Jeremiah 39 - Listen Online
Read Jeremiah 39
1 O si ṣe, nigbati a kó Jerusalemu (li ọdun kẹsan Sedekiah, ọba Juda, li oṣu kẹwa ni Nebukadnessari, ọba Babeli, ati gbogbo ogun rẹ̀ wá si Jerusalemu, nwọn si dó tì i.
1 In the ninth year of Zedekiah king of Judah, in the tenth month, came Nebuchadrezzar king of Babylon and all his army against Jerusalem, and they beseiged it.
2 Ati li ọdun kọkanla Sedekiah, li oṣu kẹrin, li ọjọ keṣan oṣu li a fọ ilu na.)
2 And in the eleventh year of Zedekiah, in the fourth month, the ninth day of the month, the city was broken up.
3 Gbogbo awọn ijoye ọba Babeli si wọle, nwọn si joko li ẹnu-bode ãrin, ani Nergali-Ṣareseri, Samgari-nebo, Sarsikimu, olori iwẹfa, Nergali-Ṣareseri, olori amoye, pẹlu gbogbo awọn ijoye ọba Babeli iyokù.
3 And all the princes of the king of Babylon came in, and sat in the middle gate, even Nergal-sharezer, Samgar-nebo, Sarsechim, Rab-saris, Nergal-sharezer, Rabmag, with all the residue of the princes of the king of Babylon.
4 O si ṣe, nigbati Sedekiah, ọba Juda, ati gbogbo awọn ologun ri wọn, nigbana ni nwọn sá, nwọn si jade kuro ni ilu li oru, nwọn gba ọ̀na ọgbà ọba ati ẹnu-bode lãrin odi mejeji, nwọn si jade lọ li ọ̀na pẹtẹlẹ.
4 And it came to pass, that when Zedekiah the king of Judah saw them, and all the men of war, then they fled, and went forth out of the city by night, by the way of the king's garden, by the gate betwixt the two walls: and he went out the way of the plain.
5 Ṣugbọn ogun awọn ara Kaldea lepa wọn, nwọn si ba Sedekiah, ọba, ni pẹtẹlẹ Jeriko; nigbati nwọn si mu u, nwọn mu u goke wá sọdọ Nebukadnessari, ọba Babeli, ni Ribla ni ilẹ Hamati, nibiti o sọ̀rọ idajọ lori rẹ̀.
5 But the Chaldeans' army pursued after them, and overtook Zedekiah in the plains of Jericho: and when they had taken him, they brought him up to Nebuchadnezzar king of Babylon to Riblah in the land of Hamath, where he gave judgment upon him.
6 Nigbana ni ọba Babeli pa awọn ọmọ Sedekiah ni Ribla, niwaju rẹ̀; ọba Babeli si pa gbogbo awọn ọlọla Juda pẹlu.
6 Then the king of Babylon slew the sons of Zedekiah in Riblah before his eyes: also the king of Babylon slew all the nobles of Judah.
7 Pẹlupẹlu o fọ Sedekiah li oju, o si fi ẹ̀wọn dè e, lati mu u lọ si Babeli.
7 Moreover he put out Zedekiah's eyes, and bound him with chains, to carry him to Babylon.
8 Awọn ara Kaldea si fi ile ọba ati ile awọn enia joná, nwọn si wó odi Jerusalemu lulẹ.
8 And the Chaldeans burned the king's house, and the houses of the people, with fire, and brake down the walls of Jerusalem.
9 Nebusaradani, balogun iṣọ, si kó iyokù awọn enia ti o kù ni ilu ni igbekun lọ si Babeli, pẹlu awọn ti o ti ya lọ, ti o ya sọdọ rẹ̀, pẹlu awọn enia iyokù ti o kù.
9 Then Nebuzar-adan the captain of the guard carried away captive into Babylon the remnant of the people that remained in the city, and those that fell away, that fell to him, with the rest of the people that remained.
10 Ṣugbọn Nebusaradani, balogun iṣọ, si mu diẹ ninu awọn enia, ani awọn talaka ti kò ni nkan rara, joko ni ilẹ Juda, o si fi ọgba-àjara ati oko fun wọn li àkoko na.
10 But Nebuzar-adan the captain of the guard left of the poor of the people, which had nothing, in the land of Judah, and gave them vineyards and fields at the same time.
11 Nebukadnessari, ọba Babeli, si paṣẹ fun Nebusaradani, balogun iṣọ, niti Jeremiah, wipe,
11 Now Nebuchadrezzar king of Babylon gave charge concerning Jeremiah to Nebuzar-adan the captain of the guard, saying,
12 Mu u, ki o si bojuto o, má si ṣe e ni ibi kan; ṣugbọn gẹgẹ bi on ba ti sọ fun ọ, bẹ̃ni ki iwọ ki o ṣe fun u.
12 Take him, and look well to him, and do him no harm; but do unto him even as he shall say unto thee.
13 Bẹ̃ni Nebusaradani, balogun iṣọ, ati Nebuṣaṣbani, olori iwẹfa, ati Nergali Ṣareseri, olori amoye, ati gbogbo ijoye ọba Babeli, si ranṣẹ,
13 So Nebuzar-adan the captain of the guard sent, and Nebushasban, Rab-saris, and Nergal-sharezer, Rabmag, and all the king of Babylon's princes;
14 Ani nwọn ranṣẹ nwọn si mu Jeremiah jade ni àgbala ile-tubu, nwọn si fi fun Gedaliah, ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, pe ki o mu u lọ si ile: bẹ̃ni o ngbe ãrin awọn enia.
14 Even they sent, and took Jeremiah out of the court of the prison, and committed him unto Gedaliah the son of Ahikam the son of Shaphan, that he should carry him home: so he dwelt among the people.
15 Ọrọ Oluwa si tọ̀ Jeremiah wá, nigbati a se e mọ ninu àgbala ile-túbu, wipe,
15 Now the word of the LORD came unto Jeremiah, while he was shut up in the court of the prison, saying,
16 Lọ, ki o si sọ fun Ebedmeleki, ara Etiopia, wipe: Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, wò o, emi o mu ọ̀rọ mi wá sori ilu yi fun ibi, kì isi ṣe fun rere; nwọn o si ṣẹ niwaju rẹ li ọjọ na.
16 Go and speak to Ebed-melech the Ethiopian, saying, Thus saith the LORD of hosts, the God of Israel; Behold, I will bring my words upon this city for evil, and not for good; and they shall be accomplished in that day before thee.
17 Ṣugbọn emi o gbà ọ li ọjọ na, li Oluwa wi: a kì o si fi ọ le ọwọ awọn enia na ti iwọ bẹ̀ru.
17 But I will deliver thee in that day, saith the LORD: and thou shalt not be given into the hand of the men of whom thou art afraid.
18 Nitori emi o gbà ọ là nitõtọ, iwọ kì o si ti ipa idà ṣubu, ṣugbọn ẹ̀mi rẹ yio jẹ bi ikogun fun ọ: nitoripe iwọ ti gbẹkẹ rẹ le mi, li Oluwa wi.
18 For I will surely deliver thee, and thou shalt not fall by the sword, but thy life shall be for a prey unto thee: because thou hast put thy trust in me, saith the LORD.