Jonah 3 - Listen Online
Read Jonah 3
1 Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ Jona wá lẹ̃keji, wipe,
1 And the word of the LORD came unto Jonah the second time, saying,
2 Dide, lọ si Ninefe, ilu nla nì, ki o si kede si i, ikede ti mo sọ fun ọ.
2 Arise, go unto Nineveh, that great city, and preach unto it the preaching that I bid thee.
3 Jona si dide, o si lọ si Ninefe, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa. Ninefe si jẹ ilu nla gidigidi tó irin ijọ mẹta.
3 So Jonah arose, and went unto Nineveh, according to the word of the LORD. Now Nineveh was an exceeding great city of three days' journey.
4 Jona si bẹrẹsi wọ inu ilu na lọ ni irin ijọ kan, o si kede, o si wipe, Niwọn ogoji ọjọ si i, a o bì Ninefe wo.
4 And Jonah began to enter into the city a day's journey, and he cried, and said, Yet forty days, and Nineveh shall be overthrown.
5 Awọn enia Ninefe si gba Ọlọrun gbọ́, nwọn si kede awẹ̀, nwọn si wọ aṣọ ọ̀fọ, lati agbà wọn titi de kekere wọn.
5 So the people of Nineveh believed God, and proclaimed a fast, and put on sackcloth, from the greatest of them even to the least of them.
6 Ọ̀rọ na si de ọdọ ọba Ninefe, o si dide kuro lori itẹ rẹ̀, o si bọ aṣọ igunwa rẹ̀ kuro lara rẹ̀, o si daṣọ ọ̀fọ bora, o si joko ninu ẽru.
6 For word came unto the king of Nineveh, and he arose from his throne, and he laid his robe from him, and covered him with sackcloth, and sat in ashes.
7 O si kede rẹ̀, o si wi pe ki a là Ninefe ja nipa aṣẹ ọba, ati awọn agbagbà rẹ̀ pe, Máṣe jẹ ki enia, tabi ẹranko, ọwọ-ẹran tabi agbo-ẹran, tọ́ ohunkohun wò: má jẹ ki wọn jẹun, má jẹ ki wọn mu omi.
7 And he caused it to be proclaimed and published through Nineveh by the decree of the king and his nobles, saying, Let neither man nor beast, herd nor flock, taste any thing: let them not feed, nor drink water:
8 Ṣugbọn jẹ ki enia ati ẹranko fi aṣọ ọ̀fọ bora, ki nwọn si kigbe kikan si Ọlọrun: si jẹ ki nwọn yipada, olukuluku kuro li ọ̀na ibi rẹ̀, ati kuro ni ìwa agbara ti o wà lọwọ wọn.
8 But let man and beast be covered with sackcloth, and cry mightily unto God: yea, let them turn every one from his evil way, and from the violence that is in their hands.
9 Tani le mọ̀ bi Ọlọrun yio yipada ki o si ronupiwada, ki o si yipada kuro ni ibinu gbigbona rẹ̀, ki awa má ṣegbe?
9 Who can tell if God will turn and repent, and turn away from his fierce anger, that we perish not?
10 Ọlọrun si ri iṣe wọn pe nwọn yipada kuro li ọ̀na ibi wọn: Ọlọrun si ronupiwada ibi ti on ti wi pe on o ṣe si wọn; on kò si ṣe e mọ.
10 And God saw their works, that they turned from their evil way; and God repented of the evil, that he had said that he would do unto them; and he did it not.