Jeremiah 49 - Listen Online
Read Jeremiah 49
1 SI awọn ọmọ Ammoni. Bayi li Oluwa wi; Israeli kò ha ni awọn ọmọkunrin? kò ha ni arole bi? nitori kini Malkomu ṣe jogun Gadi, ti awọn enia rẹ̀ si joko ni ilu rẹ̀?
1 Concerning the Ammonites, thus saith the LORD; Hath Israel no sons? hath he no heir? why then doth their king inherit Gad, and his people dwell in his cities?
2 Nitorina, wò o, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, ti emi o mu ki a gbọ́ idagiri ogun ni Rabba ti awọn ọmọ Ammoni: yio si di okiti ahoro, a o si fi iná sun awọn ọmọbinrin rẹ̀; nigbana ni Israeli yio jẹ arole awọn ti o ti jẹ arole rẹ̀, li Oluwa wi.
2 Therefore, behold, the days come, saith the LORD, that I will cause an alarm of war to be heard in Rabbah of the Ammonites; and it shall be a desolate heap, and her daughters shall be burned with fire: then shall Israel be heir unto them that were his heirs, saith the LORD.
3 Hu, iwọ Heṣboni! nitori a fi Ai ṣe ijẹ: kigbe, ẹnyin ọmọbinrin Rabba! ẹ di aṣọ-ọ̀fọ mọra, ẹ pohunrere, ki ẹ si sare soke-sodo lãrin ọgba! nitori Malkomu yio jumọ lọ si igbekun, awọn alufa rẹ̀ ati awọn ijoye rẹ̀.
3 Howl, O Heshbon, for Ai is spoiled: cry, ye daughters of Rabbah, gird you with sackcloth; lament, and run to and fro by the hedges; for their king shall go into captivity, and his priests and his princes together.
4 Ẽṣe ti iwọ fi nṣogo ninu afonifoji, afonifoji rẹ nṣan lọ, iwọ ọmọbinrin ti o gbẹkẹle iṣura rẹ, pe, tani yio tọ̀ mi wá?
4 Wherefore gloriest thou in the valleys, thy flowing valley, O backsliding daughter? that trusted in her treasures, saying, Who shall come unto me?
5 Wò o, emi o mu ẹ̀ru wá sori rẹ, li Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun wi, lati ọdọ gbogbo awọn wọnni ti o wà yi ọ kakiri; a o si le nyin, olukuluku enia tàra niwaju rẹ̀; ẹnikan kì o si kó awọn ti nsalọ jọ.
5 Behold, I will bring a fear upon thee, saith the Lord GOD of hosts, from all those that be about thee; and ye shall be driven out every man right forth; and none shall gather up him that wandereth.
6 Ati nikẹhin emi o tun mu igbekun awọn ọmọ Ammoni pada, li Oluwa wi.
6 And afterward I will bring again the captivity of the children of Ammon, saith the LORD.
7 Si Edomu. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Kò ha si ọgbọ́n mọ ni Temani? a ha ke imọran kuro lọdọ oloye? ọgbọ́n wọn ha danu bi?
7 Concerning Edom, thus saith the LORD of hosts; Is wisdom no more in Teman? is counsel perished from the prudent? is their wisdom vanished?
8 Ẹ sa, ẹ yipada, ẹ ṣe ibi jijin lati ma gbe ẹnyin olugbe Dedani; nitori emi o mu wahala Esau wá sori rẹ̀, àkoko ti emi o bẹ̀ ẹ wò.
8 Flee ye, turn back, dwell deep, O inhabitants of Dedan; for I will bring the calamity of Esau upon him, the time that I will visit him.
9 Bi awọn aka-eso ba tọ̀ ọ wá, nwọn kì o ha kù ẽṣẹ́ eso ajara silẹ? bi awọn ole ba wá li oru, nwọn kì o ha parun titi yio fi tẹ́ wọn lọrùn.
9 If grapegatherers come to thee, would they not leave some gleaning grapes? if thieves by night, they will destroy till they have enough.
10 Nitori emi ti tú Esau ni ihoho, emi ti fi ibi ikọkọ rẹ̀ han, on kì o si le fi ara rẹ̀ pamọ; iru-ọmọ rẹ̀ di ijẹ, ati awọn arakunrin rẹ̀, ati awọn aladugbo rẹ̀, nwọn kò sí mọ́.
10 But I have made Esau bare, I have uncovered his secret places, and he shall not be able to hide himself: his seed is spoiled, and his brethren, and his neighbours, and he is not.
11 Fi awọn ọmọ alainibaba rẹ silẹ, emi o si pa wọn mọ lãye; ati ki awọn opó rẹ ki o gbẹkẹle mi.
11 Leave thy fatherless children, I will preserve them alive; and let thy widows trust in me.
12 Nitori bayi li Oluwa wi; Wò o, awọn ẹniti kò jẹbi, lati mu ninu ago, ni yio mu u lõtọ: iwọ o ha si lọ li alaijiya? iwọ kì yio lọ li alaijiya, nitori lõtọ iwọ o mu u.
12 For thus saith the LORD; Behold, they whose judgment was not to drink of the cup have assuredly drunken; and art thou he that shall altogether go unpunished? thou shalt not go unpunished, but thou shalt surely drink of it.
13 Nitori emi ti fi ara mi bura, li Oluwa wi pe: Bosra yio di ahoro, ẹ̀gan, idahoro, ati egún; ati gbogbo ilu rẹ̀ ni yio di ahoro lailai.
13 For I have sworn by myself, saith the LORD, that Bozrah shall become a desolation, a reproach, a waste, and a curse; and all the cities thereof shall be perpetual wastes.
14 Ni gbigbọ́ emi ti gbọ́ iró lati ọdọ Oluwa wá, a si ran ikọ̀ si awọn orilẹ-ède pe, ẹ kó ara nyin jọ, ẹ wá sori rẹ̀, ẹ si dide lati jagun.
14 I have heard a rumour from the LORD, and an ambassador is sent unto the heathen, saying, Gather ye together, and come against her, and rise up to the battle.
15 Nitori, wò o, emi o ṣe ọ ni ẹni-kekere lãrin awọn orilẹ-ède, ẹni-ẹgan lãrin awọn enia.
15 For, lo, I will make thee small among the heathen, and despised among men.
16 Ibanilẹ̀ru rẹ ti tan ọ jẹ, igberaga ọkàn rẹ, nitori iwọ ngbe palapala okuta, ti o joko li ori oke, bi iwọ tilẹ kọ́ itẹ́ rẹ ga gẹgẹ bi idì, sibẹ emi o mu ọ sọkalẹ lati ibẹ wá, li Oluwa wi.
16 Thy terribleness hath deceived thee, and the pride of thine heart, O thou that dwellest in the clefts of the rock, that holdest the height of the hill: though thou shouldest make thy nest as high as the eagle, I will bring thee down from thence, saith the LORD.
17 Edomu yio si di ahoro: olukuluku ẹniti o ba rekọja rẹ̀, yio dãmu, yio si rẹrin si gbogbo ipọnju rẹ̀.
17 Also Edom shall be a desolation: every one that goeth by it shall be astonished, and shall hiss at all the plagues thereof.
18 Gẹgẹ bi ni ibiṣubu Sodomu ati Gomorra ati awọn aladugbo rẹ̀, li Oluwa wi; ẹnikan kì yio gbe ibẹ mọ, bẹ̃ni ọmọ enia kan kì yio ṣatipo ninu rẹ̀.
18 As in the overthrow of Sodom and Gomorrah and the neighbour cities thereof, saith the LORD, no man shall abide there, neither shall a son of man dwell in it.
19 Wò o, yio goke wá bi kiniun lati igberaga Jordani si ibugbe okuta; nitori lojiji ni emi o lé wọn jade kuro nibẹ, ati tani ayanfẹ na ti emi o yàn sori rẹ̀, nitori tani dabi emi, tani yio si pè mi ṣe ẹlẹri? ati tani oluṣọ-agutan na, ti yio le duro niwaju mi?
19 Behold, he shall come up like a lion from the swelling of Jordan against the habitation of the strong: but I will suddenly make him run away from her: and who is a chosen man, that I may appoint over her? for who is like me? and who will appoint me the time? and who is that shepherd that will stand before me?
20 Nitorina gbọ́ ìmọ Oluwa ti o ti gbà si Edomu; ati èro rẹ̀ ti o ti gba si awọn olugbe Temani pe, Lõtọ awọn ẹniti o kere julọ ninu agbo-ẹran yio wọ́ wọn kiri, lõtọ nwọn o sọ buka wọn di ahoro lori wọn.
20 Therefore hear the counsel of the LORD, that he hath taken against Edom; and his purposes, that he hath purposed against the inhabitants of Teman: Surely the least of the flock shall draw them out: surely he shall make their habitations desolate with them.
21 Ilẹ o mì nipa ariwo iṣubu wọn, ariwo! a gbọ́ ohùn igbe rẹ̀ li Okun-pupa.
21 The earth is moved at the noise of their fall, at the cry the noise thereof was heard in the Red sea.
22 Wò o, yio goke wá yio si fò gẹgẹ bi idì, yio si nà iyẹ rẹ̀ sori Bosra: ati li ọjọ na ni ọkàn awọn alagbara ọkunrin Edomu yio dabi ọkàn obinrin ni irọbi.
22 Behold, he shall come up and fly as the eagle, and spread his wings over Bozrah: and at that day shall the heart of the mighty men of Edom be as the heart of a woman in her pangs.
23 Si Damasku. Oju tì Hamati, ati Arpadi: nitori nwọn ti gbọ́ ìhin buburu: aiya ja wọn; idãmu wà lẹba okun; nwọn kò le ri isimi.
23 Concerning Damascus. Hamath is confounded, and Arpad: for they have heard evil tidings: they are fainthearted; there is sorrow on the sea; it cannot be quiet.
24 Damasku di alailera, o yi ara rẹ̀ pada lati sa, iwarìri si dì i mu: ẹ̀dun ati irora ti dì i mu, gẹgẹ bi obinrin ti nrọbi.
24 Damascus is waxed feeble, and turneth herself to flee, and fear hath seized on her: anguish and sorrows have taken her, as a woman in travail.
25 Bawo ni a kò ṣe fi ilu iyìn silẹ, ilu ayọ̀ mi!
25 How is the city of praise not left, the city of my joy!
26 Nitorina awọn ọdọmọkunrin rẹ̀ yio ṣubu ni ita rẹ̀, ati gbogbo awọn ọkunrin ogun ni a o ke kuro li ọjọ na, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
26 Therefore her young men shall fall in her streets, and all the men of war shall be cut off in that day, saith the LORD of hosts.
27 Emi o si da iná ni odi Damasku, yio si jo ãfin Benhadadi run.
27 And I will kindle a fire in the wall of Damascus, and it shall consume the palaces of Ben-hadad.
28 Si Kedari, ati si ijọba Hasori, ti Nebukadnessari ọba Babeli, kó: Bayi li Oluwa wi; Dide, goke lọ si Kedari, ki ẹ si pa awọn ọkunrin ìla-õrùn run.
28 Concerning Kedar, and concerning the kingdoms of Hazor, which Nebuchadrezzar king of Babylon shall smite, thus saith the LORD; Arise ye, go up to Kedar, and spoil the men of the east.
29 Agọ wọn ati agbo-ẹran wọn ni nwọn o kó lọ: nwọn o mu aṣọ agọ wọn fun ara wọn, ati gbogbo ohun-èlo wọn, ati ibakasiẹ wọn; nwọn o si kigbe sori wọn pe, Ẹ̀ru yikakiri!
29 Their tents and their flocks shall they take away: they shall take to themselves their curtains, and all their vessels, and their camels; and they shall cry unto them, Fear is on every side.
30 Sa, yara salọ, fi ara pamọ si ibi jijìn, ẹnyin olugbe Hasori, li Oluwa wi; nitori Nebukadnessari ọba Babeli, ti gbìmọ kan si nyin, o si ti gba èro kan si nyin.
30 Flee, get you far off, dwell deep, O ye inhabitants of Hazor, saith the LORD; for Nebuchadrezzar king of Babylon hath taken counsel against you, and hath conceived a purpose against you.
31 Dide, goke lọ sọdọ orilẹ-ède kan ti o wà ni irọra, ti o ngbe li ailewu, li Oluwa wi, ti kò ni ilẹkun ẹnu-bode tabi ikere; ti ngbe fun ara rẹ̀.
31 Arise, get you up unto the wealthy nation, that dwelleth without care, saith the LORD, which have neither gates nor bars, which dwell alone.
32 Ibakasiẹ wọn yio si di ikogun, ati ọ̀pọlọpọ ẹran-ọ̀sin wọn yio di ijẹ: emi o si tú awọn ti nda òṣu ka si gbogbo ọ̀na afẹfẹ; emi o si mu wahala wọn de lati iha gbogbo, li Oluwa wi.
32 And their camels shall be a booty, and the multitude of their cattle a spoil: and I will scatter into all winds them that are in the utmost corners; and I will bring their calamity from all sides thereof, saith the LORD.
33 Hasori yio di ibugbe fun ọ̀wawa, ahoro titi lai: kì o si ẹnikan ti yio joko nibẹ, bẹ̃ni ọmọ enia kan kì yio ṣatipo ninu rẹ̀.
33 And Hazor shall be a dwelling for dragons, and a desolation for ever: there shall no man abide there, nor any son of man dwell in it.
34 Ọ̀rọ Oluwa ti o tọ Jeremiah, woli, wá si Elamu, ni ibẹrẹ ijọba Sedekiah, ọba Juda, wipe:
34 The word of the LORD that came to Jeremiah the prophet against Elam in the beginning of the reign of Zedekiah king of Judah, saying,
35 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Wò o, emi o ṣẹ́ ọrun Elamu, ti iṣe olori agbara wọn.
35 Thus saith the LORD of hosts; Behold, I will break the bow of Elam, the chief of their might.
36 Ati sori Elamu ni emi o mu afẹfẹ mẹrin lati igun mẹrẹrin ọrun wá, emi o si tú wọn ka si gbogbo ọ̀na afẹfẹ wọnni, kì o si sí orilẹ-ède kan, nibiti awọn ãsá Elamu kì yio de.
36 And upon Elam will I bring the four winds from the four quarters of heaven, and will scatter them toward all those winds; and there shall be no nation whither the outcasts of Elam shall not come.
37 Nitori emi o mu Elamu warìri niwaju awọn ọta wọn, ati niwaju awọn ti nwá ẹmi wọn: emi o si mu ibi wá sori wọn, ani ibinu gbigbona mi, li Oluwa wi; emi o si rán idà tẹle wọn, titi emi o fi run wọn.
37 For I will cause Elam to be dismayed before their enemies, and before them that seek their life: and I will bring evil upon them even my fierce anger, saith the LORD; and I will send the sword after them, till I have consumed them:
38 Emi o si gbe itẹ mi kalẹ ni Elamu, emi o si pa ọba ati awọn ijoye run kuro nibẹ, li Oluwa wi.
38 And I will set my throne in Elam, and will destroy from thence the king and the princes, saith the LORD.
39 Ṣugbọn yio si ṣe, ni ikẹhin ọjọ, emi o tun mu igbèkun Elamu pada, li Oluwa wi.
39 But it shall come to pass in the latter days, that I will bring again the captivity of Elam, saith the LORD.