua lọ ni ibudó ni Gilgali, nwọn si wi fun u, ati fun awọn ọkunrin Israeli pe, Ilu òkere li awa ti wá; njẹ nitorina ẹ bá wa dá majẹmu.
6 And they went to Joshua unto the camp at Gilgal, and said unto him, and to the men of Israel, We be come from a far country: now therefore make ye a league with us.
7 Awọn ọkunrin Israeli si wi fun awọn Hifi pe, Bọya ẹnyin ngbé ãrin wa; awa o ti ṣe bá nyin dá majẹmu?
7 And the men of Israel said unto the Hivites, Peradventure ye dwell among us; and how shall we make a league with you?
8 Nwọn si wi fun Joṣua pe, Iranṣẹ rẹ li awa iṣe. Joṣua si wi fun wọn pe, Tali ẹnyin? nibo li ẹnyin si ti wá?
8 And they said unto Joshua, We are thy servants. And Joshua said unto them, Who are ye? and from whence come ye?
9 Nwọn si wi fun u pe, Ni ilu òkere rére li awọn iranṣẹ rẹ ti wá, nitori orukọ OLUWA Ọlọrun rẹ: nitoriti awa ti gbọ́ okikí rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ṣe ni Egipti,
9 And they said unto him, From a very far country thy servants are come because of the name of the LORD thy God: for we have heard the fame of him, and all that he did in Egypt,
10 Ati ohun gbogbo ti o ṣe si awọn ọba awọn Amori meji, ti mbẹ ni òke Jordani, si Sihoni ọba Heṣboni, ati si Ogu ọba Baṣani, ti mbẹ ni Aṣtarotu.
10 And all that he did to the two kings of the Amorites, that were beyond Jordan, to Sihon king of Heshbon, and to Og king of Bashan, which was at Ashtaroth.
11 Awọn àgba wa ati gbogbo awọn ara ilu wa sọ fun wa pe, Ẹ mú onjẹ li ọwọ́ nyin fun àjo na, ki ẹ si lọ ipade wọn, ki ẹ si wi fun wọn pe, Iranṣẹ nyin li awa iṣe: njẹ nitorina, ẹ bá wa dá majẹmu.
11 Wherefore our elders and all the inhabitants of our country spake to us, saying, Take victuals with you for the journey, and go to meet them, and say unto them, We are your servants: therefore now make ye a league with us.
12 Àkara wa yi ni gbigbona li a mú u fun èse wa, lati ile wa wá, li ọjọ́ ti a jade lati tọ̀ nyin wá; ṣugbọn nisisiyi, kiyesi i, o gbẹ, o si bu:
12 This our bread we took hot for our provision out of our houses on the day we came forth to go unto you; but now, behold, it is dry, and it is mouldy:
13 Ìgo-awọ waini wọnyi, ti awa kún, titun ni nwọn; kiyesi i, nwọn fàya: ati ẹ̀wu wa wọnyi ati bàta wa di gbigbo nitori ọ̀na ti o jìn jù.
13 And these bottles of wine, which we filled, were new; and, behold, they be rent: and these our garments and our shoes are become old by reason of the very long journey.
14 Awọn ọkunrin si gbà ninu onjẹ wọn, nwọn kò si bère li ẹnu OLUWA.
14 And the men took of their victuals, and asked not counsel at the mouth of the LORD.
15 Joṣua si bá wọn ṣọrẹ, o si bá wọn dá majẹmu lati da wọn si: awọn olori ijọ enia fi OLUWA Ọlọrun Israeli bura fun wọn.
15 And Joshua made peace with them, and made a league with them, to let them live: and the princes of the congregation sware unto them.
16 O si ṣe li opin ijọ́ mẹta, lẹhin ìgbati nwọn bá wọn dá majẹmu, ni nwọn gbọ́ pe aladugbo wọn ni nwọn, ati pe làrin wọn ni nwọn gbé wà.
16 And it came to pass at the end of three days after they had made a league with them, that they heard that they were their neighbours, and that they dwelt among them.
17 Awọn ọmọ Israeli si dide, nwọn si dé ilu wọn ni ijọ́ kẹta. Njẹ ilu wọn ni Gibeoni, ati Kefira, ati Beerotu, ati Kiriati-jearimu.
17 And the children of Israel journeyed, and came unto their cities on the third day. Now their cities were Gibeon, and Chephirah, and Beeroth, and Kirjath-jearim.
18 Awọn ọmọ Israeli kò pa wọn, nitoriti awọn olori ijọ awọn enia ti fi OLUWA, Ọlọrun Israeli, bura fun wọn. Gbogbo ijọ awọn enia si kùn si awọn olori.
18 And the children of Israel smote them not, because the princes of the congregation had sworn unto them by the LORD God of Israel. And all the congregation murmured against the princes.
19 Ṣugbọn gbogbo awọn olori wi fun gbogbo ijọ pe, Awa ti fi OLUWA, Ọlọrun Israeli, bura fun wọn: njẹ nitorina awa kò le fọwọkàn wọn.
19 But all the princes said unto all the congregation, We have sworn unto them by the LORD God of Israel: now therefore we may not touch them.
20 Eyi li awa o ṣe si wọn, ani awa o da wọn si, ki ibinu ki o má ba wà lori wa, nitori ibura ti a bura fun wọn.
20 This we will do to them; we will even let them live, lest wrath be upon us, because of the oath which we sware unto them.
21 Awọn olori si wi fun wọn pe, Ẹ da wọn si: nwọn si di aṣẹ́gi ati apọnmi fun gbogbo ijọ; gẹgẹ bi awọn olori ti sọ fun wọn.
21 And the princes said unto them, Let them live; but let them be hewers of wood and drawers of water unto all the congregation; as the princes had promised them.
22 Joṣua si pè wọn, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi tàn wa wipe, Awa jìna rére si nyin; nigbati o jẹ́ pe lãrin wa li ẹnyin ngbé?
22 And Joshua called for them, and he spake unto them, saying, Wherefore have ye beguiled us, saying, We are very far from you; when ye dwell among us?
23 Njẹ nitorina ẹnyin di ẹni egún, ẹrú li ẹnyin o si ma jẹ́ titi, ati aṣẹ́gi ati apọnmi fun ile Ọlọrun mi.
23 Now therefore ye are cursed, and there shall none of you be freed from being bondmen, and hewers of wood and drawers of water for the house of my God.
24 Nwọn si da Joṣua lohùn wipe, Nitoriti a sọ fun awọn iranṣẹ rẹ dajudaju, bi OLUWA Ọlọrun rẹ ti paṣẹ fun Mose iranṣẹ rẹ̀, lati fun nyin ni gbogbo ilẹ na, ati lati pa gbogbo awọn ara ilẹ na run kuro niwaju nyin; nitorina awa bẹ̀ru nyin gidigidi nitori ẹmi wa, a si ṣe nkan yi.
24 And they answered Joshua, and said, Because it was certainly told thy servants, how that the LORD thy God commanded his servant Moses to give you all the land, and to destroy all the inhabitants of the land from before you, therefore we were sore afraid of our lives because of you, and have done this thing.
25 Njẹ nisisiyi, kiyesi i, li ọwọ́ rẹ li awa wà: bi o ti dara si ati bi o ti tọ́ si li oju rẹ lati ṣe wa, ni ki iwọ ki o ṣe.
25 And now, behold, we are in thine hand: as it seemeth good and right unto thee to do unto us, do.
26 Bẹ̃li o si ṣe wọn, o si gbà wọn li ọwọ́ awọn ọmọ Israeli, nwọn kò si pa wọn.
26 And so did he unto them, and delivered them out of the hand of the children of Israel, that they slew them not.
27 Joṣua si ṣe wọn li aṣẹ́gi ati apọnmi fun ijọ, ati fun pẹpẹ OLUWA li ọjọ́ na, ani titi di oni-oloni, ni ibi ti o ba yàn.
27 And Joshua made them that day hewers of wood and drawers of water for the congregation, and for the altar of the LORD, even unto this day, in the place which he should choose.