Skip to content

Isaiah 15 - Listen Online

Loading Bible...
Read Isaiah 15

1 ỌRỌ-imọ̀ niti Moabu. Nitori li oru li a sọ Ari ti Moabu di ahoro, a si mu u dakẹ; nitori li oru li a sọ Kiri ti Moabu di ahoro, a si mu u dakẹ;

1 The burden of Moab. Because in the night Ar of Moab is laid waste, and brought to silence; because in the night Kir of Moab is laid waste, and brought to silence;

2 On ti goke lọ si Bajiti, ati si Diboni, ibi giga wọnni, lati sọkun: Moabu yio hu lori Nebo, ati lori Medeba: gbogbo ori wọn ni yio pá, irungbọ̀n olukulùku li a o fá.

2 He is gone up to Bajith, and to Dibon, the high places, to weep: Moab shall howl over Nebo, and over Medeba: on all their heads shall be baldness, and every beard cut off.

3 Ni igboro ni wọn o da aṣọ-ọ̀fọ bò ara wọn: lori okè ilé wọn, ati ni igboro wọn, olukuluku yio hu, yio si ma sọkun pẹ̀rẹpẹ̀rẹ.

3 In their streets they shall gird themselves with sackcloth: on the tops of their houses, and in their streets, every one shall howl, weeping abundantly.

4 Heṣboni yio si kigbe, ati Eleale: a o si gbọ́ ohùn wọn titi dé Jahasi: nitorina ni awọn ọmọ-ogun Moabu ti o hamọra yio kigbe soke; ọkàn rẹ̀ yio bajẹ fun ara rẹ̀.

4 And Heshbon shall cry, and Elealeh: their voice shall be heard even unto Jahaz: therefore the armed soldiers of Moab shall cry out; his life shall be grievous unto him.

5 Ọkàn mi kigbe soke fun Moabu; awọn ìsánsá rẹ̀ sá de Soari, abo-malũ ọlọdun mẹta: ni gigun oke Luhiti tẹkúntẹkún ni nwọn o ma fi gùn u lọ; niti ọ̀na Horonaimu nwọn o gbe ohùn iparun soke.

5 My heart shall cry out for Moab; his fugitives shall flee unto Zoar, an heifer of three years old: for by the mounting up of Luhith with weeping shall they go it up; for in the way of Horonaim they shall raise up a cry of destruction.

6 Nitori awọn omi Nimrimu yio di ahoro: nitori koriko nrọgbẹ, eweko nkú lọ, ohun tutù kan kò si.

6 For the waters of Nimrim shall be desolate: for the hay is withered away, the grass faileth, there is no green thing.

7 Nitorina ọ̀pọ eyi ti nwọn ti ni, ati eyi ti nwọn ti kojọ, ni nwọn o gbe kọja odò willo.

7 Therefore the abundance they have gotten, and that which they have laid up, shall they carry away to the brook of the willows.

8 Nitori igbe na ti yi agbegbè Moabu ka; igbe na si de Eglaimu, ati igbe na de Beerelimu.

8 For the cry is gone round about the borders of Moab; the howling thereof unto Eglaim, and the howling thereof unto Beer-elim.

9 Nitori odò Dimoni yio kún fun ẹ̀jẹ: nitori emi o fi ibi miran sori Dimoni, emi o mu kiniun wá sori ẹniti ó sálà kuro ni Moabu, ati lori awọn ti o kù ni ilẹ na.

9 For the waters of Dimon shall be full of blood: for I will bring more upon Dimon, lions upon him that escapeth of Moab, and upon the remnant of the land.