Genesis 7 - Listen Online
Read Genesis 7
1 OLUWA si wi fun Noa pe, iwọ wá, ati gbogbo awọn ara ile rẹ sinu ọkọ̀, nitori iwọ ni mo ri li olododo niwaju mi ni iran yi.
1 And the LORD said unto Noah, Come thou and all thy house into the ark; for thee have I seen righteous before me in this generation.
2 Ninu onirũru ẹran ti o mọ́ meje meje ni ki iwọ ki o mu wọn, ati akọ ati abo rẹ̀; ati ninu ẹran ti kò mọ́ meji meji, ati akọ ati abo rẹ̀.
2 Of every clean beast thou shalt take to thee by sevens, the male and his female: and of beasts that are not clean by two, the male and his female.
3 Ninu ẹiyẹ oju-ọrun pẹlu ni meje meje, ati akọ ati abo; lati dá irú si lãye lori ilẹ gbogbo.
3 Of fowls also of the air by sevens, the male and the female; to keep seed alive upon the face of all the earth.
4 Nitori ijọ́ meje si i, emi o mu òjo rọ̀ si ilẹ li ogoji ọsán ati li ogoji oru; ohun alãye gbogbo ti mo dá li emi o parun kuro lori ilẹ.
4 For yet seven days, and I will cause it to rain upon the earth forty days and forty nights; and every living substance that I have made will I destroy from off the face of the earth.
5 Noa si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA paṣẹ fun u.
5 And Noah did according unto all that the LORD commanded him.
6 Noa si jẹ ẹni ẹgbẹta ọdún nigbati kíkun-omi de si aiye.
6 And Noah was six hundred years old when the flood of waters was upon the earth.
7 Noa si wọle, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati aya rẹ̀, ati aya awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, sinu ọkọ̀, nitori kíkun-omi.
7 And Noah went in, and his sons, and his wife, and his sons' wives with him, into the ark, because of the waters of the flood.
8 Ninu ẹranko mimọ́, ati ninu ẹranko ti kò mọ́, ati ninu ẹiyẹ, ati ninu ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ,
8 Of clean beasts, and of beasts that are not clean, and of fowls, and of every thing that creepeth upon the earth,
9 Nwọn wọle tọ̀ Noa lọ sinu ọkọ̀ ni meji meji, ati akọ ati abo, bi Ọlọrun ti fi aṣẹ fun Noa.
9 There went in two and two unto Noah into the ark, the male and the female, as God had commanded Noah.
10 O si ṣe ni ijọ́ keje, bẹ̃ni kíkun-omi de si aiye.
10 And it came to pass after seven days, that the waters of the flood were upon the earth.
11 Li ẹgbẹta ọdún ọjọ́ aiye Noa, li oṣù keji, ni ọjọ́ kẹtadilogun oṣù, li ọjọ́ na ni gbogbo isun ibú nla ya, ati ferese iṣàn omi ọrun si ṣí silẹ.
11 In the six hundredth year of Noah's life, in the second month, the seventeenth day of the month, the same day were all the fountains of the great deep broken up, and the windows of heaven were opened.
12 Òjo na si wà lori ilẹ li ogoji ọsán on ogoji oru.
12 And the rain was upon the earth forty days and forty nights.
13 Li ọjọ́ na gan ni Noa wọ̀ inu ọkọ̀, ati Ṣemu, ati Hamu, ati Jafeti, awọn ọmọ Noa, ati aya Noa, (ati awọn aya ọmọ rẹ̀ mẹta pẹlu wọn).
13 In the selfsame day entered Noah, and Shem, and Ham, and Japheth, the sons of Noah, and Noah's wife, and the three wives of his sons with them, into the ark;
14 Awọn, ati gbogbo ẹranko ni irú tirẹ̀, ati ẹran-ọ̀sin gbogbo ni irú tirẹ̀, ati ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ ni irú tirẹ̀, ati gbogbo ẹiyẹ nla ni irú tirẹ̀, ati gbogbo ẹiyẹ abiyẹ.
14 They, and every beast after his kind, and all the cattle after their kind, and every creeping thing that creepeth upon the earth after his kind, and every fowl after his kind, every bird of every sort.
15 Nwọn si wọle tọ̀ Noa lọ sinu ọkọ̀, meji meji ninu ẹda gbogbo, ninu eyiti ẹmi ìye wà.
15 And they went in unto Noah into the ark, two and two of all flesh, wherein is the breath of life.
16 Awọn ti o si wọle lọ, nwọn wọle ti akọ ti abo ninu ẹdá gbogbo, bi Ọlọrun ti fi aṣẹ fun u. OLUWA si sé e mọ́ ile.
16 And they that went in, went in male and female of all flesh, as God had commanded him: and the LORD shut him in.
17 Ikún-omi si wà li ogoji ọjọ́ lori ilẹ; omi si nwú si i, o si mu ọkọ̀ fó soke, o si gbera kuro lori ilẹ.
17 And the flood was forty days upon the earth; and the waters increased, and bare up the ark, and it was lift up above the earth.
18 Omi si gbilẹ, o si nwú si i gidigidi lori ilẹ; ọkọ̀ na si fó soke loju omi.
18 And the waters prevailed, and were increased greatly upon the earth; and the ark went upon the face of the waters.
19 Omi si gbilẹ gidigidi lori ilẹ; ati gbogbo oke giga, ti o wà ni gbogbo abẹ ọrun, li a bò mọlẹ.
19 And the waters prevailed exceedingly upon the earth; and all the high hills, that were under the whole heaven, were covered.
20 Omi gbilẹ soke ni igbọ́nwọ mẹ̃dogun; a si bò gbogbo okenla mọlẹ.
20 Fifteen cubits upward did the waters prevail; and the mountains were covered.
21 Gbogbo ẹdá ti nrìn lori ilẹ si kú, ti ẹiyẹ, ti ẹran-ọ̀sin, ti ẹranko, ti ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ ati gbogbo enia:
21 And all flesh died that moved upon the earth, both of fowl, and of cattle, and of beast, and of every creeping thing that creepeth upon the earth, and every man:
22 Gbogbo ohun ti ẹmi ìye wà ni ihò imu rẹ̀, gbogbo ohun ti o wà ni iyangbẹ ilẹ si kú.
22 All in whose nostrils was the breath of life, of all that was in the dry land, died.
23 Ohun alãye gbogbo ti o wà lori ilẹ li a si parun, ati enia, ati ẹran-ọ̀sin, ati ohun ti nrakò, ati ẹiyẹ oju-ọrun, nwọn si run kuro lori ilẹ. Noa nikan li o kù, ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀ ninu ọkọ̀.
23 And every living substance was destroyed which was upon the face of the ground, both man, and cattle, and the creeping things, and the fowl of the heaven; and they were destroyed from the earth: and Noah only remained alive, and they that were with him in the ark.
24 Omi si gbilẹ li aiye li ãdọjọ ọjọ́.
24 And the waters prevailed upon the earth an hundred and fifty days.