Joshua 12 - Listen Online
Read Joshua 12
1 NJẸ wọnyi ni awọn ọba ilẹ na, ti awọn ọmọ Israeli pa, ti nwọn si gbà ilẹ wọn li apa keji Jordani, ni ìha ìla-õrùn, lati odò Arnoni lọ titi dé òke Hermoni, ati gbogbo pẹtẹlẹ̀ ni ìha ìla-õrun:
1 Now these are the kings of the land, which the children of Israel smote, and possessed their land on the other side Jordan toward the rising of the sun, from the river Arnon unto mount Hermon, and all the plain on the east:
2 Sihoni ọba Amori, ti ngbé Heṣboni, ti o si jọba lati Aroeri, ti mbẹ leti odò Arnoni, ati ilu ti o wà lãrin afonifoji na, ati àbọ Gileadi, ani titi dé odò Jaboku, àgbegbe awọn ọmọ Ammoni;
2 Sihon king of the Amorites, who dwelt in Heshbon, and ruled from Aroer, which is upon the bank of the river Arnon, and from the middle of the river, and from half Gilead, even unto the river Jabbok, which is the border of the children of Ammon;
3 Ati ni pẹtẹlẹ̀ lọ dé okun Kinnerotu ni ìha ìla-õrùn, ati titi dé okun pẹtẹlẹ̀, ani Okun Iyọ̀ ni ìha ìla-õrun, li ọ̀na Beti-jeṣimotu; ati lati gusù lọ nisalẹ ẹsẹ̀-òke Pisga:
3 And from the plain to the sea of Chinneroth on the east, and unto the sea of the plain, even the salt sea on the east, the way to Beth-jeshimoth; and from the south, under Ashdoth-pisgah:
4 Ati àgbegbe Ogu ọba Baṣani, ọkan ninu awọn ti o kù ninu awọn Refaimu, èniti ngbé Aṣtarotu ati Edrei,
4 And the coast of Og king of Bashan, which was of the remnant of the giants, that dwelt at Ashtaroth and at Edrei,
5 O si jọba li òke Hermoni, ati ni Saleka, ati ni gbogbo Baṣani, titi o fi dé àgbegbe awọn Geṣuri ati awọn Maakati, ati àbọ Gileadi, àla Sihoni ọba Heṣboni.
5 And reigned in mount Hermon, and in Salcah, and in all Bashan, unto the border of the Geshurites and the Maachathites, and half Gilead, the border of Sihon king of Heshbon.
6 Mose iranṣẹ OLUWA ati awọn ọmọ Israeli kọlù wọn: Mose iranṣẹ OLUWA si fi i fun awọn ọmọ Reubeni ni ilẹ-iní, ati fun awọn ọmọ Gadi, ati fun àbọ ẹ̀ya Manasse.
6 Them did Moses the servant of the LORD and the children of Israel smite: and Moses the servant of the LORD gave it for a possession unto the Reubenites, and the Gadites, and the half tribe of Manasseh.
7 Wọnyi li awọn ọba ilẹ na, ti Joṣua ati awọn ọmọ Israeli pa li apa ihin Jordani, ni ìwọ-õrùn, lati Baali-gadi li afonifoji Lebanoni ani titidé òke Halaki, li ọ̀na òke Seiri; ti Joṣua fi fun awọn ẹ̀ya Israeli ni ilẹ-iní gẹgẹ bi ipín wọn.
7 And these are the kings of the country which Joshua and the children of Israel smote on this side Jordan on the west, from Baal-gad in the valley of Lebanon even unto the mount Halak, that goeth up to Seir; which Joshua gave unto the tribes of Israel for a possession according to their divisions;
8 Ni ilẹ òke, ati ni ilẹ titẹju, ati ni pẹtẹlẹ̀, ati li ẹsẹ̀-òke, ati li aginjù, ati ni Gusù; awọn Hitti, awọn Amori, ati awọn ara Kenaani, awọn Perissi, awọn Hifi, ati awọn Jebusi:
8 In the mountains, and in the valleys, and in the plains, and in the springs, and in the wilderness, and in the south country; the Hittites, the Amorites, and the Canaanites, the Perizzites, the Hivites, and the Jebusites:
9 Ọba Jeriko, ọkan; ọba Ai, ti o wà lẹba Beti-eli, ọkan.
9 The king of Jericho, one; the king of Ai, which is beside Bethel, one;
10 Ọba Jerusalemu, ọkan; ọba Hebroni, ọkan;
10 The king of Jerusalem, one; the king of Hebron, one;
11 Ọba Jarmutu, ọkan; ọba Lakiṣi, ọkan;
11 The king of Jarmuth, one; the king of Lachish, one;
12 Ọba Egloni, ọkan; ọba Geseri, ọkan;
12 The king of Eglon, one; the king of Gezer, one;
13 Ọba Debiri, ọkan; ọba Gederi, ọkan;
13 The king of Debir, one; the king of Geder, one;
14 Ọba Horma, ọkan; ọba Aradi, ọkan;
14 The king of Hormah, one; the king of Arad, one;
15 Ọba Libna, ọkan; ọba Adullamu, ọkan;
15 The king of Libnah, one; the king of Adullam, one;
16 Ọba Makkeda, ọkan; ọba Betieli, ọkan;
16 The king of Makkedah, one; the king of Bethel, one;
17 Ọba Tappua, ọkan; ọba Heferi, ọkan;
17 The king of Tappuah, one; the king of Hepher, one;
18 Ọba Afeki, ọkan; ọba Laṣaroni, ọkan;
18 The king of Aphek, one; the king of Lasharon, one;
19 Ọba Madoni, ọkan; ọba Hasoru, ọkan;
19 The king of Madon, one; the king of Hazor, one;
20 Ọba Ṣimroni-meroni, ọkan; ọba Akṣafu, ọkan;
20 The king of Shimron-meron, one; the king of Achshaph, one;
21 Ọba Taanaki, ọkan; ọba Megiddo, ọkan;
21 The king of Taanach, one; the king of Megiddo, one;
22 Ọba Kedeṣi, ọkan; ọba Jokneamu ti Karmeli, ọkan;
22 The king of Kedesh, one; the king of Jokneam of Carmel, one;
23 Ọba Doru, li òke Doru, ọkan; ọba awọn orilẹ-ède Gilgali, ọkan;
23 The king of Dor in the coast of Dor, one; the king of the nations of Gilgal, one;
24 Ọba Tirsa, ọkan; gbogbo awọn ọba na jẹ́ mọkanlelọgbọ̀n.
24 The king of Tirzah, one: all the kings thirty and one.