Joshua 17 - Listen Online
Read Joshua 17
1 EYI si ni ipín ẹ̀ya Manasse; nitori on li akọ́bi Josefu. Bi o ṣe ti Makiri akọ́bi Manasse, baba Gileadi, nitori on ṣe ologun, nitorina li o ṣe ní Gileadi ati Baṣani.
1 There was also a lot for the tribe of Manasseh; for he was the firstborn of Joseph; to wit, for Machir the firstborn of Manasseh, the father of Gilead: because he was a man of war, therefore he had Gilead and Bashan.
2 Awọn ọmọ Manasse iyokù si ní ilẹ-iní gẹgẹ bi idile wọn; awọn ọmọ Abieseri, ati awọn ọmọ Heleki, ati awọn ọmọ Asrieli, ati awọn ọmọ Ṣekemu, ati awọn ọmọ Heferi, ati awọn ọmọ Ṣemida: awọn wọnyi ni awọn ọmọ Manasse ọmọ Josefu gẹgẹ bi idile wọn.
2 There was also a lot for the rest of the children of Manasseh by their families; for the children of Abiezer, and for the children of Helek, and for the children of Asriel, and for the children of Shechem, and for the children of Hepher, and for the children of Shemida: these were the male children of Manasseh the son of Joseph by their families.
3 Ṣugbọn Selofehadi, ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manasse, kò ní ọmọkunrin, bikoṣe ọmọbinrin: awọn wọnyi si li orukọ awọn ọmọbinrin rẹ̀, Mala, ati Noa, Hogla, Milka, ati Tirsa.
3 But Zelophehad, the son of Hepher, the son of Gilead, the son of Machir, the son of Manasseh, had no sons, but daughters: and these are the names of his daughters, Mahlah, and Noah, Hoglah, Milcah, and Tirzah.
4 Nwọn si wá siwaju Eleasari alufa, ati siwaju Joṣua ọmọ Nuni, ati siwaju awọn olori, wipe, OLUWA fi aṣẹ fun Mose lati fun wa ni ilẹ-iní lãrin awọn arakunrin wa: nitorina o fi ilẹ-iní fun wọn lãrin awọn arakunrin baba wọn, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA.
4 And they came near before Eleazar the priest, and before Joshua the son of Nun, and before the princes, saying, The LORD commanded Moses to give us an inheritance among our brethren. Therefore according to the commandment of the LORD he gave them an inheritance among the brethren of their father.
5 Ipín mẹwa si bọ́ sọdọ Manasse, làika ilẹ Gileadi ati Baṣani, ti mbẹ ni ìha keji Jordani;
5 And there fell ten portions to Manasseh, beside the land of Gilead and Bashan, which were on the other side Jordan;
6 Nitoriti awọn ọmọbinrin Manasse ní ilẹ-iní lãrin awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin: awọn ọmọ Manasse ọkunrin iyokù si ní ilẹ Gileadi.
6 Because the daughters of Manasseh had an inheritance among his sons: and the rest of Manasseh's sons had the land of Gilead.
7 Àla Manasse si lọ lati Aṣeri dé Mikmeta, ti mbẹ niwaju Ṣekemu; àla na si lọ titi ni ìha ọtún, sọdọ awọn ara Eni-tappua.
7 And the coast of Manasseh was from Asher to Michmethah, that lieth before Shechem; and the border went along on the right hand unto the inhabitants of En-tappuah.
8 Manasse li o ní ilẹ Tappua: ṣugbọn Tappua li àla Manasse jẹ́ ti awọn ọmọ Efraimu.
8 Now Manasseh had the land of Tappuah: but Tappuah on the border of Manasseh belonged to the children of Ephraim;
9 Àla rẹ̀ si sọkalẹ lọ si odò Kana, ni ìha gusù odò na: ilu Efraimu wọnyi wà lãrin awọn ilu Manasse: àla Manasse pẹlu si wà ni ìha ariwa odò na, o si yọ si okun:
9 And the coast descended unto the river Kanah, southward of the river: these cities of Ephraim are among the cities of Manasseh: the coast of Manasseh also was on the north side of the river, and the outgoings of it were at the sea:
10 Ni ìha gusù ti Efraimu ni, ati ni ìha ariwa ti Manasse ni, okun si ni àla rẹ̀; nwọn si dé Aṣeri ni ìha ariwa, ati Issakari ni ìha ìla-õrùn.
10 Southward it was Ephraim's, and northward it was Manasseh's, and the sea is his border; and they met together in Asher on the north, and in Issachar on the east.
11 Manasse si ní ni Issakari ati ni Aṣeri, Beti-ṣeani ati awọn ilu rẹ̀, ati Ibleamu ati awọn ilu rẹ̀, ati awọn ara Dori ati awọn ilu rẹ̀, ati awọn ara Enidori ati awọn ilu rẹ̀, ati awọn ara Taanaki ati awọn ilu rẹ̀, ati awọn ara Megiddo ati awọn ilu rẹ̀, ani òke mẹta na.
11 And Manasseh had in Issachar and in Asher Beth-shean and her towns, and Ibleam and her towns, and the inhabitants of Dor and her towns, and the inhabitants of Endor and her towns, and the inhabitants of Taanach and her towns, and the inhabitants of Megiddo and her towns, even three countries.
12 Ṣugbọn awọn ọmọ Manasse kò le gbà ilu wọnyi; awọn ara Kenaani si ngbé ilẹ na.
12 Yet the children of Manasseh could not drive out the inhabitants of those cities; but the Canaanites would dwell in that land.
13 O si ṣe, nigbati awọn ọmọ Israeli ndi alagbara, nwọn mu awọn ara Kenaani sìn, ṣugbọn nwọn kò lé wọn jade patapata.
13 Yet it came to pass, when the children of Israel were waxen strong, that they put the Canaanites to tribute; but did not utterly drive them out.
14 Awọn ọmọ Josefu si wi fun Joṣua pe, Ẽṣe ti iwọ fi fun mi ni ilẹ kan, ati ipín kan ni ilẹ-iní, bẹ̃ni enia nla ni mi, niwọnbi OLUWA ti bukún mi titi di isisiyi?
14 And the children of Joseph spake unto Joshua, saying, Why hast thou given me but one lot and one portion to inherit, seeing I am a great people, forasmuch as the LORD hath blessed me hitherto?
15 Joṣua si da wọn lohùn pe, Bi iwọ ba jẹ́ enia nla, gòke lọ si igbó, ki o si ṣanlẹ fun ara rẹ nibẹ̀ ni ilẹ awọn Perissi ati ti Refaimu; bi òke Efraimu ba há jù fun ọ.
15 And Joshua answered them, If thou be a great people, then get thee up to the wood country, and cut down for thyself there in the land of the Perizzites and of the giants, if mount Ephraim be too narrow for thee.
16 Awọn ọmọ Josefu si wipe, Òke na kò to fun wa: gbogbo awọn ara Kenaani ti ngbé ilẹ afonifoji si ní kẹkẹ́ irin, ati awọn ti mbẹ ni Beti-ṣeani, ati awọn ilu rẹ̀, ati awọn ti mbẹ ni afonifoji Jesreeli.
16 And the children of Joseph said, The hill is not enough for us: and all the Canaanites that dwell in the land of the valley have chariots of iron, both they who are of Beth-shean and her towns, and they who are of the valley of Jezreel.
17 Joṣua si wi fun ile Josefu, ani fun Efraimu ati fun Manasse pe, Enia nla ni iwọ, iwọ si lí agbara pipọ̀: iwọ ki yio ní ipín kanṣoṣo:
17 And Joshua spake unto the house of Joseph, even to Ephraim and to Manasseh, saying, Thou art a great people, and hast great power: thou shalt not have one lot only:
18 Ṣugbọn ilẹ òke yio jẹ́ tirẹ; nitoriti iṣe igbó, iwọ o si ṣán a, ati ìna rẹ̀ yio jẹ́ tirẹ: nitoriti iwọ o lé awọn ara Kenaani jade, bi o ti jẹ́ pe nwọn ní kẹkẹ́ irin nì, ti o si jẹ́ pe nwọn lí agbara.
18 But the mountain shall be thine; for it is a wood, and thou shalt cut it down: and the outgoings of it shall be thine: for thou shalt drive out the Canaanites, though they have iron chariots, and though they be strong.