Skip to content

Jeremiah 43 - Listen Online

Loading Bible...
Read Jeremiah 43

1 O si ṣe, nigbati Jeremiah pari ọ̀rọ isọ fun gbogbo awọn enia, ani gbogbo ọ̀rọ Oluwa Ọlọrun wọn, eyiti Oluwa Ọlọrun wọn ti rán a si wọn, ani gbogbo ọ̀rọ wọnyi.

1 And it came to pass, that when Jeremiah had made an end of speaking unto all the people all the words of the LORD their God, for which the LORD their God had sent him to them, even all these words,

2 Nigbana ni Asariah, ọmọ Hoṣaiah, ati Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn agberaga enia, wi fun Jeremiah pe, Iwọ ṣe eke! Oluwa, Ọlọrun wa, kò ran ọ lati wipe, Ẹ má lọ si Egipti lati ṣatipo nibẹ:

2 Then spake Azariah the son of Hoshaiah, and Johanan the son of Kareah, and all the proud men, saying unto Jeremiah, Thou speakest falsely: the LORD our God hath not sent thee to say, Go not into Egypt to sojourn there:

3 Ṣugbọn Baruku, ọmọ Neriah, li o fi ọ̀rọ si ọ li ẹnu si wa, nitori lati fi wa le awọn ara Kaldea lọwọ, lati pa wa ati lati kó wa ni igbekun lọ si Babeli.

3 But Baruch the son of Neriah setteth thee on against us, for to deliver us into the hand of the Chaldeans, that they might put us to death, and carry us away captives into Babylon.

4 Bẹ̃ni Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn olori ogun, ati gbogbo awọn enia, kò gbà ohùn Oluwa gbọ́, lati má gbe ilẹ Juda,

4 So Johanan the son of Kareah, and all the captains of the forces, and all the people, obeyed not the voice of the LORD, to dwell in the land of Judah.

5 Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn olori ogun, si mu gbogbo iyokù Juda, ti nwọn pada lati gbogbo orilẹ-ède wá, ni ibi ti a ti le wọn si, lati ma gbe ilẹ Juda;

5 But Johanan the son of Kareah, and all the captains of the forces, took all the remnant of Judah, that were returned from all nations, whither they had been driven, to dwell in the land of Judah;

6 Awọn ọkunrin, ati awọn obinrin, ati awọn ọmọde, ati awọn ọmọbinrin ọba, ati gbogbo enia ti Nebusaradani, balogun iṣọ, ti kù silẹ lọdọ Gedaliah, ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ati Jeremiah woli, ati Baruku, ọmọ Neriah,

6 Even men, and women, and children, and the king's daughters, and every person that Nebuzar-adan the captain of the guard had left with Gedaliah the son of Ahikam the son of Shaphan, and Jeremiah the prophet, and Baruch the son of Neriah.

7 Nwọn si wá si ilẹ Egipti: nitori nwọn kò gbà ohùn Oluwa gbọ́: bayi ni nwọn wá si Tafanesi.

7 So they came into the land of Egypt: for they obeyed not the voice of the LORD: thus came they even to Tahpanhes.

8 Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Jeremiah wá ni Tafanesi, wipe,

8 Then came the word of the LORD unto Jeremiah in Tahpanhes, saying,

9 Mu okuta nla li ọwọ rẹ ki o si fi wọn pamọ sinu amọ̀, ni ile-iná briki ti o wà ni ẹnu-ọ̀na ile Farao ni Tafanesi, li oju awọn ọkunrin Juda.

9 Take great stones in thine hand, and hide them in the clay in the brickkiln, which is at the entry of Pharaoh's house in Tahpanhes, in the sight of the men of Judah;

10 Ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi, pe, wò o, emi o ranṣẹ, emi o si mu Nebukadnessari, ọba Babeli, iranṣẹ mi, emi o si gbe itẹ rẹ̀ kalẹ lori okuta wọnyi, ti emi ti fi pamọ; on o si tẹ itẹ ọla rẹ̀ lori wọn.

10 And say unto them, Thus saith the LORD of hosts, the God of Israel; Behold, I will send and take Nebuchadrezzar the king of Babylon, my servant, and will set his throne upon these stones that I have hid; and he shall spread his royal pavilion over them.

11 Nigbati o ba si de, on o kọlu ilẹ Egipti, on o si fi ti ikú, fun ikú: ti igbekun, fun igbekun; ati ti idà, fun idà.

11 And when he cometh, he shall smite the land of Egypt, and deliver such as are for death to death; and such as are for captivity to captivity; and such as are for the sword to the sword.

12 Emi o si dá iná kan ni ile awọn oriṣa Egipti; on o si sun wọn, yio si kó wọn lọ; on o si fi ilẹ Egipti wọ ara rẹ̀ laṣọ gẹgẹ bi oluṣọ-agutan ti iwọ̀ aṣọ rẹ̀; yio si jade lati ibẹ lọ li alafia.

12 And I will kindle a fire in the houses of the gods of Egypt; and he shall burn them, and carry them away captives: and he shall array himself with the land of Egypt, as a shepherd putteth on his garment; and he shall go forth from thence in peace.

13 Yio si fọ́ ere ile-õrùn, ti o wà ni ilẹ Egipti tũtu, yio si fi iná kun ile awọn oriṣa awọn ara Egipti.

13 He shall break also the images of Beth-shemesh, that is in the land of Egypt; and the houses of the gods of the Egyptians shall he burn with fire.